Muhammadu Buhari
Ẹgbẹ oṣelu APC yoo mu gbogbo ilana ẹkọ to wa ninu eto Universal Basic Education Act wa si imusẹ lori eto igbaniwọole to dọgba laarin akọ ati abo ni ile iwe alakọbẹrẹ ati girama, pẹlu ipese eto ẹkọ to lamilaaka: awọn yoo lo ida marundinlogun owo isuna ọdọọdun si eto ẹkọ ki wọn ba le pese iranwọ ati idanilẹkọ to yanju fun awọn olukọ.
Agbeyẹwo Ọrọ

Eto ilana ẹkọ ti ọdun 1999 ni ki ijọba pese eto ẹkọ ọfẹ fun awọn akẹẹkọ ni ile iwe alakọbẹrẹ. Awọn akẹẹkọ gbọdọ lọ si ile iwe alakọbẹrẹ ati ọdun mẹta to saaju ni girama, amọ ti ijọba ipinlẹ ko nii san owo yii.

Ilana yii ko sọ iye akọ ati abo ti wọn gbọdọ lo si ile iwe ni igba kan naa, ṣugbọn lorilẹede Naijiria bayii, awọn ọkunrin n lọ si ile iwe ju awọn obinrin lọ.

Nitorina ipese ma n wa fun awọn obinrin lati le wọ ile iwe ki iye wọn ba le dọgba pẹlu awọn ọkunrin wọn.

Ẹka Ajọ Isọkan Agbaye to n risi eto ẹkọ, Unesco sọ wi pe eto igbani si ile iwe laarin akọ si abọ, gbọdọ jẹ 98 ati 102 awọn obinrin si iye 100 ọkunrin to ba wọle si ile iwe.

Amọ, ayẹwo fihan wi pe o din ni ipinlẹ kan ninu mẹta to n wo iye awọn obinrin si ọkunrin to wa ni ile iwe alakọbẹrẹ. Ni ile iwe girama ti ọlọdun mẹta ti ipele akọkọ, ipinlẹ mẹsan lo ni eto yii, nigbati ile iwe girama ti awọn akẹẹkọjade ko ju ipinlẹ mẹta.

Ipinlẹ Ekiti lo ṣe daadaa ju nipa wiwo alafo to wa laarin akọ sabo ni gbogbo ipele eto ẹkọ.

Katsina lo gbẹyin ninu eto yii, 170,000 ni iye ọkunrin fi ma n po ju obinrin lọ ni ile iwe alakọbẹrẹ. Nigbati ile iwe girama ọlọdun mẹta akọkọ ma n fi 43,000 po ju awọn obinrin lọ. Nigbati 44,500 ọkunrin po ju obinrin lọ ni ile iwe girama ọlọdun mẹta alakọjade.

Ṣugbọn ipinlẹ Zamfara lo buruju nipa gbi gba awọn ọmọbinrin si ile-iwe. Ni gbogbo eto ile iwe ni iye awọn ọkunrin ti pọ ju awọn obinrin lọ ni ilọpo meji.

Iru eto ẹkọ ti awọn ọmọ yii n gba ni ile iwe naa ṣe pataki. Gẹgẹ bi akọsilẹ Ajọ Nigerian Education Data Survey (NEDS) ni ọdun 2015, 44% awọn akẹẹkọ to wa ni ile-iwe alakọbẹrẹ ti ijọba lo mọ iwee ka, nigbati 74% awọn akẹẹkọ to wa ni ile iwe aladani lo mọ iwe ka. Amọ, ni ile iwe ti ọlọdun mẹta akọkọ ni girama, awọn to mọ iwee ka ati kikọ jẹ 91% ati 96%.

Aarẹ Buhari ti seleri lati fi 15% owo isuna ọdun si eto ẹko, amọ akọsilẹ isejọba rẹ fihan wi pe o nilo lati se ju bẹẹ lọ lati le mu ileri naa ṣẹ.

Ni ọdun 2016, ijọba Buhari fi 8% owo isuna si eto ẹkọ ati ni ọdun 2017 ni o walẹ si 7.4%. Ni ọdun 2018, 7% ni wọn ya sọtọ lara owo isuna ọdun to jẹ bii 650bn naira ($1.8bn, £1.4bn).

Bi Aarẹ Buhari ba fẹ mu ileri rẹ sẹ, o gbọdọ fi kun owo isuna eto ẹkọ si bii 1.3tn naira, tabi ki o din owo isuna ẹka miiran ku.

Atiku Abubakar
Ijọba n lo iye owo to to 1tn naira ($2.8bn, £2.2bn) lati fi san owo osu awọn ọmọogun Naijiria nigbati wọn ko si lo to idaji rẹ lati san owo awọn osisẹ ni ẹka ẹkọ.
Agbeyẹwo Ọrọ

Ni ọdun 2018, ijọba apapọ fi owo to to 650bn naira si ẹka eto ẹko, ti ida meji lọna mẹta (407.8bn naira) si yẹ ko jẹ fun sisan owo oṣu awọn osisẹ.

Ẹwẹ, iye owo ti wọn fi n san owo osu yii fẹrẹ dọgba pẹlu owo isuna fun eto abo ati wi pe owo perete (12.2bn naira) ninu rẹ ni wọn fi n san owo oṣu awọn ọmọogun ilẹ naa.

Ni ọdun yii bakan naa ni ijọba pinnu lati na N418bn lapapọ, eleyii to fẹrẹ dọgba pẹlu owo oṣu fun awọn to wa ni ẹka eto ẹkọ.

12.2bn naira ni owo ti wọn la kalẹ fun sisan owo oṣu awọn ọmọogun orilẹede Naijiria.

Ti wọn ba pa a pọ mọ owo oṣu awọn ti iṣẹ wọn jọ mọ ti ọlọgun (164bn naira), apapọ owo naa ko tii to iye owo ti ijọba n lo fi san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ni ẹka eto ẹko, ti ko si to 1tn naira ti Atiku Abubakar sọ wi pe wọn n na.

Boya owo oṣu naa de ọdọ awọn oṣiṣẹ naa tun jẹ ọrọ miiran to yẹ lati gbe yẹwo.

Gẹgẹ bi agbeyẹwo Ajọ Sub-National Salary Survey ti wọn gbe jade ni Oṣu Kẹsan, 2018 lati ọwọ Ajọ to n tọ pipin bi ijọba se n na owo, BudgIT, ipinlẹ 12 ninu 35 ni ko i tii san owo oṣu awọn olukọ ti wọn jẹ.

Ibaraẹnisọrọ Tẹ ibi yii lati ṣe ibaraẹnisọrọ

Agbeyẹwo Ọrọ