Gbogbo ibeere
-
- 1. Ẹ fi ara yin han awọn araalu
- 2. Eto ẹkọ ati ọrọ LAUTECH
- 3. Ọrọ eto ilera fun awọn ara Ọyọ
- 4. Eto aabo fun awọn ara ilu
- 5. Ibeere fun Ọmọbolanle Sarumi, NIP pe se o lero pe ipinlẹ Ọyọ ṣetan dibo yan obinrin si ipo gomina nipinlẹ Ọyọ?
- 6. Akanda ẹda kan beere eto awọn oludije fun awọn akanda
- 7. Kilode ti awon gomina n je owo osu osise?
- 8. Lori ọrọ ileesẹ iroyin ti ipinlẹ Ọyọ, BCOS
- 9. Ọrọ ikẹyin awọn oludije
Ọyọ BBC Gubernatorial Debate
Ti wọn ṣe ni: Ọjọ Kini, Oṣu Keji, ọdun 2019.
Ipade itagbangba BBC News Yoruba to ṣẹlẹ ni ilu Ibadan ti pari. Eleyii ni diẹ ninu awọn ibeere ti wọn bi awọn oludije naa lere ati bi wọn ṣe dahun awọn ibere naa.
Choose a topic:
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPADEBAYO ALAO AKALA ni orukọ mi. Emi ni oludije ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu ADP ni ipinlẹ Oyo. Ọmọ bibi ilu Ogbomọsọ ni mi. Mo kawe ni ilu Ogbomoso ati ni oke okun.Mo sisẹ fẹhinti gẹgẹ bi ọlọpa, Mo se oselu gẹgẹ bi Alaga ibilẹ Ogbomọsọ,Igbakeji gomina ati gomina. Awọn iriri pẹlu anfaani ti mo ni lo jẹ ki n sọ wi pe mo fẹ se e lẹẹkan si.
-
Adebayo AdelabuAPCADEBAYO ADELABU Ni orukọ mi. Emi ni oludije si ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Oyo. Ọmọ bibi agbegbe Kudẹti ní ìlú Ibadan ni mi.Mo lọ sileewe, mo si sisẹ gẹgẹbi igbakeji Gomina Ile Ifowopamọsi Banki Gbogbo Orileede Naijiria(CBN). Mo gbe igbesẹ lati dije dupo gomina nitori mo kawe de ibi ti wọn n kawe de,mo ni iriri, bẹẹsi ni mọ ni ifẹ ilu lo jẹ ki n dije dupo gomina.
-
Olufemi LanlẹhinADCOLUFEMI LANLEHIN Ni orukọ mi. Emi ni oludije ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu ADC ni ipinlẹ Oyo. Wọ́n bí mi sí idílé Lanlẹhin ti ìlú Ibadan - Amofin àti olóṣèlú níí mi, mo si jẹ Sẹ́nétọ̀ ilé aṣòfin àgbà keèje ati akẹ́kọ̀ọ́gboyè nínú òfin ni mo jẹ. Mo n dije dupo nitori ilosiwaju ipinlẹ Ọyo ni mo fẹ.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPỌMOBOLANLE SARUMI ni orukọ mi. Emi ni oludije si ipo gomina fun ẹgbẹ oṣelu NIP ni ipinlẹ Oyo. Ọmọ bibi ilu Ibadan ni wọn bi mi si.Mo lọ sileewe, mo si lọ si oke okun lati ṣiṣẹ. Abiyamo ni m, mo si fẹ di gomina ki awọn ọmọ wa le lọ si ile iwe kiakia, ma a si fi iyatọ obinrin si okunrin han nipa eto isuna ipinlẹ Ọyo.
-
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPAkala ni oun yoo seto ẹkọ ọfẹ to munadoko fun awọn ileewe aladani ati ti ijọba
-
Adebayo AdelabuAPCNi gbogbo orilẹede Naijiria,ipinlẹ Ọyo lo ni aabọ fasiti. Ti mo ba de ipo isejọba, N o gba fasiti Lautech pada fun ipinlẹ Oyo.
-
Olufemi LanlẹhinADCMa a wa iyanju ṣi ọrọ eni to ni fasiti Lautech. Ijiroro yoo waye,ki Ọyo le jogun ile iwe giga Lautech. Wọn yoo si san ẹtọ to ba yẹ fun ipinlẹ Osun. Bakan naa ni eto ẹkọ ọfẹ yoo wa fawon ileewe alakọbẹrẹ ati girama.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPN o gba Lautech pada fun ipinlẹ Oyo, ma a si tun kọ fasiti tuntun. Wahala to n de ba eto ẹkọ naa ni gbigba awọn olukọ oloṣelu si ibi isẹ, nitori awon oloselu lo gba wọn lai je pe won kun oju iwọn.
-
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPSaa isejọba akọkọ mi da awọn eto ilera alabode ẹsẹ kuku silẹ.Ati pe n o ṣe agbekalẹ ilera ọfẹ fun awọn eniyan.
-
Adebayo AdelabuAPCIlera jẹ ara ohun mẹta ti a la kalẹ bii Iṣẹ agbe, eto ẹkọ ati ilera.Isejọba mi yoo mojuto ilera alabọde ati ile iwosan alabọde yoo wa ni gbogbo ijọba ibilẹ.
-
Olufemi LanlẹhinADCBi ipinlẹ Ọyọ ṣe tobi to, kun ara ohun to n fa ipenija eto ilera. Nitori naa iṣejọba mi yoo pese ile iwosan alabọde kaakiri wọọdu.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPGbogbo awon ọmọ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju marun un lọ yoo gba eto ilera ọfe. Bakan naa ni awon arugbo ti ọjọ ori wọn ko din ni ọdun marundinlaadọta yoo maa jẹ anfani eto ilera ọfẹ bi oun ba wọlé.
-
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPGẹgẹ bii Ọlọpaa to ti fẹyinti mo mọ ọna abayọ si ipenija ọrọ abo. Ma a ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati mu eto aabo gbopọn sii.
-
Adebayo AdelabuAPCOhun meji ni n yoo ṣe.Didena ati idojukọ ipenija abo.<br>Iṣẹ agbẹ, iṣẹ ọwọ ati ere idaraya fawon ọdọ yoo din wahala ipenija aabo ku.
-
Olufemi LanlẹhinADCEto aabo to n fa wahala ni ilu yoo gba amojuto nipa ipese iṣẹ. Ko si ẹni fẹ ṣe jagidijagan to ba ri iṣẹ ṣe.Ma a se eto idaṣẹsilẹ, eto ọgbin ati ileeṣẹ kereje fun igbaniisiṣẹ.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPAi si olori gidi ni kii mu ki ilu toro, ati wi pe ko lee si abo laisi iṣẹ. N o yọ ro awọn ọdọ lagbara.
-
-
 55/9Ibeere fun Ọmọbolanle Sarumi, NIP pe se o lero pe ipinlẹ Ọyọ ṣetan dibo yan obinrin si ipo gomina nipinlẹ Ọyọ?
-
Ọmọbolanle SarumiNIPAwọn obinrin ti ṣetan fun ipo yii ati emi pẹlu ti ṣetan. Mi o ni ile rẹpẹtẹ, ṣugbọn mo ti ṣọ eeyan rẹpẹtẹ di nla.
-
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPLasiko ti oun se gomina lakọkọ,mo yan akanda ẹda kan si ipo amugbalẹgbẹ oun. Ati pe oun yoo tu ileewe awọn akanda ẹda ṣe.
-
Adebayo AdelabuAPCEmi yoo se atunse awọn ibudo ati ileewe akanda ẹda kaakiri ipinlẹ Oyo, ma a tun yan awọn akanda si ipo iṣejọba.
-
Olufemi LanlẹhinADCMa a se atunsẹ ileewe awọn akanda ẹda. Ma a si ya owo soọtọ fun eto ẹkọ ọfẹ fawon akanda.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPAwọn akanda ẹda ti n dojukọ idẹyẹsi ni awọn ile ifowopamọsi ati bẹẹ bẹẹ lọ, n o fopin si idẹyẹsi. Ati pe awon ileewe ti gbogbo ọmọ ba n lọ ni awọn akanda naa yoo maa lọ.
-
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPNigba ti mo wa ni ipo gomina, mi o jẹ awọn osisẹ ni owo. Ni bayii, Mo setan lati san 30,000 Naira gẹgẹ bi owo osu to kere julo.
-
Adebayo AdelabuAPCLati ọdun mẹrindinlọgbọn ti mo ti n sisẹ, wọn ko jẹmi ni owo osu ri. Nitorina ti mo ba de ipo, ma a ri wi pe awọn osisẹ n gba owo osu wọn loore koore.
-
Olufemi LanlẹhinADCAwọn isẹ ilu ti a ma a se, a jẹ eleyii ti o bu iyi kun omoluabi. Nitori idi eyi mi o ni jẹ awọn osisẹ lowo osu. A ko ni bẹrẹ isẹ ti ọwọ wa ko ka. Ma a san 30,000 Naira gẹgẹ bi owo osu osisẹ to kere julọ.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPKo ni si ọfiisi ọkọ gomina, nitori naa owo osu osisẹ yoo ma a wọle lasiko, pẹlu eto ilera ati ẹkọ ti yoo wa ni yoo jẹ ki owo osu naa le mọ wọn lọwọ.
-
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPGbogbo nkan ti mo ra sibẹ lasiko ti mo jẹ Gomina lọdun 2007 lo si wa nibẹ.Mo ma a da ohun gbogbo pada si ipo.
-
Adebayo AdelabuAPCA a mu idagbasoke ba ileesẹ iroyin naa. Ao sisẹ papọ pẹlu awọn ile isẹ iroyin to lamilaaka lagbaye lati le mu idagbasoke ba BCOS.
-
Olufemi LanlẹhinADCA ma a da BCOS pada si ipo kini to wa tẹlẹ. Pupọ ninu ile isẹ to wa ni ipinlẹ yọ ni ko lo deede bi o se yẹ ko lọ. A o ri wi pe awọn ti wọn gba sisẹ jẹ awọn to wa nipa eto iroyin.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPA ma a ri wi pe a fọwọsowọpọ pẹlu ileesẹ iroyin BBC lati ri wi pe awọn osisẹ BCOS gba idanilẹkọ to muna doko, ki ohun gbogbo le pada si ipo.
-
-
 
-
Adebayo Alao AkalaADPMo dupẹ fun awọn eeyan ti wọn jade wa. Ijọba tiwantiwa, ijoba araalu, ti yoo pa araalu lẹrin ni emi yoo se.
-
Adebayo AdelabuAPCMo dupe lọwọ BBC ati awọn to wa. Awọn ọdọ lo lee se e bayii.
-
Olufemi LanlẹhinADCMo ki awọn ara ipinlẹ Oyo. Mo ti se ijọba rii ni iwọnba ti mo le se. Ijọba tiwantiwa ni mo fẹ mu wa.Mi o wa owo lọ sinu iṣejọba, okun wa, agbara wa, ọpọlọ si tun wa.
-
Ọmọbolanle SarumiNIPEmi yoo rii daju pe gbogbo ọmọ to n gbe ni ipinlẹ Ọyọ ni wọn n gbe igbe aye to ni iyi ati ogo. Mo rọ awon ọdọ lati maṣe faye gba awọn oloṣelu ki wọn lo wọn fun iwa jagidijagan.
-