Gbogbo ibeere
-
- 1. Ẹ fi ara yin han awọn araalu
- 2. Kilo de ti ẹ fi woo pe ẹyin ni o tọna ju lati di gomina ipinlẹ Eko?
- 3. Kini ẹ fẹ ṣe lori ọrọ sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ?
- 4. Ọpọ iṣẹ iwadii sọ pe afẹfẹ ilu Eko ko ni anfani fun ara, kini ẹ fẹ fi yanju wahala idibajẹ afẹfẹ.
- 5. Kini ọna abayọ si ẹgbin ati idọti nipinlẹ Eko?
- 6. Ọpọ lo tun beere ibeere lori ọrọ owo ori. Wọn ni owo ori pọ awọn ko si mọ bi wọn ṣe n na. Kini ọna abayọ ti ẹyin ni si eyi?
- 7. Kini ohun to yatọ ti ẹ ni lọkan lati fi yanju ọrọ airiṣẹse awọn ọdọ nipinlẹ Eko?
- 8. Kini ohun kan pato ti ẹ ti ṣe si orisun yin ti ẹ fi ro pe o yẹ ki wọn dibo fun yin?
- 9. Wọn ni ẹ maa n pariwo pe ẹ o fi kun owo oṣu oṣiṣẹ, bawo lẹ ṣe fẹ ri owo ati pe bawo ni ẹ ko ṣe ni di toni bamubamu ni mo yo bi ẹ ba de ipo
- 10. Koko kan pataki to jẹyọ ninu ipolongo yin ni ibọwọ fun ofin l'Eko, kini igbesẹ ti ẹ la kalẹ fun ibọwọ fofin?
- 11. Ṣe lootọ ni pe ijọba ipinlẹ Eko n na ina apa?
- 12. Kini Ẹgbẹ yin ni ni ilera fun ọmọde, arugbo atawọn oṣiṣẹ
- 13. Kini ẹ fẹ ṣe lori eto abo ati ọrọ awọn smọ ẹgbẹ ọlọkọ ero nipinlẹ Eko
- 14. Kini eto yin lori idẹyẹsi awọn akanda ẹda ni ipinlẹ Eko?
- 15. Kini eto yin fun eto ilera alabọde?
- 16. Ọdunmelo lo maa gbayin lati ṣe awọn ileri yin atipe ti ẹ ko ba ṣee ṣe ẹ maa fi ipo silẹ? - Adefioye Iyunade
- 17. Kini ẹ fẹ gba ṣe eto ikọle ni ipinlẹ Eko - Ọtunba Tokunbọ Aderiokun babarinde
- 18. Kini ẹ fẹ fun awọn iyalọja? - Ọlasunkanmi Oyekanmi
- 19. Ọrọ ikadii yin.
Lagos BBC Gubernatorial Debate
Ti wọn ṣe ni: Ọjọ kẹẹtala oṣu kinni, ọdun 2019.
Ipade itagbangba BBC News Yoruba to ṣẹlẹ ni ilu Eko ti pari. Eleyii diẹ ninu awọn ibeere ti wọn bi awọn oludije naa lere ati bi wọn ṣe dahun awọn ibere naa.
Choose a topic:
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCOLUMUYIWA FAFOWORA Ni orukọ mi. Emi ni oludije ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu ADC ni ipinlẹ Eko. Nigba ti wọn bi mi ilu Eko dara. Mo lọ sileewe mo si lọ si oke okun lati ṣiṣẹ. Oṣelu mi wa lati wa sin araalu. Eko ni wọn bi wa si ni awa fi mọ. Ijọba kii ṣe ki eeyan maa ṣe alayeluwa lai mọ ibi ti bata ti n ta araalu lẹsẹ.
-
OMOLARA ADESANYAPPCOMOLARA ADESANYA ni orukọ mi. Emi ni oludije ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu PPC ni ipinlẹ Eko. Mo ṣiṣẹ ọdun marundinlogoji ni banki apapọ orilẹede Naijiria ki n to fẹyinti ni ọdun 2017. Ohun to mu mi wọ oṣelu ni pe oriṣiriṣi nnkan lo mẹhẹ, eto ẹkọ, ilera, ati bẹẹbẹẹ ni mo fi pinnu lati wa ṣe awọn ohun to yẹ.
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPBABATUNDE GBADAMOSI ni orukọ mi. Emi ni oludije ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu ADP ni ipinlẹ Eko. Ọmọ bibi ilu Ikorodu ni mi. Mo kawe ni orilẹede Naijiria, ki n to gba oke okun lọ lati ṣiṣẹ. Lẹyin eyi ni mo dari wa sile lati da ileeṣẹ silẹ. Iṣoro pọ faraalu nipinlẹ Eko, ko siṣẹ, omi, ọna, ileewe, ilera, bẹẹni karakata mẹhẹ lo jẹ ki n darapọ mi idije.
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPADEBISI OGUNSANYA ni orukọ mi. Emi ni oludije ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu YPP ni ipinlẹ Eko. Ọmọ ilu Ikorodu ni mo jẹ. A bi mi si inu oṣelu ni. Mo ṣiṣẹ fun ọpọ ọdun ni ẹka ifowopamọ si Ọrọ ilu Eko jẹ ohun to jẹ mi logun pupọ ni mo fi ti ori bọ inu oṣelu yii.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCNinu ẹgbẹ oṣelu a mọ awọn kan ti wọn jẹ oṣelu ẹsẹ kuku. Awa jẹ ọmọ Eko a si mọ ibi ti ọrọ ti n dun araalu. Ijọba kii ṣe ki eeyan maa ṣe alayeluwa lai mọ ibi ti bata ti n ta araalu lẹsẹ.
-
OMOLARA ADESANYAPPCMo ni ohun ti wọn n pe ni igboya. Bi ọrọ ba ti ri ni mo si maa n sọ. Gbogbo owo to wa ni a o si na bo ti tọ. Iya n jẹ awọn eeyan ipinlẹ Eko. Mo ti ri ọpọ obinrin labẹ afara kaakiri, mo si ti lọ si ọpọ ileewosan ṣugbọn ko si awsn ohun elo to yẹ nibẹ. Eyi gan lo faa ti mo fi beere pe ki lo de ti iya fi n jẹ awọn eeyan ipinlẹ Eko bayii?
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPA da ipinlẹ Eko silẹ fun araalu ati idagbasoke araalu. Awọn ijọba to pilẹ ipinlẹ yii bii Mọbọlaji Johnson ati Jakande ṣe ohun ti o ts fun igbayegbadun araalu. Ijọba mi yoo wa ọna ti a maa fi ṣe ohun gbogbo to ba yẹ ni ipinlẹ eko. Eto fun ina manamana ni, ilegbigbe ni, ile ẹkọ, omi, ọna, gbogbo rẹ ni mo ti ṣe. Eyi gan lo fun mi ni idaniloju pe ninu gbogbo awọn to jade fun ipo gomina ipinlẹ Eko, emi ni ẹni naa ti wọn n sọ lọwọlọwọ
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPAye ti awọn ọdọ wa ko tẹ mi lọrun. ọpọ ọdọ lo lọ sileewe ti ko ri iṣẹ. Ni igba kan awọn obi maa n wo pe bi awsn ba ti ran ọmọ lọ si ileewe iya awọn ti tan ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ bayii. Ijọba gan ko bojuto awọn ọmọ wọnyii, wọn ko kọ wọn niṣẹ, wọn ko gbawọn nimọran, awọn ọdọbinrin ti bimọ laito ọjọ, awọn ọdọkunrin ti n di adaluru. Idi niyi ti mo fi jade fun ipo gomina ipinlẹ Eko.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCNi ọdun 1983, alhaji Jakande ṣe iwadi kan eyi ti wọn fi ni a gbọdọ lọ ọkọ oju irin igbalode metro line. Ilu to ni ọpọ ero miliọnu mejilelogun gbọdọ ni eto irina yii o. Ikẹfa ninu eto meje ti ileeṣẹ wa gbe kalẹ ni ọkọ oju irin metro line. Bakan naa ni a fẹ mu iriri ilu New York wọle ni ti oju ọna ati irinna oju popo.
-
OMOLARA ADESANYAPPCA maa sun akoko awọn ọlọpaa loju popo kuro ni agọ mẹrin irọlẹ si agogo mẹwa alẹ nitori a ṣakiyesi pe bi wọn ba ti kuro lẹnu iṣẹ ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ maa n bẹrẹ. A o ṣe awọn ọkọ oju omi ti yoo maa ko awọn ero kiri lati mu ki iṣoro yii walẹ
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPOhun ti a maa kọkọ ṣe ni lati gbe awọn ọkọ oju omi nlanla wa. A ko lee ra wọn ni tuntun. Lẹyin eyi a o pin ileeṣẹ iṣẹ ode lati rii pe wọn wa kaakiri awọn ijọba ibilẹ nipinlẹ eko lati bẹrẹ atunṣe awọn opopona
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPAra ohun ti o yẹ ni ṣiṣe ni lati rii pe awọn ọkọ ajagbe to ti gba oju ọna l'Eko ko si loju popo mọ. Ọpọlọpọ awọn nnkan ti a le fi ṣeto irinna bii oju omi ati oju irin ni mo maa gbe yẹwo.
-
-
 44/19Ọpọ iṣẹ iwadii sọ pe afẹfẹ ilu Eko ko ni anfani fun ara, kini ẹ fẹ fi yanju wahala idibajẹ afẹfẹ.
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCKo si bi wahala idibajẹ afẹfẹ ko ṣe ni waye nigba ti o ba jẹ pe aloku ọkọ ni o pọju lawujọ wa. Awọn bọọsi ti o n lo afẹfẹ gaasi ni a o mu wọle. A o mu ki awọn eeyan maa ra ọkọ tuntun ti o n lo gaasi
-
OMOLARA ADESANYAPPCỌpọ awọn ọkọ ti a n lo ni ipinlẹ Eko ni wọn ti ju ogun ọdun lọ ti eefin wọn si n da afẹfẹ laamu. Bakan naa lawọn afẹfẹ ti o n jade lati awọn ileeṣẹ. Gbogbo wọn ni a o sọ fun pe wọn gbọdọ wa nnkan ṣe si tabi ki wọn foju wina ofin
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPEefin to n da araalu eko laamu, ara ẹrọ amunawa ni wọn ti n wa. Bakan naa ni awọn ọkọ gbogbo. A o bẹrẹ eto ipese ina aladani eleyi ti yoo mu ki a pa awọn ẹrọ amunawa eleefin wọnyi ti. Mo tun maa gbe awọn ọkọ to n lo ina ẹlẹntiriki wọle lati taa fun awọn eeyan ni owo ti ko ga ju ara lọ. Awọn nnkan meji yii bi a ba ṣe e, wahala afẹfẹ yoo dinku
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPAiki n tete ko awọn ẹgbin naa kun ara ohun to n fa wahala ẹgbin. Lati rii pe wọn koo loorekoore, ati lati rii pe wọn gba awọn ọkọ eleefin.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCBi mo ba de ijọba, ajọ kolẹkodọti ipinlẹ Eko, LAWMA yoo pada, wọn yoo si gba aadọta ẹgbẹrun ọdọ siṣẹ. Bakan naa ni a o lo PSP atiawọn ohun elo ti wọn fi n jo ẹgbin laye ọjọun eyi ti yoo si lee di ohun amuṣagbara fun ipinlẹ Eko.
-
OMOLARA ADESANYAPPCA maa ko awọn eeyan wa nipa jijẹ ki ipinlẹ Eko o mọ tonitoni. A o si rii pe LAWMA pada lati maa ko idọti lasiko de asiko.
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPLabẹ ofin ọdun 1999, iṣẹ ijọba ibilẹ ni ẹgbin kiko, a o si daa pada fun wọn ṣugbọn ki a to daa pada si wọn,a o kọkọ kọ nipa eto sẹgbin-dọrọ lati lee mu owo jade ninu awọn ẹgbin ati idọti wọnyii
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPAbẹ ijọba ibilẹ ni eto ikodọti yoo wa n o si daa pada fun wọn nitori wọn ti gba ọpọ ojuṣe ijọba
-
-
 66/19Ọpọ lo tun beere ibeere lori ọrọ owo ori. Wọn ni owo ori pọ awọn ko si mọ bi wọn ṣe n na. Kini ọna abayọ ti ẹyin ni si eyi?
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCA ko ṣe itaniji to to lori owo ori. Bi a ba wọle a o ṣe asopọ awọn owo ori gbogbo ti a n gba. Ohun ti o ṣe ọpọ ni pe ẹru n ba wọn pe bi wọn ba san an, nṣe lawọn to wa nipo n koo jẹ. Emi ko ni koo jẹ
-
OMOLARA ADESANYAPPCKo si nnkan ti ko dara nipa sisan owo ori. Mo maa ṣeto gbogbo to yẹ laarin owo ori sisan laarin mẹkunu ati owo ori. Bakan naa ni a o ṣe atunto eto owo ori sisan ati gbigba ni ipinlẹ Eko.
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPA kọkọ maa ko awọn owo ori sisan si oju kan naa nitori sisan owo ori kan lẹẹ meji gbọdọ duro. A o maa fun awọn oṣiṣẹ ni ilakalẹ owo ori ti wọn ba n san pẹlu. Bakan naa, ni a o maa da owo ori pada fun awọn to ba san ju iye ti o yẹ ni sisan.
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPAwọn oṣiṣẹ lo n san owo ori ju. Awọn olowo nla gan kii san owo ori gbogbo eleyi naa ni a o wa ojuutu si. Gbogbo owo ori ti awọn eeyan n san ni a maa gbe yẹwo. Koda a oo ṣe eto iwuri fun awọn to n san owo ori.
-
-
 7. Ibeereyii ni wọn fi ranṣẹ fun oludije YPP7/19Kini ohun to yatọ ti ẹ ni lọkan lati fi yanju ọrọ airiṣẹse awọn ọdọ nipinlẹ Eko?
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPỌrọ airiṣẹ awọn ọdọ jẹ mi logun pupọ. A maa da awọn ibudo igbanisiṣẹ kalẹ kaakiri fun awsn ọdọ lati lọ maa forukọ silẹ. Bi aye iṣẹ ba ti yọ, a oo gba wọn sii. Gẹgẹ bii abiyamọ, ọrọ wọn jẹmi logun
-
-
 8. Ibeereyii ni wọn fi ranṣẹ fun oludije ADC8/19Kini ohun kan pato ti ẹ ti ṣe si orisun yin ti ẹ fi ro pe o yẹ ki wọn dibo fun yin?
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCNi ọdun 2004, mo ba minisita feto iṣẹ ode lati gba awọn ọdọ agbegbe wa si NEMA, wọn ṣee ṣugbọn nigba ti ijọba yi pada wọn da wọn silẹ
-
-
 9. Ibeereyii ni wọn fi ranṣẹ fun oludije ADP9/19Wọn ni ẹ maa n pariwo pe ẹ o fi kun owo oṣu oṣiṣẹ, bawo lẹ ṣe fẹ ri owo ati pe bawo ni ẹ ko ṣe ni di toni bamubamu ni mo yo bi ẹ ba de ipo
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPIṣọwọ nawo ijọba to wa lode bayii nipinlẹ Eko le pupọ. Lori irinna oju irin ti wọn bẹrẹ lati okoko lọ si CMS ti wọn pe ni $1.2 biliọnu. Ninu iwadii mi awọn kọngila ti wọn gbe iṣẹ naa fun ṣalaye fun oja idokoowo orilẹede wọn pe milisnu mejilelọgọsan ni awọn gba fun apapọ iṣẹ naa ati omiran ti wọn wa. Iru awọn ina apa bayii ni a maa ti ri owo fun ẹkunwo oṣu oṣiṣẹ.
-
-
 10. Ibeereyii ni wọn fi ranṣẹ fun oludije PPC10/19Koko kan pataki to jẹyọ ninu ipolongo yin ni ibọwọ fun ofin l'Eko, kini igbesẹ ti ẹ la kalẹ fun ibọwọ fofin?
-
OMOLARA ADESANYAPPCKo le si iyatọ laaarin olowo ati mẹkunu niwaju ofin. Gbogbo ẹni to ba lu ofin ni yoo foju wina ofin. Idasilẹ awọn eto ati ilana fun ibọwọ fofin yoo wa nikalẹ.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCEmi ko faramọ o. Owo ti wọn darukọ yẹn pọ gan ni. Owo ti wọn ya loruks gbogbo wa ati iran awsn ọmọ gan to n bọ. Ọrọ wọn kọja oninakuna, a maa wa orukọ miran fun wọn ni.
-
OMOLARA ADESANYAPPCOotọ ni,. N92biliọnu ni wọn ni awọn na lori awọn ileewosan alabọde wa ṣugbọn nigba ti mo lọ kaakiri mo rii pe ko si ohun kan nibẹ
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPO ṣe koko ki gbogbo awa eeyan ipinlẹ Eko nna. Ẹtọ wa ni lati mọ iye ti wọn nna. Ko si owo kan to yẹ ko jẹ aṣiri ijọba.
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPOtitọ ni. Nnkan ko rọgbọ pẹlu inawo ati iṣuna ipinlẹ Eko. Bi wọn ṣe n nawo ko ni ilana eyi si n kọ mi lominu.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCIlu Eko lowo gan awọn ẹgbọn wa kan ni ika ninu ni. Ipinlẹ Eko ko na ida ọgbọn iṣuna rẹ sẹka ilera. Ijọba mi yoo rii pe eto adojutofo ilera yoo wa fun awọn
-
OMOLARA ADESANYAPPCAwọn ileewosan alabọde gbogbo ni a o rii pe wọn nio ogun to to. Bakan naa ni a o rii pe awọn oṣiṣẹ olutọju alaisan naa yoo gba idanilẹkọ tuntun.
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPA fẹ ṣeto ilera ọfẹ nitori kiiṣe ọpọ lo ni owo eto adojutofo ilera, Health Insurance. O ti waye ri lasiko baba Jakande a o si ṣe e lẹkan si. A maa mu
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPA maa yẹ owo oṣu awọn oṣiṣẹ ẹka eto ilera wo fun afikun. Bakan naa ni a o pese awọn ohun elo to yẹ fun awọn ileewosan to yẹ.
-
-
 1313/19Kini ẹ fẹ ṣe lori eto abo ati ọrọ awọn smọ ẹgbẹ ọlọkọ ero nipinlẹ Eko
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCBi ẹ fun janduku niṣẹ, janduku naa ni yoo ṣi maa jẹ. Aikii ran awọn janduku lẹwọn mọ lo n fun wọn laaye ati maa da ilu ru. Iwa ipa lo fẹ ba ilu Eko jẹ, gbogbo awọn to n hu iwa janduku la o ran lọ sẹwọn. Awọn awakọ ko ni ẹni ti o lee bawọn sọrọ mọ ni o n waye.
-
OMOLARA ADESANYAPPCA o da awọn ileeṣẹ kerejekereje silẹ fun awọn ọdọ lati kọ iṣẹ ọwọ. Awọn ti awakọ naa, a o fi wọn si ẹgbẹ pẹlu olori kan. Olori naa ni yoo maa mojuto wọn. A o si rii daju pe ipo tawọn ọkọ wọn wa jẹ eyi to dara. Baka naa ni a o da awọn ibudo idaleeṣẹsilẹ kalẹ.
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPAkọkọ ninu ohun to fa eto abo to mẹhẹ ni ainiṣẹ. Ohun ti a maa kọkọ ṣe ni fifi owo kun owo oṣiṣẹ. Awsn oṣiṣẹ eto ilera, eto ẹkọ, eto pajawiri ati eto abo. Bi a ba ṣe n nawo lori wọn naa ni a o maa nawo lori ipese ohun amayedẹrun. Lori awọn onimọto. Oloṣelu lo da ọpọ wahala ọlọkọ silẹ, oloṣelu lo si lee tunto. A o tun awọn ibudokọ kọ ni ọna ti igbalode. A o rii pe gbigba owo ẹgbẹ wọn gan ba ọna igbalode lọ
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPAisi iṣẹ fawọn ọdọ ni ko jẹ ki jagidijagan o dinku nilu. Eto ẹkọ ti yoo mu kawọn ọdọ o ronu ni a o gbe kalẹ. Ọrọ to gba eto lọrọ awọn onimọtọ. A o pewọn si ajọ to nironu lati jẹ ki wọn mọ ohun ti a fẹ.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCA o fun awọn akanda ni owooya lati fi gbe iṣẹ ti wọn ba kọ larugẹ.
-
OMOLARA ADESANYAPPCNinu ijiroro mi pẹlu awọn akanda kan, eto ẹkọṣẹ ọwọ, wa ti a o ṣe. Bakan naa ni a o fun awsn ileeṣẹ laṣẹ lati gba awọn akanda naa siṣẹ
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPA o seto gbogbo fun irọrun awọn akanda lawujọ. Gbogbo awọn ohun elo ikẹkọ wa ni a o rii pe o wa fun irọrun awọn akanda ẹda.
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPỌpọlọpọ inawo ni yoo wa lati ọdọ ijsba mi fun itọju awsn akanda ẹda nipa eleyii awọn ẹbun ti Ọlọrun fun wọn yoo jẹyọ.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCIleewosan alabọde ks ni a nilo bayii bi kii ṣe eto adojutofo ilera, Health insurance
-
-
 1616/19Ọdunmelo lo maa gbayin lati ṣe awọn ileri yin atipe ti ẹ ko ba ṣee ṣe ẹ maa fi ipo silẹ? - Adefioye Iyunade
-
OMOLARA ADESANYAPPCGbogbo nnkan ti mo ṣeleri ni maa ṣe. Bi mo ba kuna klati ṣe e ko si idi fun mi lati pada wa.
-
-
 1717/19Kini ẹ fẹ gba ṣe eto ikọle ni ipinlẹ Eko - Ọtunba Tokunbọ Aderiokun babarinde
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPIle olowo pọọku ẹlẹgbẹrun lọna ogoji ni a fẹ kọ si ipinlẹ Eko. O yewa pe ko lee ka ipinlẹ Eko idi niyi ti a o fi ṣee kaakiri ipinlẹ Eko ki o lee ya awọn aladani lara lati wa kọ ile olowo pọọku
-
-
 
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPỌpọ ọja ti wọn tun kọ ti wọn wa gbe owo rẹ soke lo fa bi awọn ọlọja ṣe n taja loju popo. A o wa atunṣe si eleyii.
-
-
 
-
OLUMUYIWA FAFOWORAADCẸyin ọmọ ipinlẹ Eko ibo lode yii. Bi ẹ ba dibo daadaa ipinlẹ Eko a dara.
-
OMOLARA ADESANYAPPCBi ẹ ba dibo fun mi lati jẹ gomina Eko, gbogbo awọn nnkan ti a maa ṣe ni a maa ṣe.
-
BABATUNDE GBADAMOSIADPẸni ti ko di ibo, wọn a dibo fun un.too ba ṣe ojuuṣe rẹ wibo ti o n bọ yii, ibo ominira ni, ibo to n bọ yii ibo pataki ni, ibo ọjọ ọla ni, ibo ọjọ oni ni. Mo rọ gbogbo ẹyin ọmọ ipinlẹ Eko pe ọjọ ibo gomina, Ẹ jade.
-
ADEBISI OGUNSANYAYPPGbogbo nnkan to wa ninu iwe ileri wa ni a maa mu ṣe. Alumọni wa l'Eko, owo dẹ wa l'Eko, ọrọ wa l'Ekoibi ti wọn n naa si ni a ko mọ. Maa dẹ rọyin pe ki ẹ jade lati dibo.
-