Báyìí ni etò òṣèlú se bẹ̀rẹ ni ìran Saraki
Ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti salábàpàdé àwọn oríṣríṣi ìdíle tíwọn sábà ń dipò ńlá mú nínú ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà látí ìran wọn kan sí ìran wọn míràn tó ń bọ̀. Bayìí ní ọ̀rọ̀ ṣe rí ní ti ìdílé Ààrẹ Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin, Sẹnatọ Bukola Saraki, tó jẹ́ ọkan lára ìdílé Saraki. Látàrí bí ó ṣe kùnà níbi ìdìbò abẹ́lẹ́ tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP se fún àwọn tí yóò díje fún ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2019, a ṣe àgbéyẹ̀wò ilà òpó ìdílé sàràkí nínú ètò òṣèlú Nàìjíríà.
Abubakar Olusola Saraki - àworan
Abubakar Olusola Saraki
(Oṣù Karun, ọdun 1933- Oṣù Kọkanla, ọdun 2012)
Ó jẹ Dokita onimọ ìṣègùn òyìnbó kí ó to darapọ mọ́ ètò òṣèlú, ó jẹ sẹnatọ láàrìn ọdún (1979-1983) tó ó si dí adarí ilé. Ó kú ní Ọ̀jọ́ Kẹrìnlá, Oṣù Kọkanla, ọdún 2012
Ètò òṣèlú lẹ́sẹẹsẹ
  • 1977
    Ọ́kan lára ọmọ ilé ti wọn dìbò yan, ó wà lára àwọn tí wọn ṣe àgbékalẹ̀ ìwé ofin 1979
  • 1979
    Ṣẹnatọ tí wọn dibo yan lẹ́yìn omìnìra keji
  • 1983
    Wọn tún tun yàn sí ilé ìgbìms aṣofin àgbà lábẹ̀ àsíà ẹgbk òṣèlú NPN
  • 1998
    Ó di adari àpapọ̀ àti ọmọ ìgbìmọ fún ẹgbk òṣèlú All People's Party (APP)
  • 2001
    Olorí ẹ̀ka kan nínú ẹgbẹ́ Arewa Consultative Forum, tó jẹ́ ẹgbẹ́ tó wà fún àṣà àti àwọn ètò òṣèlú, wọn ran láti ló ṣe ìpàdé àti láti fọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn gómìnà Arewa àti àwọn adarí kan lójúnà àti ní àfojúsùn kan náà.
  • 2003
    Ó gbárùkù ti ọmọ rẹ̀, Bukola Saraki láti dupò Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara lọ́dún 2003.
  • 2003
    Ó tún gbárùkù tí ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí aṣojúilé ìgbìmọ aṣofin àgbà tó ń sójú ẹkùn gbùngbùn Kwara.
Abubakar Bukola Saraki - àworan
Abubakar Bukola Saraki
Oṣù Ọpẹ́ 1962 títí di àsìkò yìí
Bukọla náà kọ́ ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó. Òun ní ọmọ gbájúgbaja olóṣelú Abubakar Olusola Saraki tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí (Olooyee). Ó bẹ̀rẹ̀ òṣèlú ó sì dí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ní ọdún 2003 (àtúnṣe)
Ètò òṣèlú lẹ́sẹẹsẹ
  • 2003
    Wọn yàn án gẹ́gẹ́ bíi gọmìnà ìpínlẹ̀ Kwara
  • 2007
    Wọn tún tún-un yàn gẹ́gẹ́ bii gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara
  • 2011
    Wọn yàn-án gẹ́gẹ́ bíi sẹnátọ̀ lábẹ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Peolple's Democratic Party (PDP) láti sojú ẹkùn gbùngùn Kwara
  • 2015
    Wọn tún Saraki yàn sípò Sẹnatọ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC)
  • Ọjọ́ Kẹsan, Osù Kẹfa 2015
    Ó di ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìkẹẹjọ
  • ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n Osù Agẹmọ 2018
    Ó tún pẹgbẹ́da sí égbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP)
  • Oṣù Kẹjọ, 2018
    Bukola Saraki kéde èróngbà rẹ̀ láti díje dupò ààrẹ lọ́dún 2019
  • Ọjọ́ kẹfa, Oṣù Kẹwaa, 2018
    Ó kùnà láti jáwé olúbori níbí ìdìbò abẹ́lé lati dupò ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, tí Atiku Abubakar si gbàá dípò rẹ̀
Gbemisola Ruquayyah Saraki - àworan
Gbemisola Ruquayyah Saraki
Òbìbí 1965 titi di àsìkò yìí
Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ètò ọrọ̀ ajé àti ètò adójútòfò. ó tún jẹ àbúrò ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Bukola Saraki, òun náà ní ọmọ olóògbé Olusola Saraki
Ètò òṣèlú lẹ́sẹẹsẹ
  • 1999
    Wọn dìbò yàn-án sí ilé aṣojú sòfin láti sojú Asa/ Iwoorun Ilorin ìpínlẹ̀ Kwara.
  • 2003-2011
    Bakan náà ó tún lọ fún ipò sẹnatọ lati sójú ẹkùn gbùngùn Kwara lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP)
  • 2015
    Ó pàdánù níbi ìdìbò àbẹ́lé fún gomina Kwara lábẹ́ àsíá PDP
  • ọjọ́ keje, oṣù igbe 2015
    Ó pa égbẹ́dà sí All Progressives Congress (APC)
  • 2016
    Ààrẹ Muhammadu Buhari yàn-án gẹ́gẹ́ bii àlága Fasiti ìjọba àpapọ Otuoke, Bayelsa
  • 2018
    Ó kéde àtìlẹyìn rẹ fún èrongba ààrẹ Buhari lati tún lọ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ ladún 2019

Awọn to ni àworán

Getty Images, Facebook