Eyi ni abala kẹta iwadii BBC ti wọn ṣe lati ma ṣe itọpinpin awọn oludije ipo Aarẹ Naijiria
Awọn oludibo yoo yan aayo wọn laarin awọn oludije pẹlu nnkan ti wọn ba sọ fun wọn.
Iwaadi ti a gbe kalẹ yi wa lati dari ibeere kuro nibi iroyin idibo si koko ohun ti awọn oludibo fẹ ṣe fun awọn ara ilu.
Bawo ni wọn ti ṣe fẹ mọ boya ootọ ni nnkan ti awọn oludije ba sọ?
Ẹ jẹ ki a sagbeyẹwo rẹ
Oṣi si n ba awọn eeyan pupọ finra lorileede Naijiria ti o si jọ wi pe Atiku Abubakar n ṣọ wi pe nnkan ko yi pada laarin ọdun mẹrin ti ijọba yi ti wa lori oye ati wi pe o jọ pe nnkan n buru si ni.
Iroyin to wa ni lẹ n ṣe afihan wi pe ọrọ yi le jẹ ootọ.
Bi a ba gbe gbogbo eto ọrọ aje Naijiria le osuwọn iye owo to n wọle s'apo ilu (GDP), o ti n bọ lọwọ ifasẹyin lati igba ti iye owo epo rọbi ti walẹ ni ọdun 2016 .
Laarin 2014 si 2017 owo igbe aye to kere julọ fun eeyan kan walẹ lati US$3,222 si US$1,968 gẹgẹ bi nnkan ti ile ifọwopamọsi agbaye,World Bank, ṣe agbelewọn rẹ.
Ẹwẹ,iyapa to wa laarin awọn alaini ati awọn ọlọrọ n pọ si gaan ni.
Aliko Dangote ni o jẹ ẹni to lowo julọ lafrika gẹgẹ bi ohun ti iwe iroyin atigbadegba Forbes sọ.Forbes foju sun pe owo rẹ to $10.5 billion.
O fẹ to idaji eeyan Naijiria ti wọn ko ri ju naira 133.5 lowo ina lojumọ kan.Lọdun mẹrin sẹyin,miliọnu 85 awọn eeyan Naijiria ni wọn ka kun awọn ti osi n ba finra ti iye yi si ti n lọ soke si lọdọọdun.Ni ọdun 2016,awọn ti o jẹ mẹkunu jẹ miliọnu 90 ati miliọnu 94 lọdun 2017.Lọdun to kọja banki agbaye World Bank foju sun pe eeyan miliọnu 97 niwọnjẹ mẹkunu ni Naijiria.
Oṣi n peleke si ni Naijiria ti wọn si lero wi pe eeyan mẹfa ni osi n ta lojumọ ti iye yi si jẹ miliọnu 3.2 lọdọọdun.Banki agbaye n foju sun pe iyen eeyan ti yoo jẹ mẹkunu lọdun 2030 yoo jẹ miliọnu120.
Ọrọ naa buru jayi ni ariwa Naijiria ju Guusu Naijiria .Laarin ọdun 2004 si 2013 iye eeyan to wa nipo otoṣi dinku pẹlu iye to fẹ to miliọnu mẹfa tiiye awọn ti oṣi ta ni ariwa si lẹkun pẹlu miliọnu meje.
Ni iwọ oorun ariwa ati ila oorun ariwa,iye eeyan ti osi n ba ja ko dinku ti o si yi duro ni ida 47.6% ati 59% lawọn agbegbe wọn yi.
Boko Haram ti ṣe akoba fun awọn eeyan ariwa orileede Naijiria ti aini idagbasoke ọrọ aje naa lati owo ijọba naa si kun.
Aarẹ Buhari ko sọ ootọ nipa ọrọ yi.
Lootọ ni pe ijọba apapọ ṣe agbekalẹ ilana lati na owo si ẹka agbẹ ninu ilana idagbasoke ti wọn pe ni Economic Recovery and Growth Plan 2017-2020.
Wọn gbe ilana yi kalẹ lati jẹ ki Naijiria maa gbin gbogbo irẹsi ti wọn yoo ma lo lọdun 2018 ati alikama baknanna lọdun 2020.Amọ ṣ,wọn ko ri ileri yi muṣẹ fun gbingbin irẹsi lopin ọdun to kọja ko si daju wi pe wọn yoo ri afojusun yi ba fun alikama.
Bo ti lẹ jẹwi pe ọgbin iresi ti n pọsi laarin ọdun maarun sẹyin,ti wọn si ni ireti pe yoo lekun si ni ọdun 2019,Naijiria ṣi wa lara awọn orileede to n ra irẹsi lati ilẹ okere julọ lagbaye.
Ni ọdun 2014,iye tọọnuiẹsi kan jẹ bi owo dọla 425.Ni igba naa,Naijiria n gbe irẹsi to to tọọnu miliọnu 2,600,000 wole ti ye owo rẹ si jẹ $3,027,400.Eyi jasi miliọnu mẹta dọla lojumọ yatọ si owo ori ti wọn gbe le.
Ni ọdun 2018,iye owo tọọnu irẹsi ko yato to bẹ.Iye ti wọn n ta tọọnu kan si wa ni dọla 421.Toun ti bi iye tọọnu ti wọn gbe wole ti ṣe walẹ si 2,400,000 lọdun 2018, Naijiria yoo ṣi ma na $2,766,027.40 lojumọ kan lati gbe irẹsi wọle.
Iye irẹsi tara ilu n jẹ n ga si ni bi iye ara ilu ti ṣe n pọsi.Awọn ọmọ Naijiria ko fi ọrọ jọllof ṣere rara.
Ipenija ounjẹ ṣi n ba Naijiria finra toun ti aawọ to n waye lagbegbe ariwa ati arin gbungbun Naijiria eleyi to mu adinku ba iye ounje ti ara ilu n ri fun jijẹ ati tita.
Gẹgẹ bi ohun ti ajọ to n risi ọrọ ẹ bilagbaye Global Hunger Index gbe jade Naijiria jẹ orileede kẹtalelọgọrun laarin orileede mọ́kàndínlọ́gọ́fà ti wọn koju ipenija ebi eleyi to jẹ ipenija nla fun wọn.
Ni oṣu kẹta ọdun 2018,Aarẹ Buhari ṣe ifilọlẹ igbimọ to n ri si ipese ounje eleyi ti o jẹ wi pe oun gaan fun ara rẹ lo n dari igbimọ naa lati koju ipenija ounje ni Naijiria.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ,gbese ti Naijiria jẹ lọwọlọwọ ti lo soke si lati N7.55tn ($24.66b) ni 2012 si N22.43tn ($73.21b) ni 2018, eyi to tunmọ si alekun ida 196.9%
Lati le san gbese yi,ọmọ Naijiria kọọkan yo ni lati san owo Naira N118,046.33 nto ṣe deede dọla $385.33.
Lọdun 2017,iye owo to n wọ akoto Naijiria jẹ N2.71tn ($8.89b) ti N1.62tn ($5.3b) si wa fun gbese sisan eleyi to tunmọ si ida 59.68%.
Eleyi ko tunmọ si pe ohun ti Moghalu sọ jẹ ootọ nitori ọna orisirisi ni wọn fi n san gbese..Ko si na ti a fi le mọ boya owo N1.62tn ($5.3b) ti wọn ya sọtọ fun gbese sisan wa lati inu apapọ owo to wọ akoto Naijiria.
Gbese si iye ti o ọrọ aje orilẹede kan n gbe wọle,iyẹn GDP ni wọn fi ṣe odinwọn bi orilẹede kan ṣe lee fi irọrun san gbese to ba jẹ nipa ṣiṣe afiwe gbese ti orilẹede jẹ si ohun ti ọrọ aje rẹ n gbe jade. Bi gbese ba kere si odiwọn GDP rẹ, o tumọ si pe eto ọrọ aje orilẹede bẹẹ ni agbara lati san gbese rẹ. Bi gbese rẹ ba pọ pupọ ju odinwọn agbara ọrọ aje rẹ, iyẹn GDP, o tumọ si pe orilẹede bẹẹ yoo nira fun un lati san gbese rẹ.
Ni ọdun 2018, odinwọn agbara eto ọrọ aje Naijiria si gbese to jẹ jẹ ida mọkandinlogun o le diẹ, 19.72%, eleyi to jẹ ilọsiwaju lati ida mejila o le diẹ ninu ọgọrun, 12.65% ni ọdun 2013.
Gbese kan wa ti orilẹede n jẹ awọn orilẹede miran pẹlu ileeṣẹ ati lajọlajọ okeere. Ida mọkandinlọgbọn o le diẹ ninu ọgọrun, 29.49% gbogbo gbese ti orilẹede Naijiria jẹ si okeere; banki agbaye si ni orilẹede Naijiria jẹ ni gbese julọ lokeere.
Ni ọdun 2017,ẹka ilera,igbayegbadun ara ilu,iṣẹ agbẹ,eto irina ni awọn ẹka ti wọn fi owo iya lati ita ṣe eto wọn.
Ninu aba isuna ọdun 2019,nnkan bi ida 25.65% ni wọn ya sọtọ fun sisan gbese.
Ni ọdun 2012, ile iṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ile gbee ṣalaye pe miliọnu mẹtadinlogun eeyan ni ko rile gbe. Ijọba woye pe ko too di ọdun 2014, awọn ti ko rile gbe yoo too miliọnu ọgbọn eeyan si ogoji
Ṣugbọn ajọ banki agbaye sọ pe afojusun ọdun 2012 lori ile gbigbe ku diẹ kaato nitori eeyan mẹfa lo yẹ ko wa nile kan, eleyi to ju eeyan mẹrin lọ fun ile kan. Ṣugbọn banki agbaye ni awọn ti ko rile gbe to ọgbọn miliọnu idile
Lati ọdun 2012, o ṣoro lati mọ iye ile gbigbe ti awọn ọmọ Naijiria nilo
Miliọnu mẹtadinlogun ile ti wọn maa n wi ko tọna nitori ko sọ nipa bi awọn eeyan ṣe n pọ si ati aikọle ijọba fawọn eeyan
O nira lati mọ iye awọn ti ko rile gbe nitori ko tii si eto ikaniyan lati ọdun 2006 ati pe awọn ikọlu ati rogbodiyan to n ṣẹlẹ ti sọ ọpọ di alainile lori
Ṣugbọn lọdun 2017, ajọ to n ri si iṣẹ ijọba ni eeyan meji din ni aadọfa miliọnu eeyan ni ko nile lori
Ti a ba wo pe eeyan marun un sile kan, aadọfa miliọnu eeyan ti ko nile lori, ile ti yoo to lati gbe jẹ miliọnu mẹrindinlọgbọn
Mili ọnu $3.6m ti Sowore bere fun le to lati pese ile ọta le lọọdunrun
Awọn to n ṣiṣẹ agbẹ lo pọju ninu awọn oṣiṣẹ ni Naijiria. Ida mejidinlaadọta awọn oṣiṣẹ lo n ṣiṣẹ agbẹ ti ọpọlọpọ wọn si mu iṣẹ ọgbin ni baada
Ida mẹrinla ninu ọgọrun iye awọn eeyan to wa lorilẹede Naijiria ni ẹka eto karakata, ti o jẹ ẹka keji to gba eeyan si iṣẹ julọ gba siṣẹ ti awọn ẹka miran si gba ida meje o le diẹ ninu ọgọrun siṣẹ, ti ẹka idannkanṣe, Manufacturing, si gba ida meje ninu ọgọrun awọn eeyan orilẹede Naijiria siṣẹ.
Otitọ ni Fẹla Durotoye sọ nigba ti o wi pe ẹka eto ọgbin lo gba eeyan siṣẹ julọ, ṣugbọn iye ida ti o ko ninu ọgọrun kere ju iye ti o darukọ lọ.
Ọrọ Ọgbẹni Durotoye ko jina si ootọ nigba ti o wi pe ida marundinlogoji ilẹ to ṣee ṣe eto ọgbin ni a n lo bayii.
Iwọnba ida mẹtadinlogoji ninu ọgọrun ilẹ to ṣee lo fun ọgbin (miliọnu mẹrinlelọgbọn saare ilẹ) ni a n lo fun eto ọgbin gẹgẹ bi iroyin kan ti banki agbaye fi sita ni ọdun 2016. Iyats ti de ba eyi lati ọdun 2011.
Banki agbaye ṣe iṣiro rẹ pe ida mẹtadinlọgọrin o le diẹ ninu ọgọrun gbogbo ilẹ to wa lorilẹede Naijiria ni o ṣee fi ṣe eto ọgbin
A gbiyanju lati gbe awọn ohun to n lọ lagbo oṣelu kalẹ lai ṣegbe, lori awọn ohun to wa lojutaye jade.
Awọn ohun to ṣe pataki si awọn igberiko ni a gbaju mọ, gẹgẹ bii awọn ẹgbẹ oṣelu ṣe ṣalaye rẹ.