BBC ti ṣe àgbéjáde àwọn orúkọ obìnrin ọgọ́rùn-ún tó làmì laaka káàkiri àgbáyé fún ọdún 2024.
Lára wọn ni àgbà òǹkọ̀wé Nadia Murad, ẹni tó móríbọ́ lọ́wọ́ Ìfipábánilòpọ̀ Gisèle Pelicot, òṣèré Sharon Stone, àwọn eléré ìje Olympic Rebeca Andrade àti Allyson Felix, akọrin Raye, ayàwòrán Tracey Emin, olùpolongo nípa ojú ọjọ́ Adenike Oladosu àti òǹkọ̀wé Cristina Rivera Garza.
Láti kí kojú wàhálà àti títẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀ ní Gaza, Lebanon, Ukraine àti Sudan sí rírí àwùjọ tó ní ìpèníjà látara àwọn ètò ìdìbò tó wáyé káàkiri àgbáyé, àwọn obìnrin ń wá ọ̀nà láti kojú àwọn ìṣòro wọn.
Ọgọ́rùn-ún obìnrin BBC mọ̀ nípa ipa tí ọdún yìí ní lórí àwọn obìnrin nípa ṣíṣe àyẹ́sí àwọn obìnrin - pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà yìí - tó ń jà àyípadà ọ̀tun, bí àyíká wọn ṣe ń yípadà. Àwọn orúkọ yìí tún ní ìfarajìn sí ipa tí àyípadà ojú ọjọ́ ń mú wá, ṣe kóríyá fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ láti ri dájú pé agbègbè wọn ń kojú àyípadà yìí lọ́nà tó yẹ.
A ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn orúkọ láì tẹ̀lé ìlànà kan pàtó.
Akọ̀ròyìn àti akéwì
Plestia Alaqad, ẹni ọdún méjìlélógún, ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ilé ẹ̀kọ́ gíga nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀ ní Gaza. Lásìkò tí ogun náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ó ṣe fídíò ara rẹ̀ nínú ilé tó wà pẹ̀lú bí àdó olóró ṣe ń sọlẹ̀ ní Gaza.
Fídíò gba orí ayélujára, táwọn èèyàn sì ń tẹ̀le lórí Instagram pẹ̀lú bó ṣe ń fi ìròyìn bí ogun náà ṣe ń lọ tó àwọn létí pẹ̀lú ewì àti àwọn nǹkan tó máa ń kọ sórí ìkànnì rẹ̀. Ó máa tẹ ìwé tó kọ lórí ogun náà tó pè ní "Eyes of Gaza" jáde láìpẹ́.
Alaqad ló gba àmì ẹ̀yẹ akọ̀ròyìn ọdún 2024 ti One Young World. Ó ti pè fún jíjà fún àwọn ènìyàn Palestine ní àwọn àpérò tó lágbára bíi World Government Summit.
Oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ni Alaqad kúrò ní Gaza. Wọ́n ti fun ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún masters nínú ẹ̀kọ́ ìròyìn ní Beirut.
Akọnilẹkọọ lori iroyin ati oniṣowo
Nigba ti awọn Taliban ko jẹ ki awọn ọmọbinrin Afghanistan ni anfaani ẹkọ ileewe girama mọ, Hamida Aman to jẹ agbohunsafẹfẹ, pinnu lati gbe ile ẹkọ kan to pe ni Begum Academy kalẹ. Eyi jẹ lori ayelujara, o si n kọ wọn lẹkọọ ọfẹ lori iṣẹ iroyin, iyẹn awọn akẹkọọ ti ko ri ileewe lọ mọ naa.
Lọdun to kọja, o le ni 8, 500 fidio akọnilẹkọọ to ti ibẹ jade ni Dari ati Pasho. Wọn n kẹkọọ to le gbe wọn de ipele keje si ikejila.
Ninu oṣu kẹta, Aman ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ tẹlifiṣan Begum, ẹka kan tawọn eeyan ti n kẹkọọ nipasẹ ẹrọ alatagba.
Iṣẹ yii lo tẹle eto redio Begum, ileeṣẹ kan tawọn obinrin se, to wa fawọn obinrin, eyi ti wọn da silẹ lẹyin ti awọn Taliban gbajọba ni 2021.
Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn
Svetlana Anokhina ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn èèyàn tí wọ́n ń kojú ìfìyàjẹni láti sá kúrò ní agbègbè North Caucasus ní Russia, agbègbè táwọn Mùsùlùmí p.s sí tó pa ààlà pẹ̀lú ìlà oòrùn Yúróòpù àti Asia.
Pẹ̀lú àwọn èèyàn míì, ó ṣe ìdásílẹ̀ àkànṣe ètò Marem project lọ́dún 2020. Ètò náà ṣe ìrànwọ́ fáwọn obìnrin tó wà nínú ewu ní Dagestan, Chechnya àtàwọn ìlú ní ẹkùn North Caucasus láti kúrò ní agbègbè náà, tí wọ́n sì wá ibùgbé fún wọn àtàwọn ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò.
Anokhina pinnu láti kúrò ní Russia lọ́dún 2021 lẹ́yìn táwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Chechen àti Dagestani lọ ṣe ìkọlù sí ibùgbé àwọn obìnrin náà.
Lọ́dún tó kọjá ni àwọn aláṣẹ ka ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn si lọ́rùn wí pé ó ń ba iléeṣẹ́ ológun lórúkọ jẹ́.
Ayaworan fawọn akọroyin
Ni nnkan bii ọdun 1990 sisalẹ ni Christina Assi n dagba ni Lebanon, lasiko ti ilu ọhun ko roju latari ogun abẹle to ja wọn. Iṣẹ ayaworan fun awọn akọroyin lo n ṣe, eyi si jẹ ko maa ṣe akọsilẹ awọn ohun to farasin nipa ogun naa.
Ọdun 2023 ni ibanujẹ ba Christina, nigba ti ado oloro ba a ni Guusu Lebanon, to si ṣe e leṣe gidi.
Ado oloro naa pa akọroyin kan, Issam Abdallah, awọn akọroyin marun-un mi-in naa tun fara ṣeṣe, wọn si ge ẹsẹ kan ninu meji ti Christina fi n rin tẹlẹ ki ijamba naa too de.
Ijamba to ṣe e yii lo mu ko maa kede aabo fun awọn akọroyin ẹgbẹ rẹ, o si fi iṣẹ rẹ sọri awon oniroyin to ti ku lẹnu iṣẹ nibi idije Olympic to waye ni Paris ni 2024
Mọdá
Ọkan lara awọn obinrin onigbagbọ ti ki i lọkọ ni Aarabinrin Eugenia Beonetti, eyi ti Yoruba n pe ni Mọdá.O ti le ni ọgọrun-un (100) ibugbe to ti mojuto, to si tun pese iranwọ fun awọn mọda bii tiẹ, ati awọn obinrin kaakiri ilẹ Africa. Eugenia n ṣe eyi lati yọ awọn obinrin ti wọn n fi ẹtan ko wọ Italy lati ṣiṣẹ buruku kuro ninu igbekun.
Ọpọlọpọ oru lo fi n ran awọn obinrin ti wọn ti fipa sọ di aṣẹwo ni Rome lọwọ, o si tipasẹ rẹ di aarẹ ẹgbẹ to ri si bi wọn yoo ṣe da òwò ẹrú duro,iyẹn ẹgbẹ kan to n kede pe wọn ṣi n ko awọn eeyan lẹru lasiko yii.
Bonetti jẹ ajiyinrere to n kọ awọn eeyan lọna ti wọn yoo fi gbogun ti kiko awọn eeyan lẹru , o le lọdun mẹrinlelogun (24 years) ti fi ṣiṣẹ naa lorilẹede Kenya.
Ko too fẹyinti, Pope Francis ni ki Mọda Eugenia kọ ọrọ apilẹkọ ti awọn ijọ Aguda maa n ka lọdọọdun nibi isin Ọjọ Ẹti Rere, iyẹn ti ọdun 2019.
Osere tiata
Wọn fi ọwọ ofin mu Shin Daewe, oṣere to ti gba ami ẹyẹ daadaa ri. Ohun ti wọn mu un fun naa ni ti irinṣẹ ayaworan ti wọn ba ninu ẹru rẹ.
Wọn ba a ṣe ẹjọ lọdun yii ninu iṣakoso ologun Myanmar, wọn lo n huwa igbesunmọmi. ile ẹjọ ti ki i ṣe ibi ti gbogbo eeyan le wọ ni wọn ti gbọ ẹjọ naa, wọn ko jẹ koi gba lọọya, won si ju u si ẹwọn gbere.
Oṣere yii ti n tako ijọba ologun bọ lati ọdun 1988, ko si ki n ṣe ajoji ọgba ẹwọn mọ.
O ti dari akojọpọ iṣẹ, ti pupọ rẹ si jẹ itẹwọgba lawujọ agbaye, titi kan ffimu rẹ to ni i ṣe pẹlu iwọde ọdun 2007 lori ijọba awarawa, nibi ti ẹgbẹrun awon alufaa ijọ Budhi ti darapọ, ti wọn tako ijọba ologun.
Ayàwòrán
Ní ọdún 1990s, Tracey Emin di èèyàn pàtàkì látara iṣẹ́ rẹ̀, My bed and The Tent, èyí tí wọ́n fi pe àwọn èèyàn láti sọ ìrírí wọn nípa ìbálòpọ̀.
Láti ìgbà náà ní orúkọ rẹ̀ ti di ìlúmọ̀ọ́ká lágbo àwọn ayàwòrán.
Ó ti pé ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n báyìí tí wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ My Bed fún ìgbà àkọ́kọ́ ní London. Emin tí wọ́n máa ń pè ní èèkàn nídìí iṣẹ́ ayàwòrán ní ilẹ̀ Britain tẹ́lẹ̀ ni ọba Charles tún ti fi oyè "dame" dá lọ́lá látàrí ipa rẹ̀ sídìí iṣẹ́ ayàwòrán.
Ó dá àjọ Tracey Emin Foundation sílẹ̀ ní Margate, UK láti fi máa ṣe ìrànwọ́ fáwọn ògo wẹẹrẹ nídìí iṣẹ́ ayàwòrán.
Jíjẹ́ obìnrin lásìkò yìí, mo rò pé a nílò okun púpọ̀ láti kojú àwọn ìpèníjà... Mo rò pé àsìkò yìí ni ìṣọ̀kan gbọ́dọ̀ wà láti jà fún àwọn obìnrin.
Tracey Emin
Òǹkọ̀wé
Onírúurú àmì ẹ̀yẹ ni wọ́n ti fi dá òǹkọ̀wé Cristina Rivera Garza lọ́la tó fi mọ́ àmì ẹ̀yẹ 2024 Pulitzer Prize fún ipa tí ìwé rẹ̀ Liliana's Invincible Summer, èyí tó tọná wádìí lórí bí wọ́n ṣe ń pa àwọn obìnrin.
Ikú ọmọ ìyá a rẹ̀ - tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí kan pa ní Mexico lọ́dún 1990, tó sì sá lọ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà - jẹ́ nǹkan tó fa ìpòruru ọkàn fún Liliana, tó sì ń wá ìdájọ́ òdodo lórí ikú náà ní orílẹ̀ èdè tó ní àkọ́ọ́lẹ̀ ṣíṣekúpa àwọn obìnrin jùlọ lágbàáyé.
Rivera Garza tún ni olùdásílẹ̀ àti alága ètò ẹ̀kọ́ gbígba oyè ọ̀mọ̀wé (PhD) nínú ìmọ̀ ìwé kíkọ ní èdè Spanish ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Houstaon.
Ṣíṣe àmúlò èdè lóòrè kóòrè àti lọ́pọ̀ ìgbà kí èdè ba à lè máa gbọ́ tí àwọn obìnrin náà le jẹ́ ìpìlẹ̀ fún ìfárajìn.
Cristina Rivera Garza
Alákòso ibùgbé àwọn obìnrin
Ní ibùgbé àwọn obìnrin tó wà ní Iceland, Linda Dröfn Gunnarsdóttir ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn obìnrin tí wọ́n kúrò ní ilé wọn nítorí ìfìyàjẹni tó ń wáyé fún wọn.
Iceland jẹ́ orílẹ̀ èdè tó máa ń wà nípò òkè níbi tí àwọn obìnrin le gbé àmọ́ tí ìwà fífi ìyà jẹ àwọn obìnrin ti peléke gidi.
Gẹ́gẹ́ bí alákòso àgbà fún àjọ náà, ó ṣáájú ètò náà láti ṣí gbọ̀ngàn tuntun èyí tó máa jẹ́ ibùgbé tuntun àkọ́kọ́ fáwọn obìnrin ní Iceland.
Gunnarsdóttir ní ìdá mẹ́rìnlélọ́gọ́ta àwọn obìnrin tó wà ní ibùgbé náà lógún ọdún sẹ́yìn ló padà sọ́dọ̀ àwọn tó ń fìyà jẹ wọ́n àmọ́ tí iye náà ti dínkù báyìí sí ìdá mọ́kànlá látàrí àtìlẹyìn àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n rí gbà.
Ayaworan
Nigba to n ṣiṣẹ gẹgẹ bii ayaworan lagbegbe ti ọda omi ti n ṣẹlẹ, ti odo n gbẹ, ti ire oko ko ṣe deede, Maheder Haileselassie, ṣe akojọpọ bi ọgbẹlẹ yii ṣe n mu ki awọn obi fi ọmọ wọn obinrin ti ko ti i dagba lọkọ. Iṣẹ yii lo mu un gba ami ẹyẹ 'Contemporary African Photography lọdun 2023.
Iwoye awọn ajọ ajafẹtọọ ọmọniyan ni pe iṣoro oju ọjọ yoo mu ki awọn obi to n fi ọmọdebinrin lọkọ pọ si i nigba ti yoo ba fi di ọdun 2050.
Iṣẹ ti Haileselassie n ṣe gẹgẹ bii ayaworan, da lori ohun to n ṣẹlẹ laaarin awọn eeyan to n ba ṣe ati oun funra rẹ
Ọpọlọpọ ibi ayẹyẹ pataki ni wọn ti ṣafihan iṣẹ rẹ, titi to fi kan ayẹyẹ African Biennale Photography ti wọn ṣe lọdun yii.
Onimọ-ẹrọ to n sọ ile atijọ di tuntun
Pẹlu bi ọpọ ile iṣẹmbaye ṣe ti bajẹ lẹyin ogun ọdun pipẹ to waye ni Yemen, Onimọ-ẹrọ Harbia Al Himiary, gbe igbesẹ ati sọ wọn di ọtun pada.
Nipa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ bii UN, UNESCO, o ti sọ ọpọ ile gbigbe ati ti iṣembaye di tuntun ni agbegbe Sana atijọ ati kaakiri orilẹede naa. Akọsilẹ UNESCO sọ pe o to ẹgbẹrun mẹrindinlogun agbegbe ti ọwọ ogun ti ba.
Iṣẹ ti Harbia n ṣe ki i ṣe fun ibudo atijọ lasan, ọpọ eeyan lo ti sọ igbesi aye wọn di ọtun pẹlu.
Bakan naa lo ti kọ awọn ọmọ ilu ni ilana ikọle aye ọjọun , o si ti mu ki ọpọ ọdọbinrin wa lẹnu iṣẹ naa.
Fun ọpọlọpọ ọdun ni Anat Hoffman ti n kede pe ko si bi ọbọ awọn ọkunrin ṣe ṣori ti inaki obinrin naa ko ṣe, bẹẹ naa lo si n kede ẹsin Judaism.
Ọkan lara awọn ti wọn da ẹgbẹ ti wọn n pe ni Wall group silẹ ni, iyẹn ẹgbẹ to n kede pe awọn obinrin naa lẹtọọ lati le maa gbadura ni Jeusalem atijọ. Ọpọ ọdun lo fi tako ofin to ni obinrin ko le lo ibori ki wọn si maa ka iwe ti a mọ si Torah pẹlu ọkunrin.
Hoffman tun ṣiṣẹ fun ogun ọdun gẹgẹ bii adari Israel Religious Action Center, eyi ti i ṣe ẹka to n ri si idajọ ododo ati dọgba-n-dọgba.
Ṣaaju igba naa lo ti ṣiṣẹ ni Jerusalem City Council, nibi to ti tako awọn ilana to koro oju si iṣe ibilẹ.
Akewi
Onkọwe ati akọroyin ni Maria Teresa Horta, ọkan lara awọn gbajugbaja akọroyin to maa n gbeja awọn obinrin ni. O ti kọ ọpọ iwe to si ti gba ami ẹyẹ lorii wọn, ṣugbọn eyi ti wọn mọ fun ju ni ti Novas Cartas Portuguesas(New Portuguese Letters) to kọ pẹlu awon onkọwe mi-in.
Akojọpọ itan arosọ, ewi ati iroyin ibalopọ di ohun ti wọn fofin de ni 1972, lati ọwọ ijọba apaṣẹ-waa to wa ni Portugal nigba naa. Horta ati awọn onkọwe ẹgbẹ rẹ pe ẹjọ tako iwa to tako jijẹ ọmọluabi ati fifi ẹtọ awọn oniroyin dun wọn lati ṣiṣẹ wọn.
Igbẹjọ awọn Maria mẹta, gẹgẹ baye ṣe pada waa mọ wọn si, di ohun ti wọn n gbe jade niwe iroyin, to si pada jẹ iwuri kari aye.
Igbẹjọ wọn pari lẹyin ti ifehonuhan Carnation to waye ni 1974 fopin si iṣakoso naa. Ọdun yii lo si pe aadọta ọdun ti iṣẹlẹ manigbagbe naa waye.
Ajijagbara awujọ
Abewo kan ti oṣere ori itage ọmọ ilẹ Colombia, Johana Bahamón, ṣe si ọgba ẹwọn lo yi igbesi aye rẹ pada, to si n jẹ iwuri fun un lati ran awọn to ba nilo ironupiwada lẹẹkeji lọwọ.
Ni 2012, o yi iṣẹ to n ṣe pada kuro ni oṣere ori itage, o di ẹni to n gba ẹnu sọ fun pe ki wọn ṣe atunṣe awọn ọgba ẹwọn. O da ajọ 'Fundación Acción Interna', silẹ. Ajọ naa ko si fun pipa owo wọle tabi ere jijẹ, o wa fun ṣiṣẹ iranwọ ati atilẹyin fawọn ti wọn ba jade lẹwọn ni.
Iroyin sọ pe ajọ to da silẹ naa ti ṣe anfaani fun eeyan to ju aadọjọ (150) lọ, o si ti kan si atimọle 132 kaakiri orilẹede naa.
Ajijagbara awujọ yii tun jẹ ẹni to ṣagbatẹru eto kan ti wọn pe ni Second Opportunity Law ni 2022, eyi ti a mọ si Johana Bahamón bill. Ohun to wa fun ni lati ṣe awọn eto to le ro ọrọ aje lagbara, ti yoo jẹ ki awọn eeyan ri iṣẹ ṣe, ti wọ n yoo si le kọ awọn to ba ti ẹwọn de lẹkọọ kan lẹyin ibi ti wọn lọ.
Iduro ṣinṣin kọja a ki eeyan dide lẹyin iṣoro nikan, keeyan le se ipinnu lati sọ iṣubu rẹ di di akasọ igbega lo se pataki ju.
Johana Bahamón
Aláyìpádà
Ọkan lara awọn to bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bii alayipada laaarin awọn Jew ni New York ni Sharon Kleinbaum. O ti lo to ọgbọn ọdun ninu iṣẹ ayipada awọn eeyan to gbagbọ ninu ibalopọ akọ-si-akọ, abo-si-abo, ọrọ ẹsin ati ẹtọ.
Ọdun 1992 ni wọn yan an gẹgẹ bii alayipada fun Beit Simchat Torah. O ti ṣaaju agbegbe naa nigba ojo ati ẹẹrun, titi to fi mọ asiko ti Aids n ja laaarin ọdun 1990.
O ṣiṣẹ titi ti imugbooro fi ba agbegbe to n ṣoju fun, o gba awọn to yira wọn pada kuro lọkunrin di obinrin, ati awon obinrin ti wọn sọ ara wọn di ọkunrin, pẹlu awọn ti wọn ko tiẹ ṣetan lati sọ boya akọ tabi abo lawọn. O mu wọn lọrẹẹ, to bẹẹ ti ẹka rẹ fi di eyi ti wọn lo tobi julọ ni US.
Kleinbaum fẹyinti lọdun yii, opo pataki lo jẹ nipa bi idajọ ododo yoo ṣe maa waye. Koda, Aarẹ Joe Biden yan an si ẹka to n ri si ki eeyan le ṣe ẹsin to ba wu u l'America.
Ayọ ni lati tako iṣesi ẹmi ati t'oṣelu.
Sharon Kleinbaum
Ayaworan ile
Lesley Lokko gba ami ẹyẹ goolu ilẹ Gẹẹsi ni 2024, nipasẹ iṣẹ aworan ile kikọ to yan laayo, eyi to fi n kede ijọba awarawa. Ami ẹyẹ to gba yii jẹ ọkan lara awọn eyi to ga ju lẹnu iṣẹ naa. Eyi si ti sọ ọ di obinrin akọkọ nilẹ Africa to gba ami ẹyẹ naa lati igba ti wọn ti da the Royal Institute of British Architects silẹ ni 1848.
O lewaju nipa mimu awọn eeyan ti ẹnu wọn ko to ọrọ wọ ileeṣẹ rẹ, o si ti le ni ogun ọdun to ti n ṣe eyi.
Obinrin ọmọ ilẹ Ghana to tun jẹ ọmọ Scorttish yii ni ọmọ ile Africa akọkọ lobinrin to gbe aworan ile rekete kalẹ, nibi to ti foju sun lilo eroja ibilẹ ati gbigba ominira lọwọ amunisin.
Oun lo da African Futures Institute, silẹ ni Accra, eyi to n ṣafihan ajọsepọ to wa laaarin ile kikọ, idanimọ ati ẹya.
Iduroṣinṣin ni pe ki eeyan ma yẹ ẹsẹ labẹẹ bo ti wu ko ri, koda lasiko ti nnkan ba buru ju lọ. Eyi ṣoro lati ṣe, koda, o le ju kikoku alatako lọ.
Lesley Lokko
Arinrinajo
Su Min, ẹni ọdun merindinlọgọta (56) n sa asala fun ẹmi rẹ , kuro lọdọ ọkọ to fẹ to n ṣe e baṣubaṣu. O bọ sọna irin ajo kaakiri China pẹlu mọto ayọkẹlẹ rẹ, apo to le ta bii atibaba pẹlu owo ajẹmọnu rẹ nikan.
Irinajo naa ti gbe e de ilu to le ni ọgọrun-un, ni awọn ipinlẹ to le ni ogun, latigba to ti n wa mọto rẹ kiri ni 2020.
O ti ṣe akọsilẹ gbogbo irin to ti rin, ọrọ rẹ si ti di ohun ti wọn n gba bi ẹni gba igba ọti lori ayelujara. Ọrọ rẹ jẹ iwuri fun awọn obinrin ti wọn ti n dagba lọjọ ori bii tirẹ, awọn ti awọn eeyan maa n sabaa pe ni anti lawujọ. O n jẹ ki wọn ni igboya ati koju irori to wa nilẹ.
O ti ni eeyan miliọnu mẹfa bayii ti wọn n tẹle e lori ẹka ayelujara rẹ gbogbo, wọn si ti sọ igbesi aye rẹ di sinima-Bii eyi ti wọn pe ni Rolling stone-ti wọn gbe jade lọdun yii.
Aránṣọ
Aṣa ati iṣe awọn eeyan Palestine lo jẹ iwuri fun Yasmeen Majali, ilana wọn lo fi n ṣiṣẹ aranṣọ tiẹ.
Leyin to dagba ni Guusu America, o pada si Ramallah, West Bank, nibi to ti da ileeṣẹ Nol Collective to jẹ tiẹ silẹ n1 2020.
O bẹrẹ si i ṣiṣẹ pẹlu awọn telọ ibẹ,awọn ti wọn n lo aro ibilẹ lati fi rẹ aṣọ, o si darapọ mọ alajẹṣẹku obinrin ti wọn n ranṣọ pọ. Awọn aranṣọ, awọn ti won n ko iṣẹ sara aṣọ ati bẹẹ bẹẹ lọ nilana Palestine ni Mjalli faramọ to si kọ gbogbo ẹ lọwọ wọn.
Mjalli ti fi aṣọ to n ran sọ itan Palestine, o ti fi sọrọ lorii iṣọro tawọn obinrin maa n koju kaakiri aye, eyi lo fi da aṣa kan silẹ ti won n sọ pe 'not your habibti' (not your baby'. Eyi to tumọ si pe ki i ṣe ọmọ rẹ. Wọn ti n kọ ọrọ naa si ara aṣọ bayii.
Akọ̀ròyìn
Hinda Abdi Mohamoud tó fẹ́ràn láti máa kọ nǹkan láti kékeré, ní ìwé tó fi ń kọ ìtàn nípa báwọn èèyàn ṣe ń sá kúrò ní ìlú rẹ̀, Hargeisa ní Somalia ní láàsìgbò tó ń wáyé níbẹ̀.
Òun ni olóòtú ìròyìn Bilan báyìí, iléeṣẹ́ ìròyìn tó jẹ́ ti kìkìdá àwọn obìnrin àkọ́kọ́ ní orílẹ̀ èdè náà.
Lójúnà àti kojú ìṣòro títẹ ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin lójú mọ́lẹ̀ àti ìfìyàjẹni táwọn obìnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ń kojú ló ṣe dá ikọ̀ ìròyìn náà sílẹ̀. Àjọ ìṣọ́kan àgbáyé, UN náà fìdí ìpèníjà táwọn èèyàn ń kojú náà múlẹ̀.
Èròǹgbà Bilan ni láti tọná sídìí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ tó ń wáyé ní ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tó léwu jùlọ fáwọn akọ̀ròyìn ní àgbáyé, pẹ̀lú kíkọ ìròyìn tó níṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Somali tó ń gbé ní àhámọ́ pẹ̀lú àìsàn HIV, àwọn ọmọ òrukàn tí wọ́n ń fìyà jẹ àtàwọn àfín táwọn èèyàn ìlú náà ti pa tì.
Ọkan lara awọn to da Monumental Welsh Women, silẹ
Ṣaaju ọdun 2021,ko si aworan tabi ere kankan ti wọn ṣe lorukọ awọn obinrin Welsh ti wọn wa ni Wales.
Helen Molyneux, jẹ ọkan lara awọn to da Monumental Welsh Women silẹ, ajọ kan ti ko si fun ere jijẹ, ṣugbọn to wa fun kawọn obinrin Welsh le maa kopa ninu ohun to ba n ṣẹlẹ lawujọ wọn, ki wọn si le maa yọ ayọ aṣeyọri wọn.
Pẹlu amọran ti awọn eeyan awujọ mu wa, Moluneux ati awọn ikọ rẹ ṣeto lati ṣe ere awọn obinrin marun-un, ki itan wọn ma baa di ohun ti aye yoo gbagbe.
Ẹgbẹ naa ti ṣe ere mẹrin bayii-akọkọ ni ti olukọ agba akọkọ ni Wales;Betty Campbell ni Cardiff, ikeji ni ti Elaine Morgan ti wọn ṣe si Mountain Ash, ikẹta ni ti Llangrannog ati Lady Rhondda ti wọn ṣe si Newport.
Ajafetọọ awọn akanda eeyan
Akanda eeyan ti aisan to pọ n ṣe ni Roxy Murray, ṣugbọn ki i fi eyi bo, o maa n sọ nipa boun ṣe nifẹẹ gbogbo eniyan lai wo ti ẹya, tabi iru eeyan ti wọn jẹ. Bakan naa lo maa n fi oju opo ayelujara rẹ ro awọn eeyan ti aisan n ṣe lagbara, o si maa n koro oju si awọn ti wọn maa n dẹyẹ si wọn lẹka ilera, aanu ati nileeṣẹ gbogbo.
Iṣẹ Murray tun kan bo ṣe mọ nipa oge ṣiṣe, o tun maa n ran awọn akanda lọwọ lati mọ bi won yoo ṣe lo nnkan iranwọ ti wọn nilo.Bakan naa lo maa n ran awọn ti ko riran lọwọ, ki wọn ma baa koju iṣoro lati ẹka kaakiri
O wa lara awọn to da eto 'The Sick and Sickening' silẹ, nibi ti wọn ti maa n sọ itan awọn ti wọn n gbele aye pẹlu ailera lai yọ ohunkohun kuro ninu itan naa. Wọn maa n sọrọ nipa bi wọn ṣe n ṣegun inira to n koju u wọn, titi de ori ibalopọ ati bi wọn ko ṣe ni i maa ri ibalopọ bii ohun ti ko daa.
Gẹgẹ bii akanda eeyan, iduro ṣinṣin ki i ṣe iṣẹ ẹnikan ṣoṣo, ajọsẹ ni. O da lorii ba o ṣe koju awọn ohun to n dẹyẹ si awọn eeyan bii temi.
Roxy Murray
Onkọwe ati Ogbufọ
Ọkan lara awon agba onkọwe lorilẹede Iran ni Shahrnush Parsipur, o ti kọ nipa ọpọlọpọ eewọ nipa ilu naa ninu awọn iwe rẹ. Awon bii bi wọn ṣe n tẹ obinrin loju mọlẹ lawujọ ofin to gbe ọkunrin.
O bẹrẹ iwe kikọ rẹ gẹgẹ bi alarosọ itan ati olootu ni ileeṣẹ tẹlifiṣan ati redio ijọba apapo Iran,ṣugbọn o kọwe fiṣẹ silẹ lati fi ẹhonu rẹ han nigba ti wọn pa awọn onkọtan meji ṣaaju iwọde ọdun 1979. Eyi lo si fa ẹwọn akọkọ ti obinrin yii kọkọ lọ.
Latigba ti ifẹhonuhan naa ti waye, wọn ti fi ofin de awọn iṣẹ rẹ rẹpẹtẹ, won si tun ju Parsipur si ẹwọn fun pe o sọrọ nipa ibale ninu iwe rẹ lai fi ti ọkunrin kun un. Won pada fi eyi ṣe fiimu ni ilu ti ki i ṣe Iran.
Parsipur ti fi iwe kikọ ṣalaye iriri rẹ nigba to wa lẹwọn, o si ti n gbe lẹyin odi , US lati ọdun 1994.
Adari ere, onkọtan ati ẹni to da ibudo afihan aṣa silẹ
Iya to ku diẹ ko pe ẹni ọdun marundinlọgọrun-un (95) yii ti gbe igbesi aye to lapẹẹrẹ gan-an.
Ogun meji lo ti t'oju rẹ waye ni Vietnam, o si ja fun ominira orilẹede rẹ kuro lọwọ France, nigba ti ko ti i ju ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16) lọ.
Gẹgẹ bo ṣe jẹ pe dokita ni, o ti dari ileewosan ri, o ti royin ogun ri fun ileeṣẹ amohunmaworan Vietnam, o si ri awọn nnkan manigbagbe bii igba ti wọn gba Saigon ti i ṣe olu ilu Vietnam.
Nigba to pe ẹni ọdun mejilelọgọta (62), kaka ki iya yii fẹyinti, niṣe lo da ibudo atẹ aṣa to pe ni Lotus Gallery silẹ. Eyi si jẹ ọkan ninu awọn ibudo aṣa to tobi ju ni ilu Ho Chi Minh. Iya loun fẹẹ fi aṣa ati iṣe Vietnam han gbogbo aye. Ọpọlọpọ awọn eeyan to fẹran aṣa ni mama ti kọ lohun to yẹ ki wọn mọ, o si ti ṣe bẹẹ gbayi, lokiki kaakiri agbaye.
Ologe aṣọ
Clandestina ni alaṣọ akọkọ to kọkọ da aṣọ rẹ ta lori ayelujara fun ọja agbaye ni Cuba, oun ati Idania Rio, ayaworan ni wọn jọ da a silẹ.
Wọn da ileeṣẹ naa silẹ nigba ti Aarẹ Raúl Castro, gbẹsẹ kuro lori ofin to de okoowo aladaani .
Agbarijọpọ awọn alaṣọ lobinrin ni wọn n ṣe oriṣiiriṣii aṣọ, ti wọn fi n gbe aṣa Cuba ga. Del Río lo gbe aṣa naa ga si i, to si fun wọn lọgbọn ti iṣẹ ko fi ni duro.
Akẹkọọ gboye lati ile ẹkọ Havana Institute of Design (ISDI) ni Rio, o maa n ṣe awọn iwe alẹsode fun ibudo aṣa, gbọngan sinima, ayẹyẹ ibilẹ ko too di pe o da ileeṣẹ aṣọ tirẹ silẹ.
Ẹni tó ń ṣe orò ìsìnkú
Láti bíi ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni Pooja Sharma ń ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún àwọn òkú tí wọn kò bá rí èèyàn bèèrè rẹ̀ ní Delhi.
Ìrírí rẹ̀ nígbà tí òun nìkan dá ṣètò ìsìnkú àbúrò rẹ̀ nígbà tí àwọn kan pa, tí kò ní olùrànlọ́wọ́ kankan ló bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣètò náà.
Ọ̀pọ̀ àwọn olórí ẹ̀sìn àtàwọn èèyàn ìlú rẹ̀ ló lòdì sí ohun tó ń ṣe yìí nítorí àwọn ọkùnrin ló máa ń ṣe ètò yìí ní ẹ̀sìn Hindu.
Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìdojúkọ yìí, ó ti ṣètò ìsìnkú fún èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin, tó sì máa ń ṣàfihàn rẹ̀ lórí ìkànnì ayélujára, bí ó ṣe ní pé gbogbo èèyàn ló ní ẹ̀tọ́ sí ẹ̀yẹ ìkẹyìn tó tọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde láyé.
Oludasilẹ ile ounjẹ
Bẹrẹ lati ile ounjẹ to wa fun eeyan mẹẹẹdogun pere, di bayii ti eeyan to le lẹgbẹrun marun-un ti n jẹun nibẹ loojọ, ohun kan ti awọn eeyan mọ Margarita Barrientos fun lorilẹede Argentina ni pe ko fẹ ki ebi pa ẹnikẹni. Ida mẹtalelaadọta (53%) eeyan ni akọsilẹ sọ pe wọn n gbe ninu iṣe ati oṣi bayii ninu eeyan miliọnu mẹrindinlaadọta (46m) to n gbe ni Argentina.
Ọkan lara awọn agbegbe to talika ju niluu naa ni wọn ti bi Barrientos, lati kekere lo si ti n koju iṣoro. Funra rẹ lo da ile ounjẹ tiẹ silẹ ni Los Piletones ni 1996, ile ounjẹ naa lo si ti waa gbooro bayii, to ti ni ẹka ti wọn ti n tọju awọn ọmọde, abala ilera, ẹka ẹkọṣẹ aṣọ riran ati abala ikawe.
Iṣẹ ilu to n ṣe yii ti n ri itẹwọgba ati atilẹyin lati ọdọ awọn olokoowo ati awon gbajumọ eeyan. Laipẹ yii ni gbajugbaja agbabọọlu nni, Lionel Messi, fun un ni aṣo kan to buwọ lu lati ta .
Alabojuto ibudo aṣa
Ki awọn nnkan iṣẹmbaye to wa ni Kyrgyzstan ma parun lo jẹ obinrin yii, Zhanylsynzat Turganbaeva logun.
O da ile iṣembaye kan silẹ ni Bishkek, nibi ti wọn n ko awọn nnkan aṣa ilu naa si, ti ọpọ eeyan si maa n waa fi owo wo lasiko irin ajo afẹ.
Ọkan lara awọn iṣe aanu to n ṣe ni dida aabo bo awọn iwe Kyrgyz, titi de ori Manas to sọ nipa itan akọni kan to so ẹya ogoji pọ ni Kyrgyz.
Apa kan ṣoṣọ ewi akọsilẹ UNESCO to ẹẹdẹgbẹta ila nipa iṣẹ yii, oun ni wọn lo gun ju lagbaaye. ( O gun ni ọna ogun ju 'The Odyssey' lọ. Iṣẹ iya yii maa n pese anfaani, o si maa n wulo fun awọn adanilaraya to ba n lo o.
Aṣoju loge
Lẹyin ti wọn fidi ẹ mulẹ pe o ti ni arun alopecia ti ki i jẹ ki irun hu lori obinrin, Olivia McVeigh bẹrẹ si i ṣe iwadii lorii wiigi. O n ṣawari awọn ọna irun mi-in, o si n fi awọn irun atọwọda da ara oriṣiiriṣii. O da oju opo kan silẹ lori ayelujara, nibi to ti n ro awọn obinrin to ba ni iṣoro ai nirun lori naa lagbara, to si n fi ọkan wọn balẹ.
Awọn olutẹlẹ to ni lori ayelujara ferẹ to idaji miliọnu, o so lilo wiigi di nnkan to yẹ, o si n la awọn loye lori arun alopecia ati ilera awọn obinrin.
McVeigh, aṣojuloge ati awokoṣe fun awọn eeyan, wa lati Northern Ireland. Ọmọge lo wa nigba to bẹrẹ si i padanu irun ori rẹ, ti irun naa n re jẹ.
O ti n ṣe idanilẹkọọ bayii nipa irun atọwọda ti a mọ si wiigi, o si n da awọn obinrin lọkan le lati ma ṣe kọ iyan ara wọn kere nitori iṣoro alopecia. O n mu ki awọn obinrin ti wọn ni alopecia wa papọ, ki kaluku si maa ṣalaye iriri rẹ nipa irun wọn to n re jẹ.
Iduroṣinṣin ni ade ori ti awọn obinrin n de. Titi aye la maa n gba ohun to ba de mọra, a le ṣe ayipada ka si gba ohun to ba n ṣẹlẹ layika wa mọra, bo ti wu ki kinni ọhun ri.
UK
Aranṣọ ati oniṣowo
Lọdun meji sẹyin,Dilorom Yuldosheva, padanu ẹsẹ rẹ mejeeji ninu ijamba kan to ni lasiko to n ko ere iṣe oko. Ṣugbọn eyi ko di i lọwọ lati ni afojusun rere
O fẹ lati kọ iṣẹ ọwọ tuntun bo ṣe n ran awọn ọdọbinrin Uzbek lọwọ nipa bi wọn ṣe le maa ri ounjẹ jẹ, fun idi eyi, o pinnu lati da ileeṣẹ aṣọ riran tirẹ silẹ.
O kọ nipa okoowo ati bi a ṣe n sọ ookan di eeji, o si ṣe bẹẹ kọ ọmọọṣẹ to le logoji niṣẹ. Laaarin oṣu diẹ, ileeṣẹ rẹ gbooro gidi, o bẹrẹ si i kọ awọn eeyan lọfẹẹ, o si n gba iṣẹ aṣọ riran fun awọn oṣiṣẹ ati awọn ọmọ ile ẹkọ lọpọ yanturu.
Okoowo rẹ ti di ohun to n pawo wọle fun un tipẹ, bẹẹ lo si n pawo fun ọpọlọpọ awọn obinrin mi-in naa.
Elere idaraya to n ran bi okoto
Ami ẹyẹ mẹfa ti Rebeca Andrade ti gba lo sọ ọ di ẹni to gba ami ẹyẹ ju ninu idije Olympic ni Brazil ( O tun ni ami ẹyẹ mẹsan-an mi-in to jẹ ti agbaye)
O gba ami ẹyẹ goolu ni Paris ni 2024, nigba to fẹyin Simon Biles nalẹ. Biles ati Jordan Chiles teriba fun Rebeca lẹyin idije naa, eyi to kari ayelujara kia, to si di ami idije Olympics ọdun yii.
Ọmọ mẹjọ ni Iya Rebeca Andrade bi, ọmọ ọdun mẹwaa lo wa to ti n kọ nipa ere idaraya ti wọn ti maa n ran bi okoto yii. Ile onile ni iya rẹ ti ko lọkọ maa n tunṣe to si n fi owo rẹ ran Rebeca lọ sibi ẹkọ ere idaraya to sọ ọ di ọga bayii.
O ti fara ṣeṣe lọpọ igba, o si ti sọrọ lorii bi ilera opọlọ ṣe jẹ pataki to.
Bí a bá ṣe mójútó àwọn nǹkan tó bá ṣẹlẹ̀ sí wa àti ṣíṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó wà pẹ̀lú wa, láti máa rí ohun tó dára nínú àìda ni ìfarajìn.
Rebeca Andrade
Eléré ìdárayá
Allyson Felix ni eléré sísá tó ti gba àmì ẹ̀yẹ jùlọ nínú ìtàn pẹ̀lú gbígba mẹ́dàlì ogún ní ìdíje World Championship àti mẹ́dàlì Olympic mọ́kànlá.
Lẹ́yìn tó ní pre-eclampsia àti bíbí ọmọ rẹ̀ nígbà tí oṣù rẹ̀ kò pé, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìpolongo fún ìlera ìyá àti àwọn ọmọ ọwọ́. Ó ti rí ogún mílíọ̀nù dọ́là gbà láti ọwọ́ àjọ Melinda Franch Gates láti fi tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìlera ìyá àti ọmọ fáwọn aláwọ̀ dúdú ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà.
Eléré Ìje tó ti fẹ̀yìntì wá lára àwọn tó mú ṣíṣe ìfilọ́lẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé wáyé níbi ìdíje Olympic tó wáyé ní Paris lọ́dún 2024.
Bákan náà ni wọ́n tún yàn án sí ìgbìmọ̀ International Olympic Committee Athletes' Commission lọ́dún yìí, tó sì tún ṣe ìfilọ́lẹ̀ iléeṣẹ́ tó ń rí sí eré ìdárayá fáwọn obìnrin.
Níní ìfarajìn jẹ́ wíwá okun àti agbára láti kojú ìpèníjà gbogbo àti lílo gbogbo ìjákulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ láti tẹ̀síwájú.
Allyson Felix
Akanda ẹda to n ṣe ere idaraya Taekwondo
Zakia Kuhdadadi ni ẹni akọkọ ninu awon akanda ẹda to wa nibudo ogunlende ti yoo gba ami ẹyẹ, o fi itan balẹ ninu idije to waye ni Paris ni 2024.
Zakia ti wọn bi lai ni apa kan, bẹrẹ si i kọ nipa Taekwondo nigba to wa lọmọ ọdun mọkanla. O n yọ ọ ṣe ni, nile idaraya kan to wa niluu rẹ ti i ṣe Herat, ni Iwọ-Oorun Afghanistan.
Wọn ko kọkọ gba fun un lati kopa ninu idije awọn akanda to waye ni Tokyo, lẹyin ti awọn Taliban gbajọba ni 2021.
Ṣugbọn pẹlu idasi ajọ International Paralympic Committee ati atilẹyin France, wọn ri i gbe kuro ni Afghanistan, o si di obinrin akọkọ ni Afghan to kopa ninu ere idaraya lagbaaye, lẹyin ti awọn Taliban gbajọba.
Irin ajo mi debi ti mo ti gba ami ẹyẹ Olympic, fi agbara iduroṣinsin awọn obinrin Afghan han. Agbara awọn obinrin to n gbe ni ibudo ogunlende, ati ti obinrin kọọkan. Nipa aiko aarẹ ọkan, a fi han pe ko sohun tobinrin o le se.
Zakia Khudadadi
Akọrin
Ọkan ninu awọn eekan olorin ni Pakistan ni Hadiqa Kiani, awọn eeyan mọ ọn si ẹni ti ohun ẹnu rẹ dun to si le lo o lọna to pọ, bẹẹ lo si tun maa n da si ọrọ ọmọniyan, ti ohun gbogbo yoo fi ri bo ṣe yẹ.
Nnkan bii ọdun 1990 ni okiki rẹ buyọ, o di ogunna gbongbo lagbo orin awọn obinrin, o si tun di aṣoju ajọ United Nations lori eto kan.
Nigba ti ẹkun omi ṣọṣẹ ni Pakistan ni 2022, Kiani da ajọ kan silẹ to pe ni Vaseela-e-Raah, eyi to wa fun riran awọn ti ijamba kan lọwọ, ni agbegbe Balochistan ati Guusu Punjab.
O rọ awọn eeyan lati ran awọn ti ko rile gbe lọdun naa lọwọ, ajọ rẹ naa kede pe awọn ti kọ ile to le ni ọọdunrun (370) si awọn agbegbe ti ẹkun omi naa ti ṣọṣẹ.
Olórin
Kíkojú àwọn nǹkan tó ti dàbí àṣà àti ẹ̀sìn jẹ́ ohun tó rọ Firda Marsya Kurnia lọ́rùn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti ẹni tó máa ń ta gìtá nínú ẹgbẹ́ akọrin tí gbogbo wọn ń wọ hìjáàbù, Voice of Baceprot.
Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, tó ń fi èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Sudanese - ọ̀kan lára èdè tí wọ́n ń sọ ní Indonesia- kọrin ń fi orin sọ̀rọ̀ nípa báwọn ọkùnrin ṣe jẹ gàba lórí àwùjọ.
Àwọn Mùsùlùmí kan ni bí àwọn akọrin náà ṣe ń lo irin gẹ́gẹ́ bí ohun èlò orin wọn kò tẹ́ lọ́rùn.
Àmọ́ ẹgbẹ́ akọrin náà kò kó àárẹ̀ ọkàn láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ wọn ní Garut, West Java. Wọ́n kọrin níbi ayẹyẹ àjọdún orin Indonesia, Glastonbury tó ti ń wáyé láti ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta sẹ́yìn.
Elere ije
Ẹnikan ti aye ti ba ṣe ajọyọ fun jijẹ elere ijẹ to si le sare pupọ ni Joan Chelimo,ọmọ orilẹede Kenya mọ Roamnia. O gba ami ẹyẹ Fadaka nibi idije European Championship ọdun yii, nibi to ti sare olopoo gbọọrọ idaji ti a mọ si 'half marathon'
Yatọ si ere idaraya, ẹni to ti jiya nipa jijẹ obinrin ni, o si wu u lati fi iriri rẹ kọ awọn eeyan nipa idunkooko to maa n koju awon elere ije.
O wa lara awọn to da ẹgbẹ Tirop's Angel silẹ ni Kenya, iyẹn ẹgbẹ kan to wa fun awọn elere ije, lẹyin iku elere ije bii tiẹ, Agnes Tirop toun naa gba ami ẹyẹ agbaye ti wọn pa ni 2021. Ẹgbẹ yii maa n gbẹnusọ fun awọn obinrin, paapaa labala iya to maa n jẹ wọn nitori wọn jẹ obinrin.
Lọdun yii, iku to pa elere ijẹ Olympic, Rebecca Cheptegei, lati ọwọ ọkọ to n fẹ tẹlẹ, tubọ jẹ ki ipe pọ si i, pe kawọn alaṣẹ dide si bi wọn ṣe n pa awọn obinrin.
Mo gbagbọ pe ayipada gidi maa n bẹrẹ nigba ti a ba pinnu pe inira ti a koju kọ ni opin aye wa, ṣugbọn ibẹrẹ ohun to daa ju bẹẹ lọ lo ni.
Joan Chelimo Melly
Olorin ati awoye ayipada oju ọjọ
Ẹni to n pe fun ẹtọ lori ayipada oju ọjọ, olorin ati elere ori itage ni Inna Modja. O ti kede tako abẹ-dida fun ọmọbinrin, ko si fẹ irẹjẹ
Oun lo kọ Great Green Wall to si tun kopa nibẹ, iyẹn iṣẹ kan to sọro nipa bi aṣalẹ ilẹ Africa ṣe ri igbedide. Eyi jẹ agbegbe kan to wa ni Guusu aṣalẹ Sahara, to kọja lati Ila-Oorun de Iwọ-Oorun fun orilẹede mejila.
Gegẹ bii aṣoju ajọ UN lorii bi awọn ohun to wa loko aṣalẹ ko ṣe ni i parẹ, Modja ko dakẹ nipa bi awọn eeyan yoo ṣe mọ nipa ayipada oju ọjọ.
O tun jẹ ọkan lara awon to da ajọ Code Green silẹ, ajọ ti ki i ṣe tijọba, to n pa imọ ẹrọ pọ mọ didẹ igbẹ, lati mu ayipada rere waye.
Iduroṣinṣin la fi n sọ awọn obinrin ati awọn ọdọbinrin di aṣiwaju, ti yoo si mu ojutuu wa si iṣoro.
Inna Modja
Akọrin
Akọrin foge jo ni Gaby Moreno lagbo orin Latin, oun lo gba ami ẹyẹ Grammy gẹgẹ bii olorin sufee-taka to peregede julọ ni 2024.
Orin to kọ pẹlu ede meji, to si tun mu awọn ilana American dani, ṣafihan ohun Gaby ati bo ṣe jinlẹ to ninu orin ibilẹ rẹ.
Moreno tun ni ẹni akọkọ ni Guatemala to di aṣoju ajọ UNICEF, to n kede ẹtọ awọn ọmọde.
Laipẹ yii lo ṣe ifilọlẹ ipolongo kan to fi kede pe ki wọn jẹ ki ipese nnkan eelo ẹkọ pọ si i, lorilẹede ti eeyan 2.7m jẹ ọdọkunrin, ti awọn obinrin ko si kawe.
Olorin sufee-taka
Olorin sufee-taka ni Noella Wiyaala Nwadei, orukọ ti wọn mọ ọn si ju ni Wiyaala, eyi to tumọ si ẹni to n ṣe nnkan, ledee Sissala.
Awon eeyan mọ obinrin yii fun jijẹ alafẹ nibi imura, ati awọn ẹṣọ ara to maa n lo, eyi to fi n kede ibi to ti wa, ti i ṣe Ariwa orilẹede Ghana.
Ọpọlọpọ orin rẹ maa n da lorii bi wọn ṣe n yan awọn obinrin Africa jẹ. Wiyaala ti ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ UN ati awọn alaṣẹ ilẹ Ghana, lati gbogun ti fifi ọmọdebinrin lọkọ.
O tun ti kọ ile aṣa, ileeṣẹ redio ibilẹ ati ile ounjẹ lati pese iṣẹ fawọn eeyan, ati lati mu ọgbọn atinuda waye ni ilu abinibi rẹ ti i ṣe Funsi.
Elere idaraya Archer
Ọrẹkunrin Tracy Otto lo waa ba a ja nile ni 2019, obinrin naa si ṣe bẹẹ di ẹni ti ko le gbe apa rẹ mọ, o si tun padanu oju rẹ osi ninu ija naa. Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, o pinnu lati gbele aye, ko si pada jafafa.
Ni oṣu kẹta ọdun 2021, Otto bẹrẹ ere idaraya kan ti ko ṣe iru rẹ ri-archery lorukọ ere naa. O ta ọfa akọkọ o si ba ohun to ta a mọ
Lọdun yii,Otto dije ni Paris, akọkọ idije rẹ gẹgẹ bii akanda. Nitori ailera rẹ,ẹnu lo fi ta ọfa.
O ti fẹrẹ pe ọdun marun-un bayii ti Otto ti n lo iriri rẹ lati ja fun awọn eeyan to koju ijiya ninu igbeyawo.
Eléré ìjàkadì
Ẹni tó ti gbégbá orókè ní ìdíje Olympic ní ẹ̀ẹmẹta, Vinesh Phogat jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ India tó ń ja ìjàkadì tó ti gba àmì ẹ̀yẹ jùlọ. Bákan náà ló máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìdẹ́yẹsí àwọn obìnrin lẹ́ka eré ìdárayá ní India. Ó ti gba mẹ́dàlì ní ìdíje World Championship, Commonwealth àti Asian Games.
Lọ́dún yìí ni Phogat di obìnrin àkọ́kọ́ eléré ìjàkadì ọmọ orílẹ̀ èdè India tó dé ipele àṣekágbá ní ìdíje Olympic àmọ́ pàdánù nítorí kò wọn iye ìwọ̀n tó yẹ. Lẹ́yìn náà ló fẹ̀yìntì nínú eré ìdárayá tó sì ti darapọ̀ mọ́ òṣèlú.
Phogat léwájú ìfẹ̀hónúhàn oṣù kan gbáko táwọn eléré ìjàkadì ṣe tako ọ̀gá àgbà àjọ náà, Brij Bhushan Singh fẹ́sùn pé ó ń fi ìbálòpọ̀ lọ àwọn obìnrin tó jẹ́ eléré ìdárayá - Singh jiyàn ẹ̀sùn náà.
Ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn náà gba orí gbogbo ìwé ìròyìn nígbà tí àwọn ọlọ́pàá fi Phogat àtàwọn míì sí àhámọ́ nítorí ìwọ́de náà.
Ìgbìyànjú láti dìde lẹ́yìn tí nǹkan kò bá lọ déédéé lẹ́nu iṣẹ́ àti láti fún ara èèyàn ní ìrètí ni ìfarajìn jẹ́.
Vinesh Phogat
Akọrin
Akọrin ni Raye, bẹẹ lo tun maa n kọ orin ta pẹlu, yatọ si pe ko fi ẹnu kọrin. Ẹbun mẹfa lo gba ninu meje ti wọn fa a kalẹ fun lọdun yii nibi ayẹyẹ ti wọn n pe ni Brit. Eyi ti sọ Raye di obinrin akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ akọrin naa
Ni 2021,Raye kede lori ayelujara, pe ọdun keje toun ti n ba ileeṣẹ toun n ṣe orin fun ja ree, iyẹn Poludor, nitori awo orin toun fẹẹ ko gbe jade.
O gbe awo akọkọ to pe ni My 21st Century jade loun nikan ni 2023, o si ṣe daadaa lọja.
Raye ti sọrọ nipa iṣoro to koju lagbo orin ati lawujọ, titi to fi mọ igbiyanju lati ba a ṣe iṣekuṣe, aṣilo oogun ati aleebu ara. Bakan naa lo ni ki wọn maa sanwo to daa fun awọn ti wọn n kọrin ta .
Osere ori itage
Oṣere Hend Sabry jẹ okan lara awọn gbajugbaja elere ori itage lagboo sinima ilẹ Arab. Ere kan ti wọn ṣe nipa awọn obinrin, ti wọn pe ni The Silences of the Palace, ni ọdun 1994 lo gbe e jade. Ere naa ṣalaye nipa adojukọ tawọn obinrin maa n ri nipa ibalopọ ni Tunisia.
Oun ni obinrin akọkọ nilẹẹ Arab to di adajọ nibi ayẹyẹ sinima ti wọn ṣe ni 2019
Laipẹ yii lo kopa ninu ere Olfa's Daughters, ti wọn sayan fun ami ẹyẹ Oscar niTunisia, ti wọn si tun fa kalẹ gẹgẹ bii iṣẹ to daa ju .
Losu kọkanla, Sabry fẹyinti gẹgẹ bii aṣoju UN, o ni oun fi tako iya ti wọn fi n jẹ Gaza logun.
Ki i ṣe ti ba o ṣe yè,ba o ṣe tun un ṣe ta o si tun ri koko ohun ti a n ṣe nipasẹ igbiyanju lo ṣe koko. Bi a o ṣe dide girii, sọ inira to n koju u wa.
Hend Sabry
Akọrin
Lasiko kan ti ko si ẹni to fẹẹ gbọ ohun obinrin lawujọ ni Afghanistan, Elaha Soroor to jẹ olorin, kọ orin kan to pe ni Naan, Kar, Azadi, eyi to tumọ si burẹdi, iṣẹ ati ominira. O kọ orin naa lati le dẹkun ijẹgaba, ko si le jẹ koriya fun awọn to nilo rẹ.
Wọn ṣafihan orin naa loṣu Kewaa, nibi ipade awọn obinrin All-Afghan ti wọn ṣe ni Albania.
Ninu iṣẹ ere ori itage ṣiṣe ati orin kikọ ti Soroor n ṣe ni obinrin to ti gba ami ẹyẹ naa ti maa n ja fun ẹtọ awọn obinrin.
Soroor to wa lati ẹya kekere ti a mọ si Hazara, di ẹni ti aye mọ ni 2009, lasiko ayẹyẹ ifigagbaga kan ti wọn ti n ṣafihan ẹbun awon eeyan . Ṣugbọn ọpọ eeyan lo koro oju si orin kikọ to yan laayo lorilẹede yii, o si fi ilu naa silẹ ni 2010.
Elere ori itage
Gbajumọ oṣere ni Sharon Stone l'America, o ti di gbjugbaja lori itage ati lẹrin rẹ paapaa ju ọgbọn ọdun sẹyin lọ.
Niberẹ ọdun 1990 ni okiki rẹ buyọ, pẹlu ere kan ti wọn pe ni 'Basic Instinct'. O kopa nla ninu Total Recall ati Casino, nibi to ti gba ami ẹyẹ ti wọn si forukọ rẹ ranṣẹ fun idije Oscar.
Bo ṣe n ṣiṣẹ ere ori itage naa lo tun jẹ ẹlẹyinju aanu to n ran ọpọ eeyan lọwọ. Nobel Laureates mọ riri anawọsi rẹ yii, won si fun un ni ami ayẹ fun ipa to n ko lati ran awọn eeyan to ni arun HIV lọwọ.
Niberẹ ọdun yii, o tun gba ami ẹyẹ Golden Globe International Icon Award.
Bi o ba wu ọ lati duro ṣinṣin, wa a duro. O gbọdọ yan bi nnkan yoo ṣe lọ.Ninu ki wọn pa o layo tabi ko o yan ayọ.
Sharon Stone
Atokun eto ati arinrinoge
Bo ṣe kopa ninu ipolongo 'Assume That I Can', fidio ti Madison Tevlin ṣe lọdun yii kari aye, o si ya ọpọ eeyan lẹnu. Fidio naa pa awon to n foju abuku wo awon akanda eeyan ti wọn ni aisan Down syndrome lẹnu mọ.
O le ni eeyan aadoje miliọnu (150m) to wo ipolongo naa, bẹẹ lo si tun gba ami ẹyẹ fun ipa rere to ni, titi to fi mọ kinniun wura to gba nibi ayẹyẹ Cannes Lions Festival.
Oṣere ati arinrin oge Tevlin ti kopa ninu idije New York Fashion Week, o ti sọro lorii ti Clinton Global Initiative ati bo ṣe gba ami ẹyẹ Quincy Jones Exceptional.
O ti dari eto Who Do You Think I Am to gba ami ẹyẹ, ati ti onibeere mọkanlelogun.
Iduroṣinṣin ni pe mi o ni i jẹ ko su mi, koda bi wọn da mi lẹjọ tabi wọn foju abuku wo mi. Ki n duro lori ohun ti mo gbagbọ ni itumọ re, ki n si ma ja ara mi kulẹ tabi agbegbe mi.
Madison Tevlin
Adẹ́rìnínpòṣónú
Naomi Watanabe ti ṣí ọ̀nà fáwọn obìnrin aláwàdà ní orílẹ̀ èdè rẹ̀ bí ó ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèkàn orílẹ̀ èdè Japan.
Ó ti mú àyípadà bá ẹ̀ka eré ìdárayá àwàdà ṣíṣe tó jẹ́ pé àwọn ọkùnrin ló máa ń ṣe é jùlọ ní Japan nípa ṣíṣe àgbékalẹ̀ àwọn ayẹyẹ.
Watanabe tún ń ṣe àyípadà nípa ẹ̀yà ara, bí ó ṣe ń ṣáájú ìpolongo fún kí àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ bí ara wọn ṣe rí pẹ̀lú pochakawaii tó túmọ̀ sí sísanra àti ẹwà. Ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ tó ń pèsè aṣọ fáwọn tí wọ́n bá sanra.
Lẹ́yìn tó ṣe àṣeyọrí lẹ́ka iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán àti fíìmù Japan. Ó ti kó lọ sí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà báyìí láti gbé iṣẹ́ adẹ́rìnínpòṣónú rẹ̀ wọ àgbáyé.
Báwo ló ṣe ń ní ìfarajìn? Mo máa ń rò ó pé tí èèyàn kò bá fẹ́ràn mi, kò ṣe nǹkankan. Ẹ fún mi ní ọdún kan, bóyá ọkàn rẹ máa yípadà. Ohun tí mo máa fi sọ́kàn nìyẹn.
Naomi Watanabe
Onibọn Olympic
Jijẹ aṣiwaju ati aṣeyọri rẹ ninu ere idaraya lo sọ Kim Yeji di ilu mọ ọ ka lọdun yii.
Obinrin to yinbọn ilewọ nibi idije Olympics loṣu Keje ọdun yii, eyi to wa fun awọn obinrin fun iṣẹju mẹwaa naa fitan balẹ, lẹyin to yege lagbaaye ni ti oniṣẹẹju mẹẹẹdọgbọn loṣu diẹ sẹyin.
Ko pẹ rara ti awọn fidio rẹ fi gba ori ayelujara kan, awọn eeyan n gboriyin fun un pe o mọṣẹ, wọn tun ni ara rẹ balẹ pupọ, o si fi oju si ohun to n ṣe gidi pẹlu afojusun ti ko tase.
Kim Yeji ti sọrọ lori ojuṣe rẹ gẹgẹ bi iya. O si ti gba asiko isinmi lati wa pelu ọmọ rẹ obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹfa, lati lo akoko pẹlu rẹ, ko si ṣe ojuṣe iya fun un.
Nipasẹ ere idaraya, a n ṣafihan iduroṣinṣin, ifọwọsowọpọ ati ipinnu. Loju iwoye temi, awọn nnkan wọnyi kọja ohun ti a n lo lori papa iṣere nikan, a le fi mu ayipada ba awujọ wa lapapọ naa.
Kim Yeji
Agbábọ́ọ̀lù orí tábìlì
Gbábọ́ọ̀lù orí tábìlì, Zhiying Zeng tàbí Tania kópa níbi ìdíje Olympic fún ìgbà àkọ́kọ́ ní 2024 Paris lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gọ́ta.
Ìgbà tó ti wà ní ọmọ ọdún méjìlá ló ti ń gbá bọ́ọ̀lù orí tábìlì gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́, tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ akọnimọ̀ọ́gbá rẹ̀. Àsìkò tó yẹ kó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù orí tábìlì ti China ló kó lọ sí Chile, níbi tó ti pa eré ìdárayá tì fún ọgbọ̀n ọdún láti gbájúmọ́ àwọn okoòwò rẹ̀.
Àjàkálẹ̀ àìsàn Covid-19 ló jẹ́ kí Tania Zeng padà sí ìdí eré ìdárayá orí tábìlì.
Nígbà tó di ọdún 2023, wọ́n gbe sí ipò obìnrin tó dára jùlọ nídìí eré ìdárayá ní Chile tó lọ ṣojú orílẹ̀ èdè náà ni ìdíje South American Championship àti Pan American Games kó tó di pé ó pegedé fún ìdíje Olympic.
Adarí eré
Ògbóǹtarìgì adarí eré fíìmù àti òǹkọ̀wé ni Chloé Zhao tó ti gba àmì ẹ̀yẹ Oscar. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn obìnrin mẹ́ta tó ti gba àmì ẹ̀yẹ adarí eré tó dára jùlọ.
Zhao, tí wọ́n bí ní ìlú Beijing, kó lọ sí orílẹ̀ èdè UK àti Amẹ́ríkà. Ó máa ń júwe ara a rẹ̀ bíi ẹni tó máa ń rìn ká, láì ní ibùjókòó kan pàtó. Ó ti fi eré fíìmù rẹ̀ kan tó gba àmì ẹ̀yẹ sọ ìrìnàjò yìí, Nomadland (2020).
Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ṣíṣe ojú agbègbè rẹ̀ di adarí eré tó làmì laaka káàkiri àgbáyé. Zhao ní òun ní ìfarajìn sí ohun tó so èèyàn pọ̀.
Ní ọdún yìí, ó ń ṣiṣẹ́ lórí dídarí eré àtúnṣe Maggie O'Farrel ìwé eré Shakespeare, Hamnet tí wọ́n máa gbé jáde lọ́dún 2025.
Tí a kò bá ṣe àyípadà ẹ̀ka iléeṣẹ́ tí a ti ń ṣiṣẹ́, à ń sọ pé a nílò láti rí bíi àwọn ọkùnrin kí a tó le ní ipa. Mi ò rò pé ibi tí agbára wa wà nìyẹn.
Chloé Zhao
Ajafẹtọọ awọn akọ to n fẹ ẹgbẹ wọn, abo to n fẹ obinrin ẹgbẹ wọn
Bi orilẹede Thailand ṣe sọ aba kan to sọ igbeyawo di bakan naa di ofin lọdun yii, ti wọn si di orilẹede akọkọ to ṣe bẹẹ ni Guusu -Ila-Oorun Asia, ayọ nla lo jẹ fun Ann 'Waaddao' Chumaporn
O ti gbiyanju titi lati ri i pe aba naa di ofin nile igbimọ, bo ti n ṣiṣẹ bii ẹni to n yẹ ofin wo lori rẹ nile igbimọ aṣoju naa lo n ṣe ni ti aṣofin.
Ọkan lara awọn to da ẹgbẹ Bangkok pride to n ja fun awọn ọkunrin to n fẹ ọkunrin ẹgbẹ wọn, ati awọn abo to n fẹ abo ẹgbẹ wọn ni Thailand ni . O ti le lọdun mẹwaa bayii ti Chumaporn ti n ja fun awọn eeyan yii, pe ki wọn maa fun wọn ni ẹtọ wọn.
Lasiko ti awọn ọdọ n fi ẹhonu han ni Thailand ni 2020, oun lo lewaju ninu iwọde to n kede ominira fun awọn obinrin. Ẹsun oṣelu mẹjọ ni wọn fi kan an fun ipa to ko ninu ijangbara.
Ajafẹtọọ awọn ti wọn ba n fipa ba lo pọ loju ogun
Gẹgẹ bii adari ajọ kan, Strategic Initiative for Women in the Horn of Africa(SIHA), gbajugbaja onkọwe, Hala Alkarib, lo maa n lewaju awọn eto to kan obinrin kaakiri ẹkùn.
Latigba ti ogun ti bẹ silẹ ni Sudan loṣu kẹrin ọdun 2023, SIHA ko niṣẹ meji ju ki wọn maa ṣe akọsilẹ ibi ti won ba ti fẹẹ fipa mu obinrin fun ibalopọ lọ, bẹẹ ni wọn n ṣe iranlọwọ fun awọn agbalagba obinrin ati awọn ọmọdebinrin pẹlu.
Abajade iwadii UN kan ni 2024, kilọ nipa iṣoro yii, bakan naa ni wọn fi ẹsun kan awọn Rapid Support Forces (RSF), pe awọn ni wọn n hu iwa ọdaran,ṣugbọn RSF sọ pe ko sọhun to jọ bẹẹ.
Abajade naa so pe o kere tan, irinwo eeyan (400) ti wọn foju wina ti wọn si ja ajabọ ni wọn ti ran lọ sibi ti wọn yoo ti gba itọju, iyẹn loṣu Keje ọdun 2024. Wọn ṣapejuwe eyi gẹgẹ bii onka to n mu ẹyẹ bọ lapo, ti bẹbẹ ṣi n bẹ niwaju fun.
Olori ẹgbẹ oṣelu Conservative
Kemi Badenoch ni eeyan dudu akọkọ to jẹ obinrin ti wọn yan lati dari ẹgbẹ oṣelu nla lorilẹede UK. Oṣu Kọkanla ọdun 2024 ni wọn yan an sipo naa.
Lọwọlọwọ yii, ọmọ ile igbimọ ni Kemi jẹ ni North West Essex, o si ti figba kan ri jẹ akọwe okoowo ati minisita to n ri ri ọrọ awọn obinrin ati ṣiṣe deede.
Ilu London ni wọn ti bi Kemi Bedenoch, bo tilẹ jẹ pe ọmọ Naijiria ni awọn obi rẹ. Ilu Eko lo dagba si, ko too pada si ilẹ UK nigba to wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun (16), nitori bi oṣelu ati ọrọ aje Naijiria ṣe n da oju ru ni Kemi fi kọri si UK ti wọn bi i si nigba naa, o si lọọ kawe nipa imọ irọ ati imọ ofin.
Ko too bẹrẹ oṣelu, o ti figba kan jẹ ọkan lara awọn adari banki aladaani, o si tun dari lẹka iwe iroyin 'The Spectator'.
Onisegun oyinbo ati oloṣelu
Ọkan lara ẹgbẹlẹgbẹ obinrin to n kopa ninu iwọde ni Pakistan ni Mahrang Baloch, wọn n wọde lati fi ẹhonu han fun bawọn eeyan ṣe n di awati ni ẹkun-un Balochist.
O bẹrẹ si i kede idajọ ododo lẹyin ti wọn ni awọn agbofinro mu baba rẹ ni 2009, ti wọn si ri oku rẹ lẹyin ọdun meji pẹlu apa ifiyajẹni lara rẹ.
Nigba ti 2023 n pari lọ, Baloch lewaju ọpọlọpọ obinrin lati rin irin maili ẹgbẹrun kan lọ si Olu ilu ti i ṣe Islamabad, lati beere nipa ibi ti awọn ẹbi wọn wa. Ẹẹmeji ni wọn fi ofin gbe e laaarin irin naa.
Ohun ti awọn oluwọde naa n sọ ni pe awọn agbofinro Pakistan ti ji awon eeyan awọn gbe, wọn si ti pa wọn.Ṣugbọn awọn alaṣẹ ni Islamabad sọ pe ko sohun to jọ bẹẹ.
Latigba naa ni dokita oniṣegun oyinbo yii ti di ajijagbara ati ajafẹtọọ to gbajumọ, labẹ ẹgbẹ rẹ to pe ni Baloch Yakjehti (Unity) Committee BYC. Iṣẹ ajafẹtọọ to n ṣe yii di itẹwọgba, nigba ti wọn ka a mọ TIME 100 Next 2024, ninu awọn olori to farahan.
Ajafun ẹtọ awọn aṣẹwo
Lourdes Barreto jẹ opo pataki lẹyin ẹtọ awọn aṣẹwo, o ti lo pupọ ninu aye rẹ fun ipolongo ẹtọ to yẹ fun awọn oniṣẹ nabi ni Brazil. Oun lo si maa n saba wa lẹyin ọpọ ipolongo to n beere ẹtọ wọn.
Ibi kan ti wọn n pe ni Belém do Pará, lo ti bẹrẹ ipolongo rẹ, ko too darapọ mọ awọn kan lati da Brazilian Network of Prostitues silẹ laaarin 1980. Eyi to jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ aṣẹwo ti wọn da silẹ ni Latin America.
Barreto, ẹni to ti pe ọgọrin ọdun (80) bayii, ti n tako iwa ojuṣaaju fun ọpọlọpọ ọdun.
O wa lara awọn to ṣiṣẹ fun eto ti yoo dena arun HIV, o si polongo lati dena itankalẹ rẹ lawọn ibi iwakusa. Ni 2023, o kọ iwe itan igbesi aye rẹ jade.
Ki itan wa jẹ eyi ti yoo la ipa, ko ma jẹ eyi ti wọn yoo pa ohun mọ agogo wa lẹnu. Awa obinrin agbaye, pẹlu afojusun nla ti a ni, lati yege, lati ronu, lati yi awujọ pada.
Lourdes Barreto
Eni to n gbe àṣà ga
Gẹgẹ bii ẹni ti wọn jọ da ajọ to n ri si iṣọkan aṣa silẹ lẹsẹ kuku,eyi ti wọn da silẹ lasiko ti iṣoro ajakalẹ arun, Danielle Cantor ti pese ounjẹ ati iranwọ fun opọlọpọ idile ni Tel Aviv
Oun ati Alma Beck ti wọn jọ da ajọ naa silẹ ri i daju pe ibẹ di ibi ti awọn eeyan ti n pade, ti wọn n jiroro ti wọn si n kọ nipa aṣa wọn.
Laipẹ yii lo kọwe iwe aṣa kan, eyi to sọrọ lowelowe nipa ohun to n ṣẹlẹ ni Israel ati Palestine.
Pẹlu iranlọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ Women Peace Sit-In, Cantor n kopa ninu awọn iwọde to n kede pe ki wọn dawọ ogun duro ni Middle East, ki wọn si tọwọ bọ iwe adehun alaafia ti yoo maa lọ bẹẹ.
Bi awon obinrin ba jọ n wo saakun ọrọ bakan naa, a le da ilana ti ko tẹle idajọ ododo mọ, a si le tun ero wa pa lati da ori kọ ibi to yẹ.
Danielle Cantor
Ajafẹtọọ oṣelu to ti ṣẹwọn ri
Ọkan ninu awon eeyan mẹrindinlọgbọn (26) ti wọn tu silẹ lọgba ẹwọn losu Kẹjọ, gẹgẹ bii paṣi-paarọ to waye ni Lilia Chanysheva, ọmọ Russia ni. Bo ṣe gba ominira naa lo fi Russia silẹ.
Lilia Chanysheva lo jẹ olori lọfiisi omọ ẹgbẹ oṣelu alatako, Alexei Navalny, ni Russia tẹlẹ. Iṣẹ rẹ ni lati maa tọpinpin awọn alajẹbanu, ko si maa beere fun idibo alaafia ati ẹtọ lati le sọ tẹnu ẹni.
Ṣaaju ko too maa ṣiṣẹ fun Navalny lo ti nilaari, ọrọ to ni i ṣe pẹlu owo ori ni Lilia fi n ri owo tiẹ nigba to n ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ nla nla ni Moscow
Ni 2021, wọn mu un fun ẹsun pe tiẹ pọju,wọn si ju u sẹwọn ọdun mẹsan-an aabọ. O lo ọdun meji ati oṣu mẹsan-an lẹwọn ko too gba ominira.
Aṣòfin
Ìgbà karùn-ún rèé tó ń ṣojú ìpínlẹ̀ Maine nílé aṣòfin. Susan Collins ni obìnrin ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Republican tó ti pẹ́ jù ní ilé aṣòfin Amẹ́ríkà.
Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló ti ṣe lórí àbá tó làmì laaka. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣòfin mẹ́fà tí wọ́n gbé òfin nípa ètò ìlera obìnrin tí kò ṣe nǹkan oṣù mọ́ ìyẹn Advancing Menopause and Mid-Life Women's Health Act èyí tí wọ́n máa ná $275m lé lórí láti ṣe ìwádìí lórí àìṣe nǹkan oṣù mọ́, ìtọ́jú àti ìpolongo fún ọdún márùn-ún.
Collins ló tún wà nídìí àbá National Alzheimer's Act, ètò tó wà fún dídénà àti ìtọ́jú àìsàn Alzheimer. Ó ti ṣiṣẹ́ láti ri pé ìpèsè owó ti wà fún àkànṣe iṣẹ́ náà di ọdún 2035. Bákan náà ni àbá ọ̀hún ṣe àmójútó àwọn èèyàn tí wọn kìí rí ọwọ́ ìjọba tó.
Olupolongo ẹtọ awọn obinrin
Akọroyin ni Zhina Modares Gorji, o lọwọ si idasilẹ ẹgbẹ Zhivano Women's Association ni 2019, eyi to n lo ẹkọ iwe, iwọde lati tako ohun to ba lodi sawọn obinrin, bẹẹ naa si ni wọn n kọju ija sawọn to ba n gbogun ti obinrin.
Ẹẹmeji ni wọn ti mu un latigba to ti bẹrẹ ẹgbẹ Obinrin Iran, igbesi aye wọn ati ijangbara. Ẹwọn ọdun mọkanlelogun (21) ni won kọkọ sọ Modares si, lori ẹsun pipa irọ mọ ijọba. Ẹwọn ọdun meji ati oṣu mẹrin ti wọn ba a din ẹwọn naa ku si lo n ṣe lọwọ bayii.
Modares Gorji jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ One Million Signatures to n ko awon eeyan jọ lati tun ofin Iran ṣe, wọn koju ofin to n tako awọn obinrin.
Oun naa lo wa lẹyin ẹgbẹ ayaworan kan ni Kurdish, ati eto awọn obinn kan to tun maa n sọ nipa awọn ọmọde Kurdish.
Olóṣèlú
Huang Jie gbajúmọ̀ fún jíjàfún ẹ̀tọ́ gbogbo ẹ̀yà. Oṣù Kìíní ọdún yìí ló fìtàn balẹ̀ nígbà tó wọlé ìbò sí ilé aṣòfin, tó sì di ẹni àkọ́kọ́ tí yóò jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ LGBTQ+ (Àwọn tó máa ń ní ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo) tó fojú hàn tó jẹ́ aṣòfin.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyípadà ló ti pè fún láti ìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ òṣèlú tó fi mọ́ jíjà fún ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin tí kò ì tíì lọ́kọ,àwọn abosábo tí wọ́n ti ṣègbéyàwò láti le jẹ àǹfàní ìtọ́jú láti rí ọmọ bí àti láti jẹ́ kí ìjọba máa ṣe ìrànwọ́ lórí ohun èlò nǹkan oṣù fáwọn obìnrin tí owó tó ń wọlé fún wọn kò tó nǹkan àti àwọn obìnrin tó jẹ́ àkàndá.
Lẹ́yìn tó jáde láti sọ irú èèyàn tó jẹ́ lọ́dún 2023, ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpèníjà tó ti kojú. Ó ń pè fún ṣíṣe ìfimúlẹ̀ òfin tó máa dènà ìwà ipá ìbálòpọ̀ pàápàá lórí ayélujára.
Gbígba bí àwọn èèyàn ṣe rí ní gbogbo ẹ̀yà ni níní ìfarajìn tòótọ́. Bí ohùn bá ṣe ń pọ̀ si ni a ṣe lè lágbára si pàápàá àwọn tí wọ́n gbà pé wọn kò lágbára, àwọn obìnrin àti LGBTQ+.
Huang Jie
Olukede nipa irinajo
Guerline M. Jozef n ṣiṣẹ lẹka to n ri si oṣelu ati iran eeyan ni US, o si jẹ ajafẹtọọ awọn arinrin ajo.
Oun ni oludasilẹ ẹgbẹ Haitian Bridge Alliance ti awọn obinrin n lewaju rẹ, eyi to da le ori awọn eeyan ilẹ Africa.
Labẹ idari rẹ, egbẹ naa fi ẹsun iwa ọdaran kan Donald Trump lọdun yii, lori ohun to sọ nipa ẹgbẹ naa pe wọn maa n jẹ awọn nnkan ọsin, ninu ọrọ kan ti Trump sọ lasiko ipolongo ibo aerẹ rẹ ni Ohio.
Fun ọdun pipẹ ni Jozef ti maa n tako bi wọn ṣe n da awọn omọ ilu rẹ pada sile. Ajọ rẹ ṣi rọ Biden laipẹ yii pe ki wọn yee da awọn to wa aabo lọ si America pada sile.
Amofin
Ẹni kan ti ofin ati idajọ ododo jẹ logun ni Ruth López. Agba amofin ni, ni ileeṣẹ kan to n jẹ Cristosal. ileeṣẹ to n ri si idagbasoke ijọba awarawa kaakiri Aarin-gbungbun America. (Central America).
Oun to jẹ ẹ logun ni gbigbe ogun ti iwa ajẹbanu, riri si ofin idibo ati dida aabo bo ẹtọ araalu ni El Salvador.
Alẹnulọrọ ti ki i dakẹ si aburu ijọba ni, o ti kede kari ayelujara , pe ki akoyawọ ati otitọ maa han ninu iṣejọba, ki oju araalu si maa to gbogbo rẹ bo ṣe n lọ.
Iṣẹ arabinrin yii ti di ohun to farahan kiri, nibẹrẹ ọdun yii , El Savador tun yan Aarẹ Nayib Bukele fun saa keji. Bukele toun naa ri i pe oun ti di gbajumọ nipasẹ iwa ọdaran to dinku, ti ṣapejuwe ara rẹ bii apaṣẹẹ-waa to rọrun ju lagbaaye.
Olóṣèlú
Lẹ́ni ọdún méjìlélógún, Hana-Rawhiti Maipi-Clarke di obìnrin Māori tó kéré jùlọ tí wọ́n dìbò yàn sílé aṣòfin ní New Zealand.
Lásìkò tó ń sọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, ó jó ijó haka, ijó ayẹyẹ àwọn Māori, tó sì ń pè fún àlékún kí kópa àwọn ọmọ ìlú. Láìpẹ́ yìí ló ṣáájú àwọn haka mìíràn lọ sí ilé aṣòfin láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí àbá kan tó ń fa awuyewuye.
Maipi-Clarke máa ń jà fún ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn Māori, gbígbé àṣà lárugẹ àti ọ̀rọ̀ àyíká. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ló wà nígbà tó kọ́kọ́ gbé ìwé jáde nípa kajọ́ kaṣù Maori
Ní ọdún yìí ló gba àmì ẹ̀yẹ One Young World Politician of the Year fún akitiyan rẹ̀ nípa pípe àwọn ọ̀dọ́ sínú òṣèlú.
Àwọn obìnrin nílò láti fi agbára já ilẹ̀kùn àwọn ibi tí wọn kò ti pè wọ́n dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú káàkiri àgbáyé yálà ní ẹkùn wọn, ìjọba ìbílẹ̀, ìjọba àpapọ̀ tàbí àgbáyé.
Hana-Rawhiti Maipi-Clarke
Agbẹjọrọ, ajafẹtọọ ọmọniyan
Ọpọlọpọ awọn alaisan to wa nileewosan José Manuel de Los Rios, ni Caracas, lorilẹede Venezuela ni wọn jẹ ọmọde to wa lati idile talaka ati tawọn to jẹ obi kan ṣoṣo lo n tọ wọn
Prepara Familia, ajọ kan ti ki i ṣe tijọba, ti Katherine Martinez da silẹ n pese aṣo ti wọn nilo fun wọn, pẹlu oogun ati ounjẹ, bẹẹ ni wọn si n gba wọn nimọran pẹlu.
Gẹgẹ bii lọọya to n ja fun ẹtọ awọn eeyan, Martinez maa n ṣe akọsilẹ awọn ohun to ba tẹ ẹtọ ọmọde ati awọn obinrin loju mọlẹ, nigbakigba ti oun ati awọn ikọ rẹ ba ri iru nnkan bẹẹ, paapaa ni awọn ileewosan ti awọn obinrin naa ba ti n ṣiṣẹ bii olutọju.
Nitori iṣoro ai ri ounjẹ jẹ to n ṣẹlẹ ni Venezuela, Prepara Familia tun ṣi ibudo kan ti wọn ti n fun awọn oloyun ati awọn ọmọde ni oogun ti wọn ba nilo lọfẹẹ.
Ajàfẹ́tọ̀ọ́ Irish Traveller Movement
Ọmọ ogún ọdún péré ni Latisha McCrudden àmọ́ tó ti ṣàfihàn ara rẹ̀ agbenusọ tó gbónu fún àwọn èèyàn Irish Traveller.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ fúnra rẹ̀, ó ń gbógun tako àwọn èèwọ̀ tó de àwọn ẹ̀yà kéréje ní orílẹ̀ èdè Ireland, tó sì ń lo ìrírí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó móríbọ́ lọ́wọ́ ìfìyàjẹni láti fi máa gbógun tako ìwà ìfìyàjẹni fún àwọn obìnrin.
Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Galway, McCrudden jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Irish Traveller Movement National Youth Forum, ẹgbẹ́ àwọn obìnrin ìyẹn National Women's Council of Ireland àti ọmọ ẹgbẹ́ tó ń ṣe àtìlẹyìn fún Traveller, Mincéirs Whiden.
Ó ní èrò láti díje níbi ètò ìdìbò tó máa wáyé lọ́dún 2029 àti láti ní ipa lórí ọjọ́ iwájú Ireland.
Olùpolongo fáwọn tí wọ́n ti fìyà jẹ nípa ìbálòpọ̀, Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn àti tó gba àmì ẹ̀yẹ Nobel Peace, Nadia Murad fi ara da ìwà ìpànìyàn Yazidi Iraq táwọn Islamic State (IS) lọ́dún 2014.
Àwọn alájàngbilà IS fi tipátipá sọ sí oko ẹrú, ba lòpọ̀, tí wọ́n sì fìyà jẹ ẹ́. Murad móríbọ́ lọ́wọ́ wọn lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, tó sì fi ọkàn akin ṣàlàyé gbogbo ìrírí rẹ̀ fáyé àti láti pé àkíyèsí àwọn èèyàn sí ìfìyàjẹni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀.
Ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbejọ́rò Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn Amal Clooney, tó sì ṣe ìfilọ́lẹ̀ àjọ Nadia Initiative láti fi ran àwọn ìlú lọ́wọ́ àti ìtọ́jú àwọn ènìyàn tó kojú ìṣòro irú tirẹ̀.
Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn ìpànìyàn Yazidi, Murad ń tẹ̀síwájú láti máa ṣe kóríyá fáwọn èèyàn lágbàáyé.
A gbọ́dọ̀ pọ́n ohun tí mo pè ní "idà ẹ̀mí" láti jà fún ìṣòdodo àti déédéé, òótọ́ àti ìrètí.
Nadia Murad
Awakusa
Gẹgẹ bi obinrin to n ṣẹ okoowo iwakusa, Annie Sinanduku Mwange, n dari ẹgbẹ kan to n gbogun ti fifi iṣekuṣe lọ awọn obinrin lẹnu iṣẹ naa, nibi ti idaji awon eeyan to n ṣiṣẹ nibudo iwakusa naa ti jẹ obinrin.
Aṣiwaju awon obinrin lẹka iwakusa Renafem, niṣe lo maa n pe ara rẹ ni ọga lasan, abi iya ọga. Bẹẹ lo n fi awọn obinrin sibi iṣakoso iwakusa, gẹgẹ bi ọna kan ti yoo dẹkun awọn ọkunrin ibẹ lati fi iṣekuṣe lọ wọn.
Nipa nina owo si ọna ti awọn obinrin le maa gba rọwọ mu lọ sẹnu, o tun ni ireti lati din ọna ti won n gba lo ọmọde ni ilokulo ku, bi gbogbo aye ṣe n nilo eroja cobalt si i ti wọn si n beere rẹ, ati awọn nnkan alumọni miran to tun wulo lati tun ọkọ to ba n lo ina ṣe.
Olùpolongo fún ìṣedọ́gba láàárín gbogbo ẹ̀yà
Ìwà ìbálòpọ̀ láàárín akọsákọ tàbí abosábo jẹ́ èyí tó lòdì sí òfin ní Uganda tí ìjìyà rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n. Àmọ́ Kasha Nabagesera tó ń jà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn LGBTQ+ ń pè fún àyípadà òfin yìí.
Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tó ń máa ń ní ìbálòpọ̀ abosábo fúnra rẹ̀, ó ti ní ipa káàkiri ilẹ̀ Áfíríkà lórí ìpolongo rẹ̀ pé kí wọ́n yé fojú tí kò dára wo ìwà náà.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Nabagesera ti gbé àwọn iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn àti ìjọba Uganda lọ sí ilé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ LGBTQ+. Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti pe òfin tó de ìbálòpọ̀ akọsákọ àti abosábo lọ sílé ẹjọ́ ní Uganda, tó sì ń ṣe ẹjọ́ lórí òfin ọdún 2023 lọ́wọ́.
Ilé ẹ̀kọ́ Nkumba University ní Uganda ló ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ okoòwò, tó sì tún lọ sí Stanford University. Ó ti kópa nínú àkànṣe ètò tó ní ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà ní àpérò àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, European Parliament àti àjọ ilẹ̀ Áfíríkà, African Commission.
Olukede nipa ifipanilopọ
Obinrin ti wọn fipa ba lo pọ ti ko si fi bo, ti ko sọ pe ki wọn ma darukọ oun faye ni Gisele Pelicot, eyi si ti sọ ọ di apẹẹrẹ igboya ati iduroṣinṣin fun awọn mi-in ti ifipanilopọ ti ṣẹlẹ si.
Ọkọ rẹ to n fẹ tẹlẹ, jẹwọ pe oun maa n fun un ni oogun oorun, oun yoo si fipa ba a lo pọ nigba tawọn ṣi n fẹ ara awọn, o ni oun tun maa n pe ọpọ ọkunrin mi-in wa pe ki wọn waa ba iyawo oun laṣepọ. Ọpọlọpọ ibalopọ ipa yii ni a gbọ pe wọn ya fidio rẹ bi wọn ṣe n ṣe e.
Labẹ ofin, Pelicot lẹtọọ lati ma darukọ ara rẹ to ba fẹẹ sọ nipa iṣẹlẹ yii, ṣugbọn o loun ko fẹ bẹẹ. O ni ki wọn ṣe igbẹjọ naa ni gbangba aye, ki wọn fi fidio naa han, ki abuku ti wọn fẹẹ fi kan oun le pada sọdọ awọn to ṣiṣẹ naa. Bii aadọta ninu awọn ọkunrin to fipa ba a lo pọ ni wọn ti jẹwọ pe awọn ṣe bẹẹ loootọ, ṣugbọn ọpọ wọn lo ni awọn ni ibalopọ lasan ni.
Nigba ti igbẹjọ naa de opin, ọpọ obinrin ni Pelicot ti jẹ iwuri fun kaakiri agbaye. Pelicot ti awọn ọmọ rẹ naa ti bimọ, sọ pe ireti oun ni pe ki ọrọ oun yi ofin ilẹ Faranse pada lori ifipanilopọ ati gbigba fun ọkunrin lai lo ipa.
Igbákejì Olóòtú ìjọba
Angela Rayner, tó ń di ọ̀kan lára àwọn ipò òṣèlú tó tóbi ní UK mú, di igbákejì Olóòtú ìjọba lẹ́yìn ètò ìdìbò gbogbogbò tó wáyé ní oṣù Keje.
Rayner, tí wọ́n bí tó sì dàgbà ní ìlú Stockport bẹ̀rẹ̀ sí ní tọ́jú ìyá a rẹ̀ láti ìgbà tó wà ní kékeré. Ó lóyún nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún èyí tó mu kúrò nílé ẹ̀kọ́. Ó ṣiṣẹ́ àwọn tó máa ń fún èèyàn ní ìtọ́jú ní ìjọba ìbílẹ̀ kó tó di ipò aṣojú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ mú.
Ní ọdún 2015 ni wọ́n kọ́kọ́ yàn án sí ilé aṣòfin nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour fún ẹkùn Ashton-under-Lyne. Òun ni obìnrin àkọ́kọ́ tó kọ́kọ́ ṣojú ẹkùn náà, kó tó ṣe Mínísítà fọ́rọ̀ àwọn àti ṣíṣe déédéé, àtàwọn ipò míì.
Òun ni akọ̀wé ìjọba fọ́rọ̀ ibùgbé, agbègbè àti ìjọba ìbílẹ̀.
Ajafẹtọọ awujọ
Aja fun ẹtọ awọn mẹkunnu ni India ni Aruna Roy, o fi iṣẹ ijoba to n ṣe silẹ lati le fi ara sin awọn eeyan to n gbe ni igberiko.
O tun jẹ ọkan lara awọn to da ajọ Mazdoor Kisan Shakti Sangathan (MKSS) sile, eyi to da lori akoyawọ ati sisan owo oṣu to peye fun awọn oṣiṣẹ. O si tun wa lara awọn to kopa ninu dida ofin to faaye gba oṣiṣẹ lati beere bijọba ṣe n ṣe si silẹ.
O ti ju ogoji ọdun lọ bayii ti Roy ti n lewaju ninu igbaye-gbadun awon eeyan, o si ti gba ami ẹyẹ ọlọkan-o-jọkan, titi kan eyi ti wọn n pe ni 'Nobel Prize of Asia'
Oun ni aarẹ ẹgbẹ awọn obinrin apapọ ni India, o si ti kọwe kan lọdun yii to pe ni 'The Personal Is Political
Bi ẹwà ba ru bo wa loju, o ṣee ṣe ka ma da anfaani to n wọle bọ mọ
Aruna Roy
Olupẹjọ lori ile ọmọ rẹ ti wọn yọ danu
Wọn bi Yumi Suzuki pẹlu aisan kan ti a mọ si Cerebral palsy, eyi to n sọ ọmọ di akanda ẹda. Lati kekere lo ti n koju idẹyẹsi. Nigba to pe ọmọ ọdun mejila, wọn fi ipa yọ ile ọmọ rẹ kuro.
Lati ọdun 1950 titi di ọwọ 1990 sisalẹ, awọn eeyan kan ti wọn jẹ akanda ẹda, koju iṣoro ifipa yọ ile ọmọ won kuro yii ni Japan, nitori ofin kan ti wọn ṣẹṣẹ yipada ni 1996.
Suzuki ati awọn olupẹjọ mejidinlogoji mi-in pe ijọba lẹjọ, lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n paara kootu, o jare ẹjọ naa.Loṣu Keje, ile ẹjọ to ga julọ ni Japan, paṣẹ pe ofin to n yọ ile ọmọ eeyan lai jẹ pe ẹni naa fẹ bẹẹ, lodi patapata, o si paṣẹ pe ki ijọba san owo itanran fun awọn ti wọn ti fipa sọ di alaile bimọ mọ naa.
Awọn alaṣẹ fidi ẹ mulẹ, pe 16, 500 eeyan ni wọn ti fipa sọ di alai le bimọ mọ, lai jẹ pe o tẹ awọn eeyan naa lọrun.
Olukọ ati olukede nipa oju ọjọ
Gẹgẹ bii ọkan lara awon aarẹ ẹgbẹ KlimaSeniorinnen (Senior Women for Climate Protection), ọdun mẹsan-an ni Rosmarie Wydler-Walti fi ba ijọba ja, to fi bori ẹjọ akọkọ iru re to tako ijọba, eyi to waye nile ẹjọ European Court of Human Rights, ile ẹjọ ilẹ Yuroopu to n ja fun ẹtọ ọmọniyan.
Pẹlu awọn obinrin mi-in ti wọn to ẹgbẹrun meji niye, Wydler -Walti to jẹ olukọ awọn ọmọde ati olugbani-nimọran, tako ijọba Swiss lori ooru to n fọn jade niluu, ti won ni bo ṣe n mu kari aye niyẹn. Wọn ni eyi lewu fun ilera awọn, ati pe ọjọ ori awọn, pẹlu bawọn ṣe jẹ obinrin, n mu ki ewu wa lori awọn
Loṣu Kẹrin, ile ẹjọ dajọ pe orilẹede naa ko ṣe to nipa bi adinku yoo ṣe de ba eefin.
Bo tilẹ jẹ pe igbimọ Swiss pada kọ idajọ naa, sibẹ, o fi ilana ti wọn yoo maa tọ lori igbẹjọ oju ọjọ lelẹ.
Ajafẹtọọ awọn obinrin
Feng Yuan jẹ ajafẹtọọ awọn obinrin ni China, oun lo da ileeṣẹ Equality Beijing to n ri si ọrọ awọn obinrin silẹ ni 2014. Ọdun to ti pẹ sẹyin ni Feng Yuan ti n ja fun ẹtọ awọn obinrin, oun ti ileeṣẹ to da silẹ si wa fun ni riri si atunṣe ofin, ironilagbara ati kikoju iṣoro to ba doju kọ awọn obinrin .
Lọdun diẹ sẹyin lo ti bẹrẹ si i ṣe atilẹyin fun awọn obinrin China lori agbekalẹ kan ti wọn pe ni 'MeToo survivors', bẹẹ lo si tun n kọ awọn oṣiṣẹ rẹ lẹkọọ nipa ọna ti wọn le fi da aabo bo ara wọn bi ẹnikẹni ba fẹẹ ba wọn ṣe aṣemaṣe lẹnu iṣẹ.
Feng tun ṣiṣẹ gẹgẹ bi akọroyin to n ri si ọrọ to ba kan awọn obinrin nikan, iyẹn lati ọdun 1986 de 2006.
Lati ọdun 1990 si isalẹ ni Feng ti n ṣe iranlọwọ nipa dida awọn ajọ ti ki i ṣe tijọba silẹ, eyi to da le ọrọ awọn obinrin ati bi yoo ṣe maa de etigbọọ awọn eeyan nipa iroyin. Awọn nnkan bii ẹkọ nipa arun ko gboogun,HIV/Aids, didari ati riro awọn ọdọ lagbara ko gbẹyin ninu eto Feng Yuan. O ti kọ ọpọlọpọ iwe ni China, bẹẹ lo kọwe kọja orilẹede naa rẹpẹtẹ.
Afọnrere lori awọn to wa nigbekun
Ẹni to n fọn rere pe ki wọn tu awọn to wa nigbekun silẹ ni Einav Zangauker. Obinrin yii ko lọkọ, ṣugbọn o ni ọmọ ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan ti oruko rẹ n jẹ Matan. Ọmọ naa ni wọn mu si igbekun ogun Hamas lọjọ keje, oṣu Kẹwaa ọdun 2023. Ẹnikeji Matan lo n jẹ Ilana, wọn ji oun naa gbe, wọn si pada fi i silẹ nigba ti wọn ṣe paṣi-paarọ awọn ẹlẹwọn kan.
Latigba naa ni Einav ti n kede nipa awọn ti wọn fi sigbekun yii. O n pe awọn olori lati dide si ọrọ yii, bẹẹ lo n ni kawọn araalu ṣe iwọde ọlọsọọsẹ ti yoo jẹ ki wọn ja a kunra.
Zangauker ti di alatako gbangba fun ijọba Israel, nipa bi wọn ko ṣe ri awọn to wa lahamọ gba jade ki wọn pada sile. Bo tilẹ jẹ pe oun naa wa lara awọn to dibo yan Olootu ijọba wọn, Benjamin Netanyahu to n ṣejọba.
O n fọn rere pe ki wọn fi awọn eeyan to ṣẹku nigbekun silẹ.
Ajafẹtọọ lori ọmọ bibi
Ninu oṣu kẹjọ ọdun 2022, Amanda Zurawski bẹrẹ si i ri omira lasiko ti oyun inu rẹ ko ti i too bi. Awọn dokita sọ fun un pe ọmọ naa ko ni i yè.
Texas ni Zurawski n gbe, wọn ko si gba ko ṣẹyun naa. Lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ ti tako o loṣu meji ṣaaju, ilu naa ti fofin de oyun ṣiṣẹ, afi to ba jẹ pe ẹmi iya to loyun naa wa ninu ewu nikan. Lẹyin ọjọ kẹta, aarẹ to le gba ẹmi lẹnu obinrin yii kọ lu u, wọn si pada fun un laaye lati yọ oyun inu rẹ naa danu.
Loṣu Kẹta ọdun 2023, Zurawski ati awon obinrin mọkandinlogun miran ti iru nnkan bayii ti ṣẹlẹ si ri, pe ẹjọ tako ijoba. Eyi ni ẹjọ akọkọ ti awọn obinrin ti wọn ko jẹ ki won ṣẹyun pe latigba ti ofin Roe v Wade ti yipada. Nigba ti ile ẹjọ to ga julọ kọ ofin to n dena oyun ṣiṣẹ.
Zurawski ti waa pinnu lati maa ja ija yii lọ, o loun yoo ri i pe wọn fun obinrin lẹtọọ to yẹ wọn nipa ọmọ bibi.
Ajafẹtọọ awọn obinrin
Nipa lilo ẹka ayelujara lati sọ tẹnu rẹ kaye gbọ, Fawzia al-Otaibi ti sọ ọ tipẹ, pe ki opin de ba bi awọn ọkunrin ṣe maa n jẹ alagbatọ obinrin ni Saudi Arabia.
Ṣugbọn lẹyin ti awọn alaṣẹ ilu naa pe e lati waa ṣalaye ohun to ri to fi sọ ohun to sọ, Fawzia pinnu lati sa kuro lorilẹ-ede naa.
Ikeji rẹ toun naa jẹ obinrin, Manahel-al-Otaibi toun naa maa n ja fun ẹtọ awọn obinrin ni wọn mu ti wọn si ju si ẹwọn ọdun mọkanla nibẹrẹ ọdun yii, lẹyin ti wọn lo jẹbi awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu iru aṣọ to maa n wọ, ati awọn ohun to maa n sọ lori ayelujara, gẹgẹ bi awọn ajafẹtọọ ọmọniyan ṣe wi.
Al-Otaibi ti kede lai sinmi pe ki wọn fi ikeji oun silẹ lẹwọn. Iwadii kan fi han pe opọ eeyan ni wọn ti ju sẹwọn ni Saudi Arabia, nitori ohun ti wọn kọ si oju opo ayelujara wọn.
Dokita to n tọju awon ọmọde
Bi wọn ṣe n ju ado oloro to ni Gaza, ti ko si si nnkan eelo ti wọn nilo nitosi, eyi ko di Shireen Abed lọwọ lati mAa tọju awon ọmọ ikoko ti wọn n bi ni Gaza.
Lẹyin ti ogun naa bẹrẹ loun naa di alai nile lori mọ ni 2023, ṣugbon dokita to n tọju awon ọmọde naa tẹsiwaju lati maa tọju awọn ọmọ ikoko ti wọn n bi nibudo ogunlende kaakiri.
Pẹlu iriri to ti ni lẹka itọju ọmọde, paapaa gẹgẹ bii adari ẹka ibimọ nileesosan Al-Shifa, o da ẹka itọju pajawiri silẹ lati doloa ẹmi bi ko ṣe si nnkan eelo to. Bẹẹ lo si n kọ awọn dokita mi-in niṣẹ pẹlu.
Ohun to ṣẹlẹ to kọja agbara rẹ lo mu ko kuro ni Gaza pẹlu awọn ọmọ rẹ obinrin meji nibẹrẹ ọdun yii, ṣugbọn Abed ṣi n tẹsiwaju lati ran awọn dokita lọwọ labẹlẹ.
Shilshila Acharya lo ni ọkan lara awọn ileeṣẹ to tobi ju ti wọn ti n sọ idọti di owo ni Nepal. Ileeṣẹ afidọti-ṣowo to da silẹ naa lo pe ni Avni Ventures, o maa n gba awọn oṣiṣẹ ti wọn wa lati agbegbe ti ẹnikan ko ka kun, o si da oju kọ gbigba awọn obinrin si i lati eka to n ṣiṣẹ lai lo kẹmika kankan.
Acharya ko ipa pataki ninu ipolongo kan ti wọn pe ni 'No Thanks, I Can Carry My Own Bag, ti wọn se ni 2014. Eyi to tumọ si pe, ' o ṣe, mo le gbe apo mi funra a mi' . Eto naa lo fi opin si lilo ọra gẹgẹ bii baagi.
Olukọni nipa bi a ṣe n sọ idọti dowo yii lo tun wa nidii eto kan ti wọn fi maa n tun agbegbe Himalayas ṣe. Wọn maa n ko awọn idọti ti awọn to waa wo oke naa ba ṣe sibẹ kuro, wọn si maa n ri to toonu 119, eyi ti wọn ti bẹrẹ lati ọdun 2019.
Nipasẹ iṣẹ rẹ, awọn nnkan ti wọn ko lo mọ yii tun n ṣee lo fun awọn oniṣẹ ọwọ lati fi ṣe apẹrẹ, ẹni ati ẹṣọ ara, wọn si n gba ibẹ rowo gbọ bukaata ara wọn.
Onimọ nipa ọgbin
Nigba ti ọwọn omi bẹrẹ ni Gaza latari ogun to n waye, Enas Al-Ghoul ro pe oun ti ri ọna abayọ kan.
Onimọ nipa ọgbin naa lo awọn nnkan bii igi, igo ati awọ lati pese omi. Ilana oorun ti a mọ si solar lo lo to fi sọ omi okun di ohun to ṣee mu.
Ilana omi rẹ yii lo di ohun to n gba ọpọ eeyan la bayii ni Khan Younis ti i ṣe Guusu Gaza, nigba ti wọn ti di ọna omi ati imọtoto lati oṣu Kẹwaa ọdun 2023.
Al-Ghoul pinnu lati lo ọgbọn ori rẹ yii lati ran awọn eeyan Palestine ti wọn ko rile gbe mọ lọwọ, o si tun pese ilana solar kan fun wọn lati maa fi dana ounjẹ. Bẹẹ lo tun lo awọn nnkan ti wọn ko lo mọ, to fi won ṣe timutimu ti wọn le maa fi sun, ati baagi to ṣee gbe .
Onímọ̀ nípa ẹ̀yà ara ìbímọ obìnrin
Nígbà tí ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ìwòsàn rẹ̀ ní Sudan lọ́dún tó kọjá, Dókítà Safa Ali kọ̀ láti tẹ̀lé àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé wọn kò rí bi jáde.
Safa Ali, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀yà ara obìnrin, ó ṣe ìrànlọ́wọ́ láti kó àwọn obìnrin àtàwọn olóyún lọ sí ibi tí ààbò wà látàrí làásìgbò tó ń wáyé láàárín àwọn ọmọ ogun àti ikọ̀ Rapid Support Forces.
Ní ilé ìwòsàn Al-Saudi Maternity Hospital ló ti ń ṣe iṣẹ́ abẹ fáwọn èèyàn báyìí, tó sì ń ṣe ìtọ́jú fáwọn obìnrin tí ogun tó ń lọ lọ́wọ́ ń fá fún wọn.
Bákan náà ló ń tẹ̀síwájú láti máa kọ́ àwọn dókítà ogún tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ jáde nípa ẹ̀yà ara obìnrin láti kojú ìṣòro àìsí òṣìṣẹ́ ìlera tó.
Mo gbàgbọ́ pé pẹ̀lú àwọn obìnrin, ìlérí ìwòsàn wà, ìdájọ́ òdodo àti ọjọ́ iwájú tí a kò ní máa gbé nínú ìbẹ̀rù. Wọ́n máa ń mú mi rántí pé ìrètí ṣì wà, kódà lásìkò tí gbogbo nǹkan bá dàbí pé nǹkan kò fararọ.
Safa Ali
Nọ́ọ̀sì àti olùdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́
Ní ìlú kéréje ní ẹkùn àríwá Bangladesh tí Rikta Akter Banu tó jẹ́ nọ́ọ̀sì ń gbé, ègún ni wọ́n máa ń rí àwọn ọmọ tó bá jẹ́ àkàndá sí.
Nígbà tí kò rí ilé ẹ̀kọ́ kankan gba ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ àkàndá látàrí ìpèníjà ọpọlọ tó ní fún ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ó ta ilẹ̀ tó ní, tó sì fi owó rẹ̀ kọ́ ilé ẹ̀kọ́.
Ilé ẹ̀kọ́ Rikta Akter Banu Learning Disability School ti ń gbà tó ọ̀ọ́dúnrún akẹ́kọ̀ọ́ báyìí, tó sì ti mú àyípadà bá ojú táwọn ará ìlú náà fi máa ń wo àwọn tó jẹ́ àkàndá.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ tó jẹ́ àkàndá, tó ní ìpèníjà láti ni wọ́n ṣe dá ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn tó ní ìpèníjà ara ní ilé ẹ̀kọ́ náà báyìí.
Ẹni to ṣe agbekalẹ nnkan eelo sayẹnsi ti eeyan le ṣe funra rẹ DIY
Sara Berkai jẹ ọmọ orilẹede Eritrea, wọn bi i si Sudan, wọn si wo o dagba ni London. Oun ni akọkọ ọmọ to lọ si yunifasiti ninu ebi rẹ.
Oun lo da ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Ambessa Play silẹ, nibi ti wọn ti n pese awọn nnkan eelo ikawe fun awọn ọmọde, ti wọn si n kọ wọn bi wọn ṣe le fi nnkan iṣere da ara oriṣiiriṣii.
Iṣẹ Berkai n kọ awọn ọmọ ti ko lọ sileewe ni ọna ti wọn le gba lati kẹkọọ lasiko ti won ba ro pe awọn n ṣere ọwọ ni. Nigba to n kọ awọn akẹkọọ nipa ilana STEM lo gbe ilana yii kalẹ, iyẹn fun awọn ọmọ ti ko rile gbe ni Ethiopia ati Eritrea ni 2019.
Irori rẹ yii ti di itẹwọgba fun ajọ Forbes, wọn ka a mọ awọn agbekalẹ ọgbọn (30) ti wọn n la ipa. Bẹẹ si ni o ti gba ọpọlọlọ oriyin pẹlu.
O daa keeyan duro ṣinṣin lori iṣẹ rẹ- ki eeyan fi gbogbo ara duro ti ohun to gbe dani, fun ọjọ ọla to daa ju ti asiko yii, ti a si fi ifẹ pilẹ ẹ rẹ.
Sara Berkai
Onimọẹrọ
Ede abinibi Gabriela Salas Cabrera ko si lori atẹ Google to ni gbogbo ede lori tẹlẹ, afi nigba ti obinrin yii kẹsẹ bọ ọ lati ri i pe ede naa ti i ṣe Náhuatl, wa lori atẹ naa.
Onimọẹrọ yii ṣiṣẹ pọ pẹlu akọṣẹmọṣẹ nipa ede, lati ri i pe ede rẹ pẹlu awọn ede ibilẹ mi-in wọ ori atẹ Google to n tumọ ede ni Mexico. Wọn ti gbe ede Náhuatl naa sori atẹ ọhun bayii lati ibẹrẹ ọdun yii.
Salas lo ilana ẹrọ AI lati gbe awọn ede ti ko si nibẹ tẹlẹ kalẹ, ko si tun fun awọn obinrin to n ṣiṣẹ ẹrọ lẹka ibilẹ ni idanimọ gidi.
Oun to dojukọ ni lilo nnkan eelo ati AI lati gbe eto to nitumọ kalẹ, bẹẹ lo si n kẹkọọ nile ẹkọ Univerisidad Politécnica to wa ni Madrid, lorilẹede Spain.
Iduroṣinṣin obinrin jẹ ina ti ki i ku, o n sọ inira di idi ọrọ, o si n tan imọlẹ fun ara yooku lati tẹle.
Gabriela Salas Cabrera
Agbẹ ati olukọni
Gẹgẹ bii atọnisọna loko, ohun ti Naomi Chanda duro fun ni lati kọ awọn eeyan rẹ lẹkọọ nipa ilana oko dida ti ko ni i pa ilẹ wọn lara.
O dojukọ ọna oko dida to ba oju ọjọ mu, bii eyi ti ki i lo omi pupọ, abi gbigbin awon nnkan oko ti ki i pẹ hù, bẹẹ lo si n ri i daju pe awọn obinrin n kopa ninu ilana ayipada oju ọjọ ọhun.
Pẹlu ajọ to n ri si ẹkọ awọn ọmọbinrin to da silẹ, Chanda ti kọ aadọjọ (150) awọn obinrin ni ilana ti wọn le fi maa da oko, ti wọn yoo si le koju ayipada yoowu ki oju ọjọ gbe wa ni Ariwa-Ila-Oorun Zambia, nibi ti asiko ọgbẹlẹ ti maa n pẹ gan-an, to si maa n ko ba awọn agbẹ oloko kereje.
Olukọni nipa ẹya ara obinrin
Akọnilẹkọọ nipa ẹya ara obinrin ni Nour Emam, o maa n da wọn lẹkọọ nipa imọtoto lasiko nnkan osu, ọmọ bibi ati ibalopọ, eyi si jẹ awọn ọrọ ti wọn ka si eewọ ni apa Middle East ati Ariwa Africa.
Emam jẹ ọkan lara awọn to da ileeṣẹ Motherbeing silẹ, nibi wọn ti n ṣiṣẹ iwosan pẹlu ajọṣepọ ileewosan imọ ẹrọ kan to wa ni Cair o. Erongba wọn ni lati mu ayipada rere ba ilera awọn obinrin nipasẹ imọ ẹrọ .
Afojusun rẹ ni lati ro awọn obinrin lagbara nipa ọna ti wọn yoo fi mọ bi ẹya ara wọn ṣe jẹ, ti wọn yoo si tun mọ nipa ọna ifeto-si-ọmọ-bibi, ti wọn yoo si tun le sọrọ nipa awọn nnkan wọnyi lai bẹru tabi tiju rara.
Ìmọ̀ ìyáìyá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn ṣe ìwúrí fún Rosa Vásquez Espinosa gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì láti pa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì papọ̀ mọ́ ìṣègùn ìbílẹ̀ láti fi dá ààbò bo àwọn ewé àti ẹranko ní ẹkùn Peru.
Gẹ́gẹ́ bí olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ tó ń ṣe ìwádìí Amazon Research International, ó ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìlú lábẹ́lé láti ṣàmúlò àwọn ewé àti ẹranko tí wọn kò ì tíì máa ṣàmúlò ní agbègbè náà.
Ìrìnàjò Espinosa sí àwọn ẹṣẹ̀ kùkú ní ẹkùn rẹ̀ jẹ́ kó ṣe àwárí àwọn kòkòrò àìfojúrí tuntun kan nínú odò Amazon Boiling River àti pé òun ló ṣáájú àyẹ̀wò nípa kòkòrò oyin tí kìí ta èèyàn àti oyin tó wà fún ìwòsàn ní Peru.
Bákan náà ló jẹ́ aṣojú ilẹ̀ òkèrè fáwọn èèyàn Ashaninka, ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ ọmọ onílùú ní Gúúsù Amẹ́ríkà.
Onimọ nipa oogun ati eni to gba ami ẹyẹ Nobel laureate
Ọmọ orilẹede Hungary to jẹ onimọ nipa oogun ni Katalin Karikò, oun lo ṣiṣẹ iwadii lorii kinni kan ti a mọ si RNA (mRNA), ti wọn lo lati ṣe abẹrẹ ajẹsara Korona. Awọn BioNTech/Pfizer ati Moderna ni wọn ṣe abẹrẹ ajẹsara naa.
O gba ẹbun (Nobel Prize) lori rẹ, eyi ti oun ati akẹgbẹ rẹ; Drew Weissman jọ pin fun ipa ti oun naa ko ninu iwadii ti ko ti i si iru rẹ ri naa, lasiko ti ẹmi ọpọ eeyan wa ninu ewu ailera.
mRNA, jẹ irinṣẹ kan ti wọn maa n lo lati tu DNA ara eeyan si eroja protein. Nnkan ẹlẹgẹ ni, o si ṣoro pupọ lati lo,ṣugbọn Kariko ni o da oun loju pe yoo ko ipa pataki lẹka oogun.
Wọn dan imọ ẹrọ naa wo ṣaaju ki Korona too bẹ silẹ, ṣugbọn wọn ti fun ọpọ miliọnu eeyan bayii lati fi da aabo bo ara wọn nitori arun Korona.
Ṣiṣẹ tọ afojusun rẹ nipa dida oju kọ ohun ti o le sẹ, dipo ohun ti awọn eeyan yooku le ṣe. Bi o ba ṣubu, kọ ẹkọ lati ara rẹ. Dide ki o si tẹsiwaju pẹlu ijafafa kan naa.
Katalin Karikó
Olutọju aisan jẹjẹrẹ nilana oyinbo
Nipa afojusun ilana itọju jẹjẹrẹ nipa lilo ṣọja ara ẹni, Georginia Long fẹẹ ki aye kan wa ti awọn eeyan ko ni i maa ku iku jẹjẹrẹ mọ
Gẹgẹ bii ọkan lara awọn adari ni Melanoma Institute Australia, Long di gbajugbaja ni 2024, lẹyin to lọwọ si ilana itọju kan to jẹ akọkọ iru rẹ lagbaaye, eyi to ran ọrẹ ati akẹgbẹ rẹ, Richard Scolyer, lọwọ, to fi bọ lọwọ aisan jẹjẹrẹ, lẹyin to ti kọkọ ni oriṣi jẹjẹrẹ kan to maa n ba ọpọlọ eeyan finra.
Long ati awọn ikọ rẹ-titi kan alaisan ti wọn n tọju, ri i daju pe jẹjẹrẹ ṣee tọju daadaa nipa lilo awọn ṣọja ara ẹni ti arun naa kọlu (immunotherapy), ju akojọpọ awọn oogun lọ, ṣaaju ki wọn too ṣiṣẹ abẹ lati yọ arun naa danu.
Iṣẹ iwadii wọn lorii melanoma ti gba ọpọlọpọ ọdun, wọn si n gba oriyin fun pe wọn ti gba ọpọ ẹmi awọn eeyan ti ayewo fi han pe wọn ni arun jẹjẹrẹ la.
O yẹ kawọn olori ọjọ ọla fi ijẹ-ọmọniyan ṣaaju, ki wọn maa ro awọn eeyan lagbara lati koju awọn ilana atijọ, ki wọn si wa ojutuu si iṣọro pẹlu ọgbọn atinuda.
Georgina Long
Bi gbogbo aye ṣe n tẹwọgba imọ ẹrọ AI to n ṣiṣẹ ni gbogbo ẹka, o ṣee ṣe nigba mi-in ki wọn fẹẹ foju pa afijọ ọhun rẹ.
Áṣiwaju onimọ nipa AI ni Sasha Luccioni, o ti ṣeranlọwo lati gbe irinṣẹ kan kalẹ, eyi to ṣee lo lati ṣe odiwọn eefin to ba n jade, ti wọn si ti lo ju igba 1.3 lọ.
Luccioni lo n lewaju agbekalẹ kan ti a mọ si Hugging Face, irinṣẹ agbaye to n ṣiṣẹ pọ pẹlu AI, to si tun fẹẹ sọ ẹkọṣẹ rẹ di tiwa-n-tiwa.
Ohun to da oju kọ ni bi irinṣẹ ti a mọ si AI yoo ṣe duro titi, o si tun n gbero lati ṣe irinṣẹ kan ti yoo maa ṣodiwọn agbara, eyi ti AI le lo lati yẹ ipa ti wọn n ni lara oju ọjọ wo.
Olori fawọn to n gbe eto ori ayelujara jade
Kauna Malgwi jẹ ajafẹtọọ oṣiṣẹ lẹka imọ ẹrọ (AI). Obinrin to kẹkọọ nipa iwoye naa jẹ olori fun ẹgbẹ aw ọn to n gbe eto ori ayelujara jade ni Naijiria. Oun lo maa n kede igbiyanju awọn eeyan to n fi imọ ẹrọ gbe nnkan jade nipa lilo ilana AI
Nibi iṣẹ rẹ to n ṣe tẹlẹ fun ẹka Facebook, Malgwi ṣalaye pe oriṣiiriṣii fidio loun ri nipa ifipabanilopọ, pipa ara ẹni ati lilo awọn ọmọde ni ọna ti ko tọ, eyi to ni o n fa keeyan ma le sun ati fifura si awọn eeyan yooku.
Malgwi jẹ ọkan lara awọn eeyan 184 to ti ba Facebook ṣiṣẹ ri ti wọn si ti pe ileeṣẹ Meta to ni Facebook lẹjọ. Bẹẹ ni wọn pe ẹka agbaṣẹṣe rẹ to wa ni Kenya naa lẹjọ pẹlu. Eyi waye lẹyin ti ami kan tu aṣiri pe wọn ko ṣe awọn oṣiṣẹ wọn daadaa.
O ti jẹrii niwaju igbimọ ilẹ Europe ri lati ja fun ẹtọ awọn eeyan to n gbe eto jade lori ayelujara.
Àwọn obinrin le ko ohun ti ko tọna lawujọ wa loju, ki won si yi ohun ti ko tọ pada, nipa ṣiṣe amulo ilana imọ ẹrọ ti yoo mu ilọsiwaju, alaafia ara ati ti ọkan wa.
Kauna Malgwi
Àgbẹ̀
Nigba ti baba rẹ ku ni 2015, Olga Olefirenko fẹẹ mu ala baba naa ṣẹ nipa iṣẹ agbẹ. Lẹyin to ra awon nnkan ọsin, o bẹrẹ si i ṣiṣẹ,ṣugbọn ai si owo wọle tọ ọ, o si pada ta gbogbo awọn ẹranko to ra naa.
Ṣugbọn ko wu u lati lati pa ohun to wu baba rẹ ti, baba rẹ to ku loju ogun gẹgẹ bii olori ogun .
Lọdun to kọja, o bẹrẹ okoowo kan, o n beere fu n iranlọwọ owo lati ọdọ awọn agba ọjẹ ni Ukrain, o si rowo gba lọwọ wọn.
Olga Olefirenko bẹrẹ iṣe oko rẹ pada, pẹlu erongba lati ṣe e nilana igbalode, ko si pese iṣẹ fawọn eeyan agbegbe, nibi ti wọn ti ri i bii aṣiwaju.
Olùdásílẹ̀, Stair Crusher Club
Nígbà tí Subin Park, ẹni tó ń lo àga arọ, ri pé òun kò lè rí àwọn ibìkan wọ̀ ní Seoul, ó lo ìmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ẹ̀rọ láti fi ṣàfihàn ohun tó ń là kọjá náà.
Park jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ Stair Crusher Club, àjọ tó máa ń lọ káàkiri orílẹ̀ èdè South Korea láti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn ibi tí àwọn tó ń lo àga arọ kò ti lè ṣe àmúlò ohun ìrìnsẹ̀ wọn.
Ohun tí ètò náà wà fún ni láti ṣe àkójọ àwọn máàpù àwọn ibi tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn le máa ṣàmúlò.
Àwọn èèyàn tó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ló ti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ fún wọn látara Stair Crusher Club, tí wọ́n sì ṣe àwárì ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá agbègbè ní orílẹ̀ èdè náà tí wọ́n le ṣàmúlò.
Onímọ̀ nípa AI
Lẹ́ni ogún ọdún, Sneha Revanur ti ń léwájú nínú iṣẹ́ AI. Òun ni olùdásílẹ̀ Encode Justice, tó jẹ́ ètò orí ayélujára fáwọn ọ̀dọ́ lórí AI, tó sì ti ní àwọn èèyàn 1,300 tó ń ṣe àmúlò rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè ọgbọ̀n.
Iṣẹ́ Revanur dá lé láti ṣe àmójútó ìdúnkokò tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ń mú wá àti ṣíṣe àfikún àwọn ọ̀dọ́ lórí ọ̀rọ̀ tó ń lọ.
Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Stanford University àti ọmọ ẹgbẹ́ ní Center for AI ànd Digital Policy.
Òun ni ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ tí orúkọ rẹ̀ yóò wọ Time Magazine fún ọgọ́rùn-ún èèyàn tí wọ́n gbajúmọ̀ lórí AI.
A ní àǹfàní láti tètè kojú àwọn ìpèníjà tí AI le mú wá kó tó bẹ̀rẹ̀ sí nípa. Fún èmi, ohun tí ìfarajìn túmọ̀ sí ni: lílékè ohun tó ti wáyé sẹ́yìn láti ṣe àyípadà ọjọ́ iwájú.
Sneha Revanur
Oludasilẹ ibudo itọju fun awọn eeyan to padanu ẹya ara
Lẹyin ti Russia kọlu Ukraine, Olga Rudnieva, ronu pe oun gbọdọ ṣe nnkan kan lati ran awọn ti ijamba kan lọwọ.
Oju ẹni ti tiẹ ti ba ni wọn fi n wo awọn eeyan to padanu ẹsẹ loju ogun, ṣugbọn Rudnieva ki i fi oju iru ẹ wo wọn. Ni tiẹ, akanda ẹda ni awọn eeyan naa, wọn si nilo iranlọwọ toun ba le ṣe fun wọn.
O da ileeṣẹ to n ri si idaamu ọkan eeyan silẹ ni Lviv, eyi to n dari rẹ to si tun gba awọn akọṣẹmọṣẹ si i. Ileeṣẹ naa n pese atọwọda ẹsẹ fawọn to ba nilo rẹ, aipẹ yii si ni wọn tun ṣe ifilọlẹ ibudo irapada fawọn ti nnkan n ṣe.
O ti le ni ẹgbẹrun kan eeyan to ti jẹ anfaani iṣẹ wọn laaarin ọdun meji akọkọ ti wọn berẹ iṣẹ.
Iduroṣinṣin ni pe ki eeyan ji laaarọ ko si maa gbọ ohun fere ya a fun un, ya a fun un, ṣugbọn sibẹ naa, k'eeyan ṣi maa ja fun orilẹede rẹ. O maa n jẹ keeyan mọ idi ti ohun to n ṣẹlẹ fi n waye, dipo ti eeyan yoo fi maa beere lọwọ ara re pe ki lo de to jẹ emi leyi n ṣẹlẹ si. Itumọ iduroṣinṣin ni pe ki eeyan maa wa ọna ti yoo fi le ṣe si i, ti yoo si maa dinku bojumọ ṣe n mọ.
Olga Rudnieva
Onimọ nipa nnkan ẹlẹmi ati agbegbe wọn
Silvana Santos jẹ onimọ nipa aisan ara ti ko wọpọ, oun paapaa sọ pe boun ṣe di ẹni to n ṣe iwadii aisan yii kan ṣẹlẹ ni. Adugbo to n gbe lo ti ṣalabapade idile kan ti aisan ti ẹnikẹni ko mọ n ba ja.
O ṣe iwadii lori aisan SPOAN (Spastic paraplegia, optic atrophy and neuropathy) Eyi jẹ aisan kan ti ko wọpọ, ṣugbọn to maa n daamu ara to si le fa rọpa-rọsẹ, ni Ariwa -Ila-Oorun Brazil.
Lati ogun ọdun to ti bẹrẹ iwadii rẹ niluu Serrinha dos Pintos, Santos ti ran awọn olugbe ibẹ ti aisan naa n ṣe lọwọ lati mọ ohun to n ṣe wọn gan-an.
O kẹkọọ nipa awọn aisan to n ṣe ara ti ko wọpọ ati ajọṣepọ wọn ninu igbeyawo, iyẹn laaarin awọn eeyan ti wọn jẹ ẹbi, ti wọn si n gbe ni agbegbe awọn talika ni Brazil
Bawo la ṣe n ṣafihan iduroṣinṣin? Nipa mimọ pe aye ko duro loju kan ni. Nigba ti ọgbẹlẹ ba de, a maa fara da a titi ta o fi bori rẹ. Nigba to ba si di akoko ojo, a o maa jẹ ninu ọpọ, a o si gbin eso.
Silvana Santos
Ajafetọọ nipa ayipada oju ọjọ
Ọmọ orilẹede Naijiria ni Adenike Titilope Oladosu, oun lo da ajọ 'I Lead Climate Action' silẹ. Iyẹn ajọ to wa fun awọn obinrin ati awọn ọdọ lati ja fun ọrọ to ba kan ayipada oju ọjọ.
O ti kede nipa odo Lake Chad to wa lorita Naijiria, Niger, Chad ati Cameroon, nibi ti omi to n dinku ti n da wahala silẹ.
Iṣẹ Oladosu ni i ṣe pẹlu ayika ati awujọ, paapaa apa ibi to kan awọn obinrin nibẹ. O maa n ro awọn obinrin lagbara nipa ọna ti wọn le gba maa ṣiṣẹ oko ti yoo si to wọn lati da duro, ti anito ounjẹ yoo si wa pẹlu.
Pẹlu bo ṣe ti n kopa ninu awọn ipade to n sọ nipa ayipada oju ọjọ kaakiri agbaye, bẹrẹ lati 2019, Oladosu rọ awọn alaṣẹ lati ri si ayipada oju ọjọ nilẹẹ Africa.
Iṣoro ayipada oju ọjọ ko ni ọgbọn kankan ti a le da, afi ki a koju rẹ ka si ṣẹgun. Lati ṣẹgun iṣoro yii, a nilo lati tẹpẹlẹ mọ ilana imọ ẹrọ ati ọgbọn atinuda.
Adenike Titilope Oladosu
Arìnrìnàjò ojú òfurufú
Nígbà tí Sunita Williams fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò sí ojú òfurufú lọ sí International Space Station (ISS) pẹ̀lú wíwọ ọkọ̀ Boeing Starliner lọ́jọ́ Karùn-ún oṣù Kẹfà, ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni pé òun ń lọ fún ìrìnàjò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ.
Àmọ́ nítorí àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tí wọ́n bá pàdé nínú ìrìnàjò náà, wọ́n sọ fún Williams àti akẹgbẹ́ rẹ̀, Barry Wilmore pé wọn kò ní padà sí orílẹ̀ ayé títí di oṣù Kejì ọdún 2025.
Williams, tó ti fẹ̀yìntì nídìí iṣẹ́ wíwa ọkọ̀ òfurufú fún iléeṣẹ́ ológun òfurufú, tó sì tún ti fìgbà kan rí jẹ́ obìnrin tó rìnrìn tó pọ̀ jùlọ lójú òfurufú, ni obìnrin àkọ́kọ́ tó sáré àsáyípo ní ojú òfurufú lọ́dún 2007.
Pẹ̀lú bí kò ṣe sí pẹ̀lú àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́, tó sì jìnà sí orí ilẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n irinwó kìlómítà, ó ti gbà pé àlékún ọjọ́ tí yóò lò lójú òfurufú náà pẹ̀lú ìfarajìn, tó sì júwe ojú òfurufú náà bíi ibi ìdùnnú rẹ̀.
BBC 100 Women máa ń ṣe àkójọ orúkọ àwọn obìnrin ọgọ́rùn-ún tó làmì laaka káàkiri àgbáyé ní ọdọọdún. A máa ń kọ ìròyìn pàtàkì àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò nípa àwọn obìnrin lórí ìkànnì gbogbo BBC.
Ẹ tẹ̀lé BBC 100 Women lórí Instagram àti Facebook. Ẹ lè darapọ̀ mọ́ ìtàkurọ̀sọ wa pẹ̀lú #BBC100Women.
Ikọ̀ BBC 100 Women ṣàkójọ orúkọ nípa ṣíṣe ìwádìí àti ìmọ̀ràn àwọn ikọ̀ ìròyìn BBC àgbáyé, World Service Languages àti BBC Media Action.
Àwọn obìnrin tó ti ní ipa láàárín ọdún kan sẹ́yìn ni àwọn tí à ń wá, tí wọ́n ní ìròyìn tó múni lọ́kàn tàbí tí wọ́n ti ṣe ìwúrí kan tó ní ipa lórí àwùjọ wọn.
Ọ̀pọ̀ orúkọ ni a ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àkórí ọdún yìí tó jẹ́ ìfarajìn. A fẹ́ ṣe àfihàn ipa tí ọdún yìí ti ní lórí àwọn obìnrin káàkiri àgbáyé nípa mímú àwọn -nípasẹ̀ ìfarajìn wọn - ń mú àyípadà bá ìgbé ayé agbègbè wọn tàbí orílẹ̀ ayé lápapọ̀. Bákan náà ni a tún ṣàgbéyẹ̀wò orúkọ àwọn obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ lẹ́ka àyípadà ojú ọjọ́ níbi tí a ti rí àwọn olùdásílẹ̀ nípa àyípadà ojú ọjọ́ àtàwọn olórí lórí ètò àyíká.
A tún ní àwọn aṣojú láti ètò òṣèlú àti ọ̀rọ̀ àwùjọ lápapọ̀.
A ṣe ìgbéléwọ̀n àwọn orúkọ náà lẹ́kùn ò jẹkùn kí a tó mú àwọn orúkọ tí a yàn. Gbogbo àwọn obìnrin náà ló gbà pé kí a fi orúkọ wọn síbẹ̀.
Ikọ̀ òṣìṣẹ́ BBC 100 Women Valeria Perasso, Natalia Pianzola, Maria Zaccaro, Rebecca Thorn, Lara Owen, Natasha Fernandes, Niamh Hughes, Shaina Oppenheimer, Sarah Tiamiyu and Rubab Batool.
Àlékún ìrànlọ́wọ́ fún iṣẹ́ yìí Vandana Vijay, Kateryna Khinkulova, Mariam Aman, Vera Kwakofi, Mouna Ba, Rupa Jha, Julien El-Hajj, Mark Shea, Chris Clayton, Yuna Ku, Issariya Praithongyaem, Paula Adamo Idoeta, Laura García, Ana Pais, Zhanna Bezpiatchuk, Zlata Onufrieva, Berza Simsek, Farhat Javed, Anastasia Soroka, Thais Carranca, Celestine Karoney, Shahnewaz Rocky, Khayrulla Ubaidullaev, Abdybek Kaziev, Katerina Tse, Sylvia Chang, Laura Bicker, Aye Thu San, Bui Thu, Do Hung, Farzad Seifikaran.
Olóòtú BBC 100 Women Golnoosh Golshani.
Olóòtú àgbà Claire Williams.
Olóòtú iṣẹ́ Fiona Crack.
Ìpèsè fún World Service Languages Rafael Chacón, Pip Joy và Carol Olona.
Ìyàwòrán Lily Huynh, Prina Shah, Jenny Law, Matt Thomas, Pauline Wilson and Oli Powell.
Ìdàgbàsókè Scott Jarvis, Arun Bhari, Alexander Ivanov, Matthew Taylor and Preeti Vaghela.
Orísun àwòrán Getty Images, Lauren Hurley/No. 10 Downing Street, Tracey Emin, Yoshimoto Entertainment, United World Wrestling, Stephanie King, Derrick Evans, Asta Kristjans, Shahnewaz Rocky, Annette Hornischer, Farhio Mohamed Hussein, Billsatya, Mohanad Elhussein, Mataara Stokes, Joe O'Shaughnessy, Tapas Mallick, @KuchuTimes, Melanoma Institute Australia, Christopher Michel, LeYa, M. Sven Torfinn, Mundele Badimubungi Alain, USA Archery, Daryna Lavrenko, Ko Oo, Alix McIntosh, Steve Gerrard, Kellys Portillo, Bangkok Pride, Mariana Castiñeiras, Diaspora Arts Connection, Acción Interna, Juan Pablo Orellana, Jean Francois Carly for Kathrine Hamnett/Samsung Global series, Paige Censale/Haitian Bridge Alliance, Gonzalo Marroquín, Raj Kumar Shrestha, Ravshan Musaev, HK studio, Lisa Palomino, Harold Levine, Media Wales, Nensi Ragab, Alexandre Nunis, Manon Obel/Clandestina, Hila Shiloni/Women of the Wall, Felix Speller/Design Museum, Kazım Kızıl, Hugo Mathy, Dmitry Aychuvakov, Ula Osman, NASA, Peter Giodano, Yero Adugna, Gauri Gill, Jumadyl Tokkojoev, Marco Conti Sikic, François Barrère, Social Fund for Development, Membley Studios, Greg C. Holland, Ben Cohen, Hagar Bader/Laba Impact House, nhân vật cung cấp.