Eto idibo ọdun 2023: Ki ni awọn ileri awọn ẹgbẹ oṣelu?
Awọn eto ẹgbẹ kọọkan
All Progressives Congress
Awọn ohun to ṣe pataki
Lari ṣe afikun bi Naijiria ṣe n fi ọja ranṣẹ silẹ okeere, ati adinku si bi bo ṣe n ko ọja wọle
Ṣe adinku iye ọdọ ti ko riṣẹ pẹlu idaji laarin ọdun mẹrin
Gbe igbesẹ lati ri daju pe ẹka eto idajọ ni ominira
Eto ọrọ aje
Ṣe atilẹyin fun awọn ileeṣẹ nla-nla
Ri daju pe ko si ọwọngogo mọ laarin ilu
Ṣe afikun ipese epo rọbi pẹlu ida ogun
Eto igabnisiṣẹ
Da iṣẹ ti iye rẹ to miliọnu kan silẹ ni ẹka imọ ICT laarin ọdun meji
Fi adinku si airiṣẹṣe nipa ṣiṣe atilẹyin fun awọn banki lati maa ya awọn ọdọ olokowo kekek lowo
Ṣe atilẹyin fun miliọnu meji oniṣowo lati kọ awọn ọdọ lori bi wọn ṣe maa da ileeṣẹ silẹ
Eto ilera
Ṣe ifilọlẹ eto adojutofo eto ilera fun o kere tan ida ogojin awọn ọmọ Naijiria laarin ọdun meji pere
Ṣe afikun ati idanilẹkọ fun awọn oṣiṣẹ eto ilera, paapaa awọn to wa ni ẹka eto ilera alabode
Ṣe atilẹyin fun kikọ awọn ile iwosan alagbeka fun anfani araalu
Ṣe atilẹyin fun ipese ipese oogun ati abẹrẹ ajẹsara labẹle
Eto abo
Ṣe afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ eto abo ati ipese iranwọ fun awọn ọmọ ogun to ṣubu loju ija ati awọn to farapa
Ṣe itgbesoke ohun ija, ohun elo ibaraẹnisọrọ ati ọkọ awọn awọn ọmọ ogun
Ṣe igbanisisẹ ati idanilẹkọ awọn ọmọ ogun atawọn oṣiṣẹ eto abo
Fi opin si ikọlu awọn agbebọn si dukia ijọba
Eto ẹkọ
Ṣe atunṣe ẹka eto ẹkọ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de ile ẹkọ giga
Ṣe ifilọlẹ eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ
Gbe owo kalẹ fun eto ẹkọ lara eyii ti awọn akẹkọọ yoo ti maa ya
Iwa ajẹbanu
Fi gbedeke si iye owo ti awọn adari atawọn oṣisẹ ijọba yoo maa na
Fi adinku si iye owo ijọba to n ṣofo
Ṣe iwuri fun awọn oṣiṣe to jafafa ki a si tu aṣiiri awọn ayederu oṣiṣẹ ijọba to n gba owo oṣu lai ṣiṣẹ
Fi adinku si bi iṣẹ ijọba ṣe n falẹ
Labour Party
Awọn ohun to ṣe pataki
Ṣe awọn ohun to ki ofin le fẹsẹ mulẹ, doju ija kọ iwa ajẹbanu ki a si ṣadinku iye owo ti ijọba n na
Mu Naijiria kuro ni ipo orilẹ-ede to n ko ọja wọle nika si eyii to n ko ọjalọ silẹ okere fun tita
Ran awọn araalu lọwọ lati ṣe aṣeyọri nipa ṣiṣe atilẹyin fun imọ sayẹnsi, imọ ẹrọ ati eto ẹkọ
Eto ọrọ aje
Mu ayipada ba ọrọ ajẹ pẹlu atilẹyin fun eto ọgbin
Din ọwọngogo ounjẹ atawọn nnkan mii ku, rii daju pe banki apapọ CBN ni ominira
Fi adinku si igbẹkẹle ijọba lori epo rọbi nikan
Yọ awọn ofin to mu ko ṣoro lati ko ẹru ato owo wọle lati ilẹ okeere
Eto igabnisiṣẹ
Ṣi anfani silẹ awọn olowo kekeke lati ya owo lọna ati di airiṣẹ ṣe ku lawujọ
Ṣe idagbasoke awọn araalu
Mu irọrun ba karakata lọna ati le mu ki awọn ileesẹ ilẹ okere wa si Naijiria
Ṣe awọn eto ti yoo mu ko rọrun fun awọn olokowo kekeke lati gberu si
Eto ilera
Ṣe afikun owo oṣu ati igbeaye awọn oṣiṣẹ eto ilera
Pese eto adojutofo eto ilera fun 133 miliọnu eeyan to kuṣẹ julọ ni Naijiria
Pese idanilẹkọ to peye fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ki wọn le jafafa si lẹnu iṣẹ wọn
Fun araalu ni anfani si eto ilera pẹlu owo perete
Eto abo
Fopin si ikọlu awọn abebọn
Fọwọsowọpọ pẹlu awọn orilẹ-ede ayika fun abo awọn ẹnubode wa
Ṣagbekalẹ ofin fun idasilẹ ọlọpaa agbegbe
Gba ọpọ eeyan siṣẹ ologun, ọlọpaa atawọn iṣẹ eto abo mii, a oo si fun wọn ni idanilẹkọọ atawọn atilẹyi mii ti wọn bas n fẹ
Eto ẹkọ
Gbe owo tabua kalẹ fun ẹkọ iṣẹ ọwọ, ere idaraya atawọn eto ẹkọ mii to rọ mọ imọ ẹrọ
Ya ọpọ owo sọtọ funeto ilera, eto ẹkọ ati ile gbigbe
Faye gba awọn ileeṣẹ aladabi lati maa dari awọn ile ẹkọ, ki ijọba si maa bojuto awọn ohun ti wọn n kọ nibẹ
Na ida 14% owo ijọba si eto ẹkọ
Iwa ajẹbanu
Ṣiṣẹ ni ilana to ba ofin iṣẹ ijọba mu
Maa ṣe ayẹwo bi gbogbo ẹka ṣe n na owo loorekoore
Fopin si afikun iranwo owo epo
Ṣe gbogbo iṣẹ ijọba ni gbangba loju gbogbo araalu
New Nigeria Peoples Party
Awọn ohun to ṣe pataki
Pese iṣẹ nipa eto ọgbin
Yanju iṣoro eto abo
Bọwọ fun ofin, a o si ṣe ohun gbogbo lọna to ba ofin mu
Eto ọrọ aje
Gbogun ti iwa ajẹbanu ni gbogbo ẹka ijọba lọna ati pa owo wọle fun ijọba
Ṣe igbelarugẹ eto ọrọ aje
Ṣe atunṣe si ipaarọ owo ilẹ okere
Eto igabnisiṣẹ
Mu adinku ba ainiṣelọwọ ọpọ araalu
Ṣe iwuri fun awọn ọdọ lati kopa ninu eto ọgbin
Ṣe iwuri fun awọn ileeṣẹ aladani lati da awọn ileeṣẹ to n pese ounjẹ silẹ ki awọn ọdọ le riṣẹ ṣe
Eto ilera
Ṣe atunṣe si eto adojutofo eto ilera ijọba apapọ
Mu adinku ba bi awọn araalu ṣe n lọ si oke okun fun itọju nipa ṣiṣe atunṣe si awọn ile iwosan wa ati fifun awọn oṣiṣẹ eto ilera wa ni ẹkọ to peye pẹlu ipese awọn irinṣe igbalode
Ṣe afikun eto iṣuna ẹka eto ilera
Eto abo
Gbogun ti iwa igbesumọmi
Ṣe atilẹyin fun iṣọkan awọn ọmọ Naijiria
A ko ni fi ohunkohun pamọ fun araalu
Eto ẹkọ
Pese owo gọbọi fun ẹka eto ẹkọ
A o ṣe igbeleke awọn ile ẹkọ giga wa ki a to maa da awọn miran silẹ
A o gbiyanju lati kọ ile gbigbe fun 20 miliọnu awọn ọmọ ti ko si nile ẹkọ to wa laarin igboro wa
Iwa ajẹbanu
A oo ṣe atilẹyin fun awọn ajọ ijọba to gbogun ti iwa ajẹbanu
A ko ni fi ohunkohun pamọ fun araalu
A oo lo imọ ẹrọ lati gbogun ti iwa ajẹbanu
Peoples Democratic Party
Awọn ohun to ṣe pataki
Fun ẹka aladani laaye lati ṣiṣẹ daadaa
Ṣe atilẹyin fun iṣọkan Naijiria nipa yiyan awọn lati gbogbo Naiojiria sipo ijọba
Ṣe atunto eto ijọba Naijiria
Eto ọrọ aje
A o ri daju pe GDP yoo ti gberasọ si ilọpo meji iyẹ $5,000 (£4,200) titi ọdun 2030
Ṣe agbekalẹ awọn amayedẹrun faraalu
A oo ṣe afikun bi a ṣe n wa epo rọbi si miliọnu meji 'barrels' lọjọ kan ṣoṣo titi ọdun 2027
Eto igabnisiṣẹ
A oo da milọnu mẹta tuntun silẹ, a o si mu miliọnu mẹwaa eeyan kuro ninu iṣẹ
A o ṣe agbekalẹ eto igbanisiṣẹ fun awọn araalu
Idasilẹ awọn ileeṣẹ ti yoo ran awọn olokowo kekeke lọwọ
Eto ilera
A o ṣagbekalẹ eto ilera ti owo rẹ ko dani lagara fun awọn araalu ko to di ọdun 2030
A o ṣe iwuri fun awọn dọkita to wa nilẹ okere lati pada wale
Atilẹyin fun awọn ileeṣẹ apoogun lati maa po oogun labẹle
Eto abo
A o ṣeto iforukọsilẹ awọn ọmọ tuntun lati mọ iye araalu ati lati gbogun ti iwa ọdaran
A o gba nnkan bii miliọnu kan eeyan siṣẹ ọlọpaa gẹgẹ bii alakalẹ UN
Ṣe atunṣe si ibaṣepọ awọn ọmọ ogun atawọn araalu
Ṣe atunto ẹka eto abo
Eto ẹkọ
Ṣe igbelarugẹ ẹkọ imọ syẹnsi ati iṣẹ ọwọ
Ṣe agbẹkalẹ ileeṣẹ ti yoo maa bojuto awọn ile ẹkọ giga
Na obitibiti owo si ọna oju popo, oju irin, ina mọnamọna ati ile gbigbe
Iwa ajẹbanu
Ṣe eto iwuri fun awọn oṣiṣẹ ijọba
Lo imọ ẹrọ lati gbogun ti iwa ajẹbanu
A o ri daju pe awọn idajọ ile ẹjọ lori iwa jẹgudujẹra mulẹ
End of Eto idibo ọdun 2023: Ki ni awọn ileri awọn ẹgbẹ oṣelu?