Awọn akanlo ede eto idibo 2019

Kini iyatọ to wa laarin titọpinpin idibo ati onwoye idibo? Atundi idibo ati atundi idibo ti ko ba si ẹni to jawe olubori?

Gẹgẹ bi eto idibo ọdun 2019 ṣe ti n kanlẹkun ni oṣu keji ati ikẹta, oriṣiiriṣii ọrọ bayii ni o maa maa jẹ jade. Eyi ni ilana to rọrun ti yoo jẹ ki o mọ itumọ awọn ọrọ to ta koko

A


Accreditation (Ayẹwo orukọ) : Eyi ni igbese lati se ayẹwo orukọ ki idibo to bẹrẹ.

B


Ballot box (Apoti idibo) : Eyi ni apoti idibo ti wọn ti pa, amọ to ni oju iho kekere ti awọn oludibo le ju ibo wọn si, ki wọn to maa kaa.

Ballot paper (Iwe idibo) : Iwe idibo ni iwe ti orukọ awọn ti o n dije ni ẹkun kọọkan wa.

Bye-election (Idibo si ipo asofin) : Eyi ni eto idibo to waye lati yan asofin miran sipo, lẹyin iku ẹni to wa nibẹ tẹlẹ. Eyi tun le waye lẹyin ti awọn oludibo ba yọ ẹni to wa nipo kuro nitori magomago tabi aṣemaṣe.

C


CVR :

Card reader (Kaadi itẹka) : Kaadi itẹka ni ohun elo ti wọn maa n lo lati fi se ayẹwo ika ti oludibo fẹ lo, boya tirẹ ni tabi tirẹ kọ.

Claim : Eyi ni igbese ti awọn eniyan maa n gbe lẹyin ti wọn ba ri abawọn tabi aisedede ninu iforukọsilẹ ti wọn se.

D


Display : Eyi ni sise afihan orukọ awọn to fi orukọ silẹ lati le dibo, ki awọn eniyan ti ko ba tẹ lọrun le pe akiyesi Ajọ INEC si.

E


EMB : Ajọ to n ṣakoso eto idibo.(ẹka mẹtadinlogoji lo wa ni Naijiria. i.e Ajọ INEC ati Ajọ SIEC ni ipinlẹ kọọkan (36).

Election Monitors (Olutọpinpin idibo) : Awọn wọn yii jẹ osisẹ Ajọ INEC ti wọn n ṣabẹwo si awọn agbegbe idibo lati mọ bo se n lọ.

Election Observers (Onwoye lasiko idibo) : Awọn wọn yii ni ajọ tabi ẹgbẹ to n se onwoye lasiko idibo, wọn maa n lọ si agbegbe ti idibo ti n waye lati bojuto eto idibo lati ibẹrẹ titi de opin. Awọn onwoye idibo meji lo wa. i.e. Onwoye idibo abẹlẹ ati onwoye lati ilẹ okeere.

Eto idibo ni gbangba : Eyi ni ọna ti awọn awọn oludibo n gba dibo ni kọrọ, sugbọn ti wọn yoo wa fi iwe idibo wọn sinu apo idibo ni gbangba.

G


General Elections (Idibo gbogboogbo) : Idibo gbogboogbo jẹ eto idibo to ma n waye kaakiri awọn ipinlẹ to wa lorilẹ-ede lati yan awọn oludibo si ipo, lẹyin ti awọn to wa nibẹ tẹlẹ ba ti pari saa wọn.

I


INEC : Ajọ eleto idibo lorilẹ-ede Naijria

Inconclusive election (Eto idibo ti ko ni ẹni to jawe olubori) : Eyi ni eto idibo ti o sẹle leyin ti iye awọn to se iforukọsilẹ lasiko idibo to iye eniyan ti o le sọ bi esi idibo yoo se ri.

M


Manifesto (Iwe ipolongo) : Eyi ni iwe to kun fun awọn ohun ti ẹgbẹ oselu kan nireti lati se ti wọn ba jawe olubori lasiko idibo. Iwe yii ma n se afihan ohun ti ẹgbẹ duro fun ati ọna ti wọn fẹ gba lati mu aye dẹrun fun awọn eniyan.

N


Nomination (Yiyan oludije) : Yiyan oludije sipo jẹ ọkan lara awọn eto ti awọn ẹgbẹ oselu fi n se eto lati gbe oludije jade lẹgbẹ oselu wọn.

O


Objection : Eyi ni igbese kotẹmilorun ti awọn eniyan maa n gbe ti wọn ko ba faramọ atẹjade ti Ajọ INEC fi sita lasiko ti wọn n le orukọ awọn to forukọsilẹ fun eto idibo.

Opposition (egbe alatako) : Ẹgbẹ alatako ni ẹgbẹ ti ko si ni ijọba, amọ to jẹ awọn lo poju lẹyin ẹgbẹ to wa ni ijọba.

P


PRV : Eyi ni iwe ti orukọ awọn ti o ti se iforukọsilẹ wa. Ajọ INEC ma n le iwe yii ki awọn eniyan le lọ yẹ orukọ wọn wo bọya orukọ wọn wa ni pese, ati bi o ti yẹ.

PVC :

Party Agent (Asoju ẹgbẹ oselu) : Eyi ni ẹni ti o n soju ẹgbẹ oselu tabi oludije ni ibi ti wọn ti n ka ibo ni ọjọ idibo.

Party primary (Idibo abẹle) : idibo yii ma n waye ninu ẹgbẹ oselu kọọkan lati yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ lati dije dupo ni ọjọ idibo.

Polling Unit (Agọ idibo) : Agọ idibo ni agbegbe to wa ni itagbangba nibi ti Ajọ INEC fi ọwọ si wi pe idibo yoo ti waye.

R


Re-run election (Atundi idibo) : Idibo yi ma n waye ti idibo alakọkọ ba ni magomago ninu, tabi ti awọn eleto idibo ko ba tẹlẹ alakalẹ eto idibo.

Recall (Yiyọ oloselu) : Yiyọ oloselu jẹ eto ti awọn oludibo le gbe lati yọ asoju ni Ile Igbimo Asofin Ipinlẹ ati ti ijọba apapọ kuro ni ipo.

Rejected ballot (Awọn ibo ti wọn kọ) : Awọn ibo ti wọn kọ ni awọn ibo ti ko ṣafhan eni ti oludibo naa dibo fun daadaa, nitori wọn ko tẹ ika si iwaju ẹni ti wọn fẹ dibo fun bi o ti yẹ, nitori naa, awọn eleto idibo a da ibo naa nu nitori itẹka naa ko si loju ibi to yẹ ko wa.

Return (Dida oludije pada) : Eyi ma n waye ti oludije to ti wa ni ipo tẹlẹ ba jawe olubori, ti Ajọ INEC wa fun ni iwe lati da a pada si ipo.

Returning Officer (RO) (Oṣiṣẹ Ajo INEC) : Eyi ni osisẹ Ajo INEC ti yoo sọ esi idibo lẹyin ti wọn ba ti ka a.

Run-off election (Atundi idibo) : Idibo eyi maa n waye ti ko ba si ẹni to jawe olubori lọna to lamilaaka si ipo gomina tabi aarẹ orilẹ-ede. Eyi le waye ti ẹni to ba jawe olubori ko ba bori lawọn agbegbe to se pataki lati jawe olubori.

S


SIEC (Ajọ eleto idibo ni ipinlẹ.) : Ajọ eleto idibo ni ipinlẹ ni o wa ni isakoso idibo ni awọn ijọba ibilẹ. Ipinlẹ kọọkan lo ni ajọ yii lati le sakoso eto ibo.

T


Tactile Ballot Paper (Iwe idibo awọn akanda ẹda) : Iwe idibo yii wa fun awọn ti o ni aisan oju ti ko si le riran daradara, ki wọn baa le dibo wọn ni ikọkọ lai si iranwọ ẹnikẹni (i.e ni idakọnkọ ati lai si iranwọ ẹnikẹni)

Tendered ballot paper (Idibo to ni bosejẹ) : Eyi ni iwe idibo fun oludibo, lẹyin ti ẹlomiran ti lo orukọ rẹ lati fi dibo. Nitori naa ni wọn yoo se fun un ni iwe idibo miran, amo ti o ba ti dibo tan, asoju Ajọ INEC to wa nibẹ ko ni fi sinu apoti idibo, yoo fi si ibomiran.

Turnout : Eyi ni lati se akawe oye awọn eniyan to jade lati wa dibo lasiko eto idibo ni agbeegbe ti wọn ti n dibo.

Orisun

Ajọ INEC Naijiria, BBC