Bola Ahmed Tinubu
Wọn burawọle fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bi aarẹ16th ni May 29
O di ipo gomina Eko mu larin ọdun 1999-2007
O tun ṣe sẹnetọ ipinlẹ Eko, akọṣẹmọṣẹ iṣiro si tun ni pẹlu.
Wọn burawọle fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu gẹgẹ bi aarẹ16th ni May 29
O di ipo gomina Eko mu larin ọdun 1999-2007
O tun ṣe sẹnetọ ipinlẹ Eko, akọṣẹmọṣẹ iṣiro si tun ni pẹlu.
Igbakeji aarẹ Kahim Shettima ni igbakeji aarẹ Naijiria lọwọ lọwọ
Ohun ni gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ ri
O sisẹ fun igba pipẹ ni ẹka banki
Wọn ti yan Mohammed Badaru gẹgẹ bi minisita fun ileeṣẹ iroyin
O ti di ipo gomina Jigawa tẹlẹ ri lati ọdun 2015 si 2023
Ohun ni alaṣẹ ileeṣẹ Talamiz pẹlu awọn ẹka to n risi ọkọ ayọkẹlẹ,eto ọgbin ati ṣiṣe akoso ẹranko
Abubakar lo kawe gboye imọ iṣiro owo ni fasiti Ahmadu Bello,Zaria.
Wọn ti yan Bello Matawalle gẹgẹ bi minisita labele fun ileeṣẹ eto aabo
O ti jẹ gomina ri nipinlẹ Zamfara
O kẹkọ gẹgẹ bi olukọ,to si tun di ipo aṣojuṣofin mu.
Wọn ti yan Olawale Edun gẹgẹ bi Minisita fun eto iṣuna ati iṣakoso eto ọrọ aje
Oun ni olubadamọran fun aarẹ Bola Tinubu lori ohun to niiṣe pẹlu eto owo
oun naa ni kọmiṣọnna tẹlẹ fun eto iṣuna nipinlẹ Eko
O ti ṣiṣẹ fun Banki Agbaye lori eto ọrọ aje ati isuna fun awọn agbegbe Carribbean ati Latin Amerika
O wa lara oludasilẹ Stanbic IBTC Bank
Wọn ti yan Atiku Bagudu gẹgẹ bi
Minisita fun eto isuna ati eto ọrọ aje
O jẹ ọrẹ korikosun adari ijọba ologun nigba kan ri,Sani Abacha, ti wọn si fi atimọle fun ẹsun lilu owo ilu ni ponpo lorilẹede Amẹrika,ti wọn si da pada si ile
Olubunmi Tunji Ojo ni Minisita fọrọ abẹle
Ọmọ ile igbimọ aṣojuṣofin ni.
O kẹkọgboye imọ ijinlẹ keji ni ibanisọr ori ayelujara ati ikani ayelujara ni fasiti London Metropolitan.
Tahir Mamman ni wọn ti yan gẹgẹ bi minisita fun eto ẹkọ
Oun ni igbakeji adari fasiti Baze University ni ilu Abuja
O tun jẹ ọjọgbọn imọ amofin ati agbẹjọro agba
O ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ileẹkọ imọ ofin,Nigerian Law School lati ọdun 2005-2013
Tanko Sununu ti gba ipo Minisita abẹlẹ fun eto ẹkọ
Sununu jẹ ọmọ ile aṣofin lati Kebbi
O tun jẹ dokita nipa obinrin ni Ileewosan ijọba ni Birnin Kebbi, nibi to ti ṣiṣẹ ni ọdun 2012
Ali Pate ti gba ipo Minisita fun eto ilera ati ọrọ awujọ
Onimọ nipa eto ilera lawujọ ni ni Fasiti Harvard
O ti ṣiṣẹ gẹgẹbi adari eto ilera,ounjẹ ati awọn araalu ati adari ajọ to n risi awọn obinrin,ọmọde ati ọdọ fun banki agbaye
Tunji Alausa ti gba ipo gẹgẹ bi minisita abẹle fun eto ilera ati awujọ
Oun ni oludasilẹ ileewosan Kidney Care Center ni Illinois,lorilẹede Amẹrika
Onimọ nipa ilera kidinrin naa ni irir to le ni ọgbọn ọdun ni idi iṣẹ eto ilera
Ibrahim Geidam ni wọn yan gẹgẹ bi Minisita fun ileeṣẹ ọlọpaa
O di ipo gomina mu fun saa meji,to si tun di ipo sẹnetọ mu fun saa meji lati ipinlẹ rẹ.
O ni iwe ẹri nipa isiro owo, to si jẹ ọkan lara awọn ajọ Certified Public Accountant of Nigeria
Imaan Suleiman Ibrahim gba ipo gẹgẹ bi minisita abẹle fun ileeṣẹ ọlọpaa
O ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ni ileeṣẹ National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons,ki wọn to gbe lọ si ileeṣẹ to n risi awọn ogunlende.
David Umahi ni minisita fun iṣẹ ode
Sẹnetọ ni lati ipinlẹ Ebonyi nibi to ti jẹ gomina fun saa meji laarin ọdun 2015 sii 2023.
Ahmed Dangiwa ni Minisita fun ile gbigbe ati idagbasoke ilu
oun ni oludari agba banki ayanilowo kọle ti ijọba Naijiria.
Ahmed Tijani Gwarzo ni minisita keji fun ile gbigbe ati idagbasoke ilu
Igbakeji gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Kano ni laarin ọdun 2007 si 2011.
Ile ẹkọ giga fasiti imọ iṣejọba lorilẹede South Afrika lo wa gẹgẹ bi oluwadi imọ ijinlẹ.
O kẹkọ gboye imọ ijinlẹ nipa imọ ẹrọ
Alkali Ahmed ni Minisita fun igbokegbodo ọkọ
O di ipo Sẹnetọ mu lati ipinlẹ Gombe laarin ọdun 2010 si 2023
O kawe gboye imọ ijinlẹ ninu eto ọrọ aje
ọmọwe Betta Edu ni Minisita fun eto ileṣẹ lugbẹ
Ọmọwe ni,bakan naa lo tun jẹ olori awọn obinrin lẹgbẹ oṣelu APC
O kawe gboye ijinlẹ ninu eto ilera alabọde lati ile ẹkọ fasiti London School of Hygiene & Tropical Medicine ati Ọmọwe ninu imọ eto ilera alabọde ni fasiti Texila American University.
Waheed Adebayọ Adelabu ni Minisita fun ohun amuṣagbara.
O ti fi igba kan ri jẹ igbakeji gomina ni banki apapọ NAijiria.
O du ipo gomina ipinlẹ Ọyọ lọdun 2019. ileeṣẹ isiro owo Pricewaterhouse coopers lo ti bẹrẹ iṣẹ gẹgẹ bi olusiro owo.
Abubakar Kyari ni Minisita fun eto ọgbin ati ipese ounjẹ
O ti ṣe sẹnetọ fun ipinlẹ Borno laarin ọdun 2015 si 2022
o kẹkọ gboye imọ ijinlẹ keji ninu akoso okoowo lati ile ẹkọ giga fasiti Webster University,St Louis Missouri,USA
Aliyu Sabi ni Minisita keji fun eto ọgbin ati ipese ounjẹ
O lo saa meji gẹgẹ bii sẹnetọ to ṣoju ipinlẹ Niger laarin ọdun 2015 si 2023
Joseph Ustev ni Minisita fun ipese omi ati imọtoto
O kẹkọ gboye ọmọwe ninu imọ ijinlẹ nipa ipese omi ati imọ nipa ayika
o ti figba kan ri jẹ oludari ajọ idagbasoke iṣẹ ọwọ ni fasiti ijọba fun eto ọgbin apapọ laarin ọdun 2013 si 2017
o tun di ipo kọmiṣọna fun ipese omi ati ayika mu ni ipinlẹ Benue
Bello Muhammad Goronyo ni Minisita fun ipese omi ati imọtoto.
Oun ni kọmiṣọna feto iroyin tẹlẹ ni ipinlẹ Sokoto.
Abubakar Momoh Minisita fun idagbasoke ẹkun Niger Delta
Onimọẹrọ ni, igb meji ọtọọtọ lo si ti wọle si ile igbimọ aṣojuṣofin.
John Eno ni Minisita fere idaraya
Sẹnetọ to ṣoju ipinlẹ Cross rivers laaring ọdun 2015 ati 2019
o tun figbakan jẹ aṣofin ipinlẹ ati aṣofinṣoju
Adegboyega Oyetọla ni Minisita fun ohun alumọni ati ọrọ aje ori omi
O jẹ gomina ni ipinlẹ Osun laarin ọdun 2018 si 2022
Eto idojutofo lo fi bẹrẹ lẹyin to kẹkọgboye imọ nipa idojutofo ni fasiti ilu Eko.
Bosun Tijani ni minisita fun ibanisọrọ, ọgbọn inu ati ọrọ aje ori ayelujara.
Oludasilẹ ileeṣẹ CcHub ni.
O kẹkọ gboye ọmọwe ninu imọ ọgbọn inu ati idagbasoke ọrọ aje ni fasiti ilu Leicester
Yusuf Miatama Tuggar ni Minisita fọrọ ilẹ okeere.
Ọmọ ile igbimọ aṣofinṣoju tẹlẹ laarin ọdun 2007 si 2011.
Oun si tun ni aṣoju ijọba NAijiria si orilẹede Germany lati ọdun 2017
Festus Keyamo ni Minisita fun irinna ofurufu.
Oun ni minisita keji fun idagbsoke ẹkun Niger Delta ati fun ọrọ oṣiṣẹ labẹ iṣejọba.
Amofin ati ajafẹtọ ọmọniyan ni.
Ishak Salako ni Minisita keji fun ọrọ ayika.
Dokita iṣegun oyinbo ni, o si tun ti dipo kọmiṣọna feto ilera ri ni ipinlẹ Ogun
Oun ni alakoso ajọ Ogun West Stakeholders Forum.
Uche Nnaji ni Minisita fun imọ ẹrọ ati Sayẹnsi
Oniṣowo.
Muhammad Idris Minisita fun eto iroyin ati itaniji.
Oun ni oludasilẹ ileeṣẹ iwe iroyin ati mohunmaworan Blueprint.
O kẹkọgboye imọ ijinlẹ keji ninu imọ ede oyinbo.
Dokita Dorris Aniche Uzoka ni Minisita fun idaleeṣẹ silẹ, katakara ati idokoowo
Dokita iṣegun oyinbo ni, oun ni kọmiṣọna fọrọ aje tẹlẹ ni ipinlẹ Imo.
Shuaibu Abubakar Minisita fun idagbasoke irin tutu.
oludari agba ni ni banki Standard IBTC Bank pẹlu ọpọlọpọ iriri ni eto idokoowo ati akoso dukia.
O kẹkọ gboye imọ ijinlẹ keji ni fasiti Oxford ni ilẹ Gẹẹsi ati fasiti Leicester.
Dele Alake ni Minisita fun idagbasoke ohun alumọni inu ilẹ
oun ni olubadamọran pataki fun aarẹ Tinubu lori akanṣe iṣẹ, ibanisọrọ ati eto
O figbakan jẹ kọmiṣọna fun eto iriyin ni ipinlẹ Eko.
Akọroyin to pegede ni.
Uba Maigari ni Minisita keji fun idagbasoke irin tutu
igbakeji gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Taraba ki wọn to yọọ nipo lẹyin idibo ọdun 2003.
Agbẹjọro ni
Heineken Lokpobiri ni Minisita keji fun ọrọ epo rọbi.
saa meji lo lo gẹgẹbi sẹnetọ ki o to di minisita keji fun eto ọgbin ati idagbasoke ẹsẹ kuku lọdun 2015 labẹ iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.
Agbẹjọro ni.
Ekperipe Ekpo ni Minisita keji fun afẹfẹ gaasi
Ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ laarin ọdun 2007 si 2011.
Simon Lalong Bako ni Minisita fun ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisṣẹ
Saa meji lo lo gẹgẹbi gomina ipinlẹ Plateau
O di ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Plateau lọdun 1998 ki o to di olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lọdun 2000
Oun ni adari agba igbimọ to ṣe kokari eto ipolongo idibo aarẹ Tinubu
Lọla Ade-John ni Minisita fun irinajo afẹ
Akọṣẹmọṣẹ iroyin ati imọẹrọ ni pẹlu ile ifowopamọsi Access Bank, United Bank for Africa, Ecobank ati Novateur Bussiness Technology.
O kẹkọgboye ijinlẹ ninu imọ ẹrọ Kọmputa ni fasiti ilu Ibadan
Nkeiruka Onyejeocha ni Minisita keji fun ọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ.
mọ ile igbimọ aṣofin apapọ lati ipinlẹ Abia.
Alaga fidihẹ tẹlẹ ni ijọba ibilẹ Umunneochi ni ipinlẹ Abia
Lateef Fagbemi ni Minisita fun eto idajọ ati agbẹjọro agba.
Ọdun 1984 lo bẹrẹ iṣẹ agbẹjọro,o si ti gboye SAN.
Uju Kennedy-Ohanenye ni Minisita fọrọ awọn obinrin.
Oniṣowo to ni ọpọlọpọ idokoowo lẹka ikọle ati eto ẹkọ
Nyesom Wike ni Minisita folu ilu Naijiria.
oun ni gomina ipinlẹ ipinlẹ Rivers laarin ọdun 2015 si 2023.Agbẹjọro ni.
Mariga Mahmud ni Minisita keji folu ilu Naijiria.
O ti figba kan di ipo kọmiṣọna eto ẹkọ giga mu ri ni ipinlẹ Kano.
Ọmọ igbimọ to ga julọ fun eto iṣegun oyinbo ni Naijiria ati ẹkun iwọ oorun afrika ni.
Hannatu Musawa ni Minisita fun aṣa, iṣe ati ọrọ aje iṣẹ ọpọlọ.
Oun ni olubadamọran pataki fun Aarẹ Tinubu lori ọrọ aṣa, ati imuludun.
Agbẹjọro ni, o si n kẹkọ lati gboye Ọmọwe.
Zephaniah Jisalo ni Minisita fun akanṣe iṣẹ ati ajọṣepọ ẹka ijọba gbogbo.
Igba meji ni wọn yan an gẹgẹbi aṣojuṣofin ati alaga ijọba ibilẹ Abuja Municipla Area council.
Akẹkọ gboye nipa imọ Psychology, eto iṣedajọ iwa ọdaran ni fasiti ilu Jos.