Tẹ aworan oludije ki o le mọ si nipa wọn ati ohun ti wọn fẹ ṣe
John Mahama
National Democratic Congress
John Dramani Mahama jẹ oloṣelu ilẹ Ghana, sọrọsọrọ, ati olukọtan ti wọn bi si idile oloṣelu lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 1958.
Ẹka ilera
Ipese eto ilera ọfẹ alabọde
Igbelarugẹ eto ilera ati igbayegbadun
Adinku iku awọn ọmọde ni rewe-rewe
Ipese paadi nkan oṣu fawọn akẹkọọbinrin
Ohun amayedẹrun
Ipese ohun amayedẹrun pẹlu $10bn ti orukọ rẹ n jẹ ''Big Push.''
Ọdun marun un ni ijọba yoo fi ṣe akanṣe iṣẹ naan
Kikọ ile ẹkọ fasiti ati ile iwosan sawọn agbegbe ti ko ni.
Kikọ 20,000 ile ẹdinwo fawọn eeyan ni 260 ilu nla atawọn ilu kereje laarin ọdun mẹrin.
Eto ẹkọ
Imugbooro eto ilera fawọn akẹkọọ girama ileewe adani lawọn agbegbe ti ko ni iru anfaani bẹẹ.
Wiwọgile sisanwo eto ẹkọ lọna meji
Pipari awọn yara ikẹkọọ ileewe girama ti wọn ti kọ pati lati pese aye fawọn akẹkọọ to fẹ wọle
Ipese ẹrọ Wi-Fi fawọn akẹkọọ lati le mọ ẹrọ ayelujara lo lawọn ileewe
Ọrọ aje
Agbekalẹ eto ọrọ aje onikoko mẹta papaa julọ lẹka ileeṣẹ to n ṣe nkan atawọn iṣẹ mii .
Ipese iṣẹ miliọnu kan lẹka iṣẹ aladani.
Ṣiṣe ọna lati igboro lọ si igberiko tori kiko ere oko lọ si ọja.
Nana Akufo-Ado
New Patriotic Party
Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 1944 ni wọn bi William Dankwa Akufo-Addo. Ilu Accra lo ti dagba. Edward Akudo-Addo den Adeline ni baba rẹ.Amofin ati oloṣelu ni Aarẹ Akufo-Addo.
Ẹka ilera
Kikọ ile iwosan 101 pẹlu ọgọrun un bẹẹdi/kikọ 100 ile iwosan igbalode.
Ilegbe fawọn dokita ati nọọsi lawọn ẹkun to ko ni ile iwosan.
Kikọ ile fun ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun ni Ghana
Kikọ ile iwosan arun ọpọlọ meji atawọn to wa tẹlẹ
Ohun amayedẹrun
Ṣiṣe eto ẹyawo ti ko gara fawọn eeyan, ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn olokowo aladani lati ṣeto ẹyawo fawọn ọmọ orilẹede Ghana.
Ipese ilegbe ẹdinwo fawọn eeyan laarin ọdun mẹrin
Pipari ojuurin reluwe Westeren Line ati Tema lọ si Mpakadan ati ojuurin ila oorun Aduadin si Obuasi to fi mọ ojuurin reluwee lati Ghana si Burkina Faso
Eto ẹkọ
Itẹsiwaju eto ilera ọfẹ pẹlu akanṣe eto TVET
Itẹsiwaju imugbooro ohun amayedẹrun lawọn ileewe giga ti ijọba lati le gba awọn akẹkọọ sii
Ipese ẹrọ Wi-Fi lawọn ile ẹkọ lati ṣeranwọ fawọn akẹkọọ lori imọ lilo ẹrọ kọmputa ipese Wif-Fi bakan naa fawọn akẹkọọ girama ti ileewe ijọba
Imugbooro ohun amayedẹrun lati mu jẹ ki ẹka eto ẹkọ mu tubọ pese awọ akẹkọọ nipa ofin
Ọrọ aje
Ju ọdun 2020 lọ, ijọba yoo tẹsiwaju lati ṣe afikun lori miliọnu meji iṣẹ ṣiṣe ti ijọba ati ti aladani
Idagbasoke ohun amayedẹrun nipa ajoṣepọ ijọba ati ileeṣẹ aladini nipa gbigba owo ibode
Idasilẹ eto igboke-gbodo ọkọ Metro kaakiri ilu nla nla ni Ghana