Olimpiki Tokyo 2020: Awọn elere idaraya ilẹ Afrika to yẹ ko wo

  • Taoufik Makhloufi, 33

    Algeria Asare

    Taoufik Makhloufi jẹ asare aarin (awọn ere 800m ati awọn mita mita 1,500).

    O bẹrẹ si ni kopa ni Olimpiki odun 2012 to waye nilu London ti o si gba goolu kan nibi idije ere 1,500m ati ami fadaka meji ni Olimpiiki Rio 2016.

  • Wali Bidani, 27

    Algeria Ere Idaraya

    Wali Bidani jẹ ọmọ Algeria to ma n gbe nkan to wuwo. O kopa ni Olympics fun igba akọkọ ni London 2012 Olympics, to si kopa fun igba keji ni Rio 2016 Olympics.

  • Azenaide Carlos, 31

    Angola Bọọlu afọwọgba

    Azenaide Carlos jẹ agbabọọlu ọlọwọ ati ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu ọlọwọ obinrin orilẹ-ede Angola ti ọpọ mọ si 'The Pearls'

    Idije Olympics mẹta lo ti kopa lati ọdun 2008.

  • Nijel Amos, 27

    Botswana Asare

    Ọmọ orilẹ-ede Botswana ni Nijel Amos, to jẹ elere sisa, to si ti ami ẹyẹ fadaka fun idije 880m ti awọn ọkunrin ni London 2012 Olympic Games.

    Tokyo 2020 ni yoo jẹ igba kẹta rẹ.

  • Hugues Fabrice, 28

    Burkina Faso O ma n fo nkan

    Ọmọ orilẹ-ede Burkina Faso ni Hugues Fabrice, o jẹ ọmọ ikọ Burkinabe, to si ma n fo nkan. O ti gba ami ẹy idẹ ni 2019 World Athletics Championships.

  • Francine Niyonsaba, 28

    Burundi Elere sisa

    Elere sisa ni Francine Niyonsaba lati orilẹ-ede Burundi. O gba ami ẹyẹ fadaka ni Rio 2016 ati 2017 World Championships ninu ere sisa 800m ti awọn obinrin.

  • Cheick Cisse, 27

    Côte D’Ivoire Taekwondo

    Cheick Cisse fi itan lelẹ nigba to gba ami ẹyẹ Goolu akọkọ fun Ivory Coast ni idije Rio 2016 Olympics.

    Oun si ni ọmọ ilẹ Afica akọkọ to gba ami ẹyẹ goolu ninu ere idaraya Taekwondo.

  • Marie-Josée Ta Lou, 32

    Côte D’Ivoire Asare

    Marie-Josée jẹ elere idaray nkan jiju lati orilẹ-ede Ivory Coast, to si ma n sa ere 100m ati 200m.

    O ti gba ami ẹyẹ idẹ ninu idije 100m ti awọn obinrin ni World Athletics Championships, o si tun ṣe ipo kẹrin ni Rio 2016 Olympics ninu idije 100m ati 200m.

  • Haydy Morsy, 22

    Egypt Ere idaraya Pentathlon

    Haydy Morsy jẹ elere idaraya Pentathlon igbalode, to ma n luwẹ, to si ma n gun ẹṣin.

    Idije Tokyo 2020 ni igba keji ti yoo kopa ni idije Olympics ni

  • Azmy Mehelba, 30

    Egypt Ibọn yinyin

    Azmy Mehelba jẹ ẹni to ma n yinbọn, lati Egypt. Idije Tokyo 2020 Olympics games si ni igba kẹta ti yoo kopa ni idije Olympics.

    O gba ami ẹyẹ goolu ni idije ISSF World Cup Shotgun to waye ni oṣu Karun-un, ọdun 2021.

  • Giana Farouk, 26

    Egypt Karate

    Giana Farouk wa lati Egypt, to si ma n kopa ni ere idaray Karate. Tokyo 2020 games ni idije Olympics akọkọ ti yoo ti kopa.

    Ọ gba ami ẹyẹ goolu ni idije World Karate Championships lọdun 2016, ati ami ẹyẹ idẹ lọdun 2018.

  • Merhawi Kudus, 27

    Eritrea Kẹẹkẹ gigun

    Merhawi Kudus, ẹni ọdun 27 jẹ ọmọ orilẹ-ede Eritrea, to ma n gun kẹẹkẹ. O ṣe ipo kẹta ni idje Turkey 2019 Cycling Tour.

    O bori ni idije Individual Time Trial ni 2021 Eritrean Championships. Tokyo 2020 ni idije Olympics akọkọ ti yoo lọ.

  • Amanuel Gebreigzabhier

    Eritrea Kẹẹkẹ gigun

    Amanuel Gebreigzabhier n kopa fun igba akọkọ ni idije Olympics lọdun yii. Oun lo ṣe ipo kinni ni idje 2018 African Road Championships.

  • Mosana Debesay, 27

    Eritrea Kẹẹkẹ gigun

    Mosana Debesay jẹ elere idaraya kẹẹkẹ gigun lati Eritrea. O bori ni idije 2019 African Road Championships, ati 2018 African Road Championships individual time trial.

    Tẹgbọn-taburo ni oun ati elere idaraya kẹẹkẹ gigun, Mekseb Debesay

  • Daniele Christian, 23

    Eritrea Liluwẹ

    Daniele Christian jẹ elere idaraya liluwẹ, lati orilẹ-ede Eritrea, to n lọ si idije Tokyo Olymnpics, yoo si kopa ni idije s200m medley.

  • Letesenbet Gidey, 23

    Ethiopia Maratọọni

    Letesenbet Gidey jẹ ọmọ orilẹ-ede Ethiopia to ma n sa maratọọni, o si ti gba ami ẹyẹ ni agbaye. Gidey ni orukọ rẹ wa ninu iwe akọsilẹ lagbaye fun bo ṣe bori ni idije 5000m ti awn obinrin, to si tun bori ni 10,000m laipẹ yi.

    O gba ami ẹyẹ fadaka ni idije awọn obirin fun 10,000m nibi idije 2019 World Athletics Championships.

  • Selemon Barega, 21

    Ethiopia Ere sisa ọna jijin

    Selemon Barega wa lati Ethiopia, p su ma n sa ere ọna jijin. O gba ami ẹyẹ fadaka ni idije awọn ọkunrin fun 5000m ni idije 2019 World Athletics Championships.

    Tokyo 2020 ni idije Olympics akọkọ ti yoo yi kopa.

  • Yomif Kejelcha, 23

    Ethiopia Ere sisa

    Yomif Kejelcha jẹ elere sisa lati Ethiopia, ti yoo kopa ni Olympics fun igba akọkọ ni Tokyo Games.

    Kejelcha ti gba ami ẹyẹ goolu ri ni idije 3000m ti awọn ọkunrin, ni 2018 World Indoor Championships.

    O tun gba ami ẹyẹ fadaka ni 10,000m ti awọn ọkunrin ni 2019 World Athletics Championships.

  • Lelisa Desisa, 31

    Ethiopia Elere sisa maratọọnu

    Lelisa Desisa wa lati Ethiopia, o jẹ elere sisa maratọọnu, o si ti gba ami ẹyẹ goolu ni 2019 World Athletics Championships.

  • Shura Kitata, 25

    Ethiopia Elere sisa maratọọnu

    Shura Kitata jẹ elere idaraya maratọọnu lati Ethiopia

    O gba ami ẹyẹ goolu ni 2020 London Marathon, o si tun lu ọmọ Kenya, Eliud Kipchoge to bori rẹ ni 2018.

  • Gudaf Tsegay, 24

    Ethiopia Elere sisa

    Gudaf Tsegay jẹ aṣare agbedemeji ara Ethopia to lamilaka ami-ẹyẹ awọn obinrin 1,500 mita ni agbaye ni ilu Liévin, France ni oṣu keji odun 2021.

    Arabinrin naa si tun gba idẹ ni idije ọdun 2019

  • Gina Bass, 26

    Gambia Asare

    Gina Bass jẹ elere sisa Gambia to gba ami-ẹyẹ ni idije200m tí àwọn obinrin ni Rabat 2019.

    Awọn idije Tokyo ni yoo jẹ ẹlẹkeji rẹ ni Olimpiki

  • Julius Yego, 32

    Kenya Oluju nkan

    Julius Yego jẹ olujunkan Kenyan to gba ami ẹyẹ fadaka ni Olimpiki to waye ni Rio lọdun 2016

    Wọn fun ni inagije 'Mr Youtube' nitori bo ṣe mọ iṣẹ ọhun latara wiwo fọran lori Youtube

  • Brigid Kosgei, 27

    Kenya Elere

    Brigid Kosgei jẹ asare Kenya to lamilaaka ni odun 2018 ati 2019 nibi idije Chicago marathon ati ilu London 2019 ati 2020

    Kosgei jẹ ẹni to di ami ẹyẹ agbaye lọwọ pẹlu akoko 2:14:04 to gba ni Chicago marathon ọdun 2019. Idije Tokyo ni akoko ti yoo kopa.

  • Eliud Kipchoge, 36

    Kenya Elere sisa

    Eliud Kipchoge jẹ ẹni ti ere jẹ iṣẹ rẹ

    Ọmọ Kenya ọhun jẹ ẹni to di ami ẹyẹ agbaye mu pẹlu igba 2:01:39 ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan ọdun 2018 nibi Berlin Marathon.

    Otungba ami ẹyẹ goolu ni olimpiki Rio lọdun 2016

  • Beatrice Chepkoech, 29

    Kenya Steeplechase

    Beatrice Chepkoech lo jẹ ẹni ti ami ẹyẹ agbaye si wa lọwọ rẹ fun ere Steeplechase

    Asare orilẹede Kenya to ni goolu fun 3,000 SSteplechase ni idije odun 2019.

  • Faith Kipyegon, 27

    Kenya Asare

    Faith Kipyegon jẹ asare orilẹede Kenya to gba ami ẹyẹ goolu fun 1500m ni idije Rio Olimpiki lọdun 2016

    O tun gba fadaka nibi idije agbaye lọdun 2017 ati omiran ni odun 2019.

  • Khadija Mardi, 30

    Morocco Ẹlẹṣẹ

    Khadija Mardi jẹ afẹṣẹja ọmọ ilu Morocco. O kopa ninu Awọn ere Olimpiiki Rio 2016 ṣugbọn o padanu ni agbedemeji obinrin (69-75kg) nibi ipele quarter finals

    O tun gba ami-idẹ kan níbi ere ẹlẹṣẹ obinrin ni odun 2019

  • Rababe Arafi, 30

    Morocco Asare

    Rababe Arafi jẹ aṣare Moroccan kan ti o gba goolu ni 1500m 2019 IAAF Diamond League ti awọn obinrin.

    Idije Tokyo 2020 ni yoo ẹlekeji rẹ ti yoo kopa

  • Ramzi Boukhiam, 27

    Morocco Elere ori omi

    Ramzi Boukhiam jẹ yan iṣẹ ere sisa oju omi laayo

    Idije Olimpiki yii ni yoo jẹ akọkọ rẹ ati wipe ohun si ni yoo koko soju orilẹede Morocco nibi ere sisa ori omi.

  • Soufiane El Bakkali, 27

    Morocco Steeplechase

    Soufiane El Bakkali wa lati orilẹ-ede Morocco. O gba ami ẹyẹ fadaka ni idije awọn ọkunrin fun 3,000m steeplechase ni 2017 IAAF World Championships.

    Rio 2016 Olympics ni Olympics akọkọ to ti kopa.

  • Maria Machava, 23

    Mozambique Irinajo ori omi

    Maria Machav jẹ awakọ oju omi to wa lati Mozambique, yoo si kopa ni idije Olympic Games fun igba akọkọ ni Tokyo 2020.

  • Deisy Nhaquile

    Mozambique Ieinajo ori omi

    Ọmọ orilẹ-ede Mozambique ni Deisy Nhaquile. O jẹ awakọ ori omi ti yoo kopa ni idije Olympic Games fun igba akọkọ ni Tokyo 2020.

    o bori ni idije 2019 Afican Sailing Championships ni 420 Radial Laser class.

  • Denise Parruque

    Mozambique Irinajo ori omi

    Tokyo 2020 ni idije Olympics akọkọ ti Denise Parruque, ọmọ orilẹ-ede Mozambique to jẹ awakọ oju omi, yoo ti kopa.

    Oun ati akẹẹgbẹ rẹ, Maria, to bori ni idije 2019 Africa class 470 regatta.

  • Maike Diekmann, 27

    Namibia Atukọ ori omi

    Maike Diekmann jẹ ọmọ orilẹ-ede Namibia, o ma n tukọ oju omi, yoo si ṣoju Namibia fun igba akọkọ ninu idije yii ni Olympic Games.

  • Aminatou Seyni, 24

    Niger Elere sisa

    Ọmọ orilẹ-ede Niger ni Aminatou Seyni, elere sisa to kopa ni idije 2019 World Championships.

  • Blessing Okagbare, 33

    Nigeria Elere sisa/

    Elere sisa ati ẹni to ma n fo nkan ni Blessing Okagbare, ọmọ orilẹ-ede Naijiria.

    O ni akọsilẹ nipa rẹ ti ẹnikẹni ko ni iru rẹ, fun bo ṣe pari ere sisa 100m laarin iṣẹju aaya 10.75, to si tun ṣe ju bẹẹ lọ ni oṣu Kẹfa, ọdun 2021 pẹlu 10.63.

    Oun lo yara julọ ni Naijiria ati Africa.Oun ati ọmọ orilẹ-ede Jamaica, Shelly-Ann, to bori ni idije Fraser-Pryce lọdun 2021 lo wa ni ipo kan naa

  • Elizabeth Anyanacho,22

    Nigeria Taekwondo

    Elizabeth Anyanacho ni obinrin, ọmọ orilẹ-ede Naijiria keji ati ẹni akọkọ lati ọdun 16 sẹyin, to ni anfaani lati kopa ni idije Olympics fun ere idaraya Taekwondo.

  • Divine Oduduru, 24

    Nigeria Elere sisa

    Idije Rio 2016 Olympics ni Divine Oduduru ti kopa fun igba akọkọ

    Oun nikan ni elere sisa lati Naijiria to de ipele 'semifinal' laarin awọn ọkunrin to n sare.

  • Tobi Amusan, 24

    Nigeria

    Tobi Amusan jẹ elere sisa, to tun ma n fo nkan, lati Naijiria, O gba ami ẹyẹ goolu ni idije 100m ti awọn obinrin nibi Gold Coast 2018 Commonwealth Games ni Australia.

    2016 Rio Olympics ni Olympics akọkọ to ti kopa, o si de ipele 'semifinal', ṣugbọn ko de ipelel to kẹhin, nitori pe o sẹ ipo kẹta.

  • Ese Brume, 25.

    Nigeria Elere sisa

    Ese Brume jẹ ẹnikan lara obinrin ilẹ Africa mẹta to ma n fo, to si tiu tayọ &m

    Rio 2016 Games ni idije Olympics akọkọ to ti kopa. O si ṣe ipo karun-un.

    O gba ami ẹyẹ idẹ ni 2019 World Athletics Championships.

  • Chukwuebuka Enekwechi, 28

    Nigeria Shot Put

    Ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni Chukwuebuka Enekwechi. O ma n sẹ ere idaraya Shot Put, o si gba ami ẹyẹ fadaka ni idije 2018 Commonwealth Games.

    O tun ṣe ipo kẹjọ ni 2019 World Championships, eyi to mu ko jẹ elere idaraya ọkunrin, ọmọ Naijria kan ṣoṣo to de ipele to kẹhin

  • Usheoritse Itsekiri, 23

    Nigeria Elere sisa

    Usheoritse Itsekiri jẹ elere sisa lati Naijiria to ti gba ami ẹyẹ idẹ, to tun gba ami ẹyẹ rẹ lati ilẹ okeere fun igba akọkọ ninu ere sisa 100m ti awọn ọkunrin ni African Games ni Rabat.

  • Esther Toko, 21

    Nigeria Atukọ oju omi

    Esther Toko jẹ atukọ oju omi lati Naijiria, to ti gba ami ẹyẹ idẹ ati fadaka ni Cape Verde 2019 African Beach Games.

    Tokyo ni idije Olympics akọkọ to n lọ. Eyi to mu ko jẹ atukọ oju omito n gbe ni Naijiria ti yoo kọkọ ṣoju Naijiria ni Olympics.

  • Ayomide Emmanuel Bello, 19

    Nigeria Ere sisa pẹlu canoe

    Ayomide Emmanuel Bello yoo kopa fun igba akọkọ ni Olympics, gẹgẹ bi obinrin akọkọ to n wa ọkọ oju omi 'canoe' lati Naijiria ti yoo kopa ni idije naa.

    Bello gba ami ẹyẹ goolu mẹrin ni idije Rabat 2019 African Games ni C-1 200m, C-1 500m, C-2, 200m ati C2 500m.

  • Rodney Govinden, 35

    Seychelles Irinajo oju omi

    Rodney Govinden yoo ṣoju Seychelles ni Tokyo 2020 Olympics Games.

    Idije Olympics keji ti yoo ti kopa re e , lẹyin Rio 2016. O bori ni idije 2019 Seychellois of the Year Award.

  • Wayde Van Nierkerk, 29

    South Africa Elere sisa

    Wayde Van Nierkerk jẹ ọmọ orilẹ-ede South Afirca, to jẹ elere sisa to ti gba mi ẹyẹ goolu ni Rio 2016 Olympics, ni idije ere sisa 400m.

    O di ipilẹ tuntun iṣẹju aaya 43.03 lelẹ ni agbaye, eyi to fi gba a mọ ẹni to yara ju tẹlẹ, Michael Johnson, ọmọ orilẹ-ede America.

  • Chad Le Clos, 29

    South Africa Liluwẹ

    Chad le Clos jẹ omuwẹ lati orilẹ-ede South Africa, to ti gba ami ẹyẹ lọpọlọpọ. Lara wọn ni goolu kan ni London 2012 Olympics, ati fadaka meji ni Rio 2016 Olympics.

  • Akani Simbine, 27

    South Africa Elere sisa

    Asare ori ọdan ni Akani Simbine to jẹ ọmọ orilẹ-ede South Africa ni ipele 100m ni idije Commonwealth to waye lọdun 2018.

    O ṣe ipo kẹrin ni 2019 World Championships.

  • Caitlin Rooskrantz, 19

    South africa Gymnastics

    Caitlin Rooskrantz ti ṣetan lati kopa fun igba akọkọ ni 2020 Tokyo Olympics

    Ọmọ orilẹ-ede South Afirca naa bori ni idije 2018 African Artistic Gymnastics Championships ati Hungary 2019 Artistic Gymnastics World Cup Challenge

    Yoo kopa fun igba akọkọ ni idije Olympics, ni Tokyo 2020 Olympics

  • Erin Sterkenburg, 18

    South Africa Ere idaraya oke gigun

    Erin Sterkenburg jẹ ọmọ orilẹ-ede South Africa, to ma n gun nkan. oun si ni ọmọ Africa akọkọ to ti yoo kopa ni idije oke gigun ni idije Tokyo 2020 Olympic Games.

    O bori ni idije 2020 IFSC Africa Championships

  • Henri Schoeman, 29

    South Africa Triathlon

    Ọmọ orilẹ-ede South Africa ni Henri Schoeman. O jẹ elere idara Triathon, to gba ami ẹyẹ goolu lasiko idije Gold Coast 2018 Commonwealth Games.

    O gba ami ẹyẹ idẹ ni idije triathlon,awọn ọkunrin ni Rio 2016 Olympics

  • Boipelo Awuah, 15

    South Africa Skateboarding

    Boipelo Awuah ni elere idaraya 'skateboard' akọkọ lati south Africa to kopa ni Olympics. Oun naa ni elere idaraya ti ọjọ ori rẹ kere ju nu idije naa.

  • Blitzboks

    South Africa Rugby Sevens

    Ikọ Rugby South Africa Sevens, to tun n jẹ́ Blitzboks gba ami ẹyẹ idẹ, ni Rio Olympics 2016.

    Ipo keji ni wọn ṣe ni idije Rugby Sevens World Cup ni 1997.

  • Oussama Mellouli, 37

    Tunisia Uogoleaji

    Oussama Mellouli, jẹ omuwẹ lati orilẹ-ede Tunisia, to gba ami ẹyẹ goolu fun idije mita 1500, ti awọn ọkunrin ni Beijing 2008 Olympics, ati idije liluwẹ, maratọọnu o ni kilomita 10 ni London 2012 Olympics.

  • Marwa Amri, 32

    Tunisia Myeleka

    Marwa Amri jẹ ọmọ orilẹ-ede Tunisia, to ma n ja ijakadi. O gba ami ẹyẹ idẹ ni Rio 2016 Olympics. Eyi to mu ko jẹ obinrin Africa akọkọ to gba ami ẹyẹ ninu ijakadi ni idje Olympics.

  • Ines Boubakri,32

    Tunisia Fencing

    Ọmọ orilẹ-ede Tunisia ni Ines Boubakri. O ma n fo odi. O si gba ami ẹyẹ idẹ ni idije awọn obinrin ni Rio 2016 Olympics.

  • Jacob Kiplimo, 29

    Uganda Mwanariadha

    Jacob Kiplimo jẹ ọmọ orilẹ-ede Uganda, to pari ere sisa mita 3000, ni idije awọn ọkunrin ni 2020 IAAF Diamond Golden Gala.

    Tokyo 2020 ni yoo jẹ idije keji to ti kopa lẹyin Rio 2016.

  • Ronald Musagala, 28

    Uganda Asare ori ọdan

    Roland Musagala jẹ ọmọ Uganda to kopa ninu idije Olympic ninu ere sisa fun igba akọkọ lọdun 2016.

    O gb a goolu ni liigi Diamond ati ni Paris pẹlu

  • Joshua Cheptegei,25

    Uganda Elere sisa

    Ọmọ orilẹ-ede Uganda ni Joshua Chep tegei. O ti gba ami ẹyẹ goolu ni idije ere sisa oni mita 10,000 ni idije World Athletics Championships lọdun 2019, o tun ṣe nkan ti ko ṣẹlẹ ri nigba to bori ere sisa mita 5,000 ni idije Monaco 2020 Diamond League.

  • Peruth Chemutai, 22

    Uganda Steeplechase

    Elere idaraya 'steeplechase' ni Peruth Chemutai. O pari ere ije steeplechase o ni mita 3,000 ni Rio 2016 Olympics.

    Bakan naa lo ṣe ipo karun-un, ni idije 'steeplechase' o ni mita 3,000 ti awọn obirin lọdun 2019 lasiko World Athletics Championships.

  • Copper Queens

    Zambia Bọọlu gbigba

    Ẹgbẹ agbabọọlu awọn obinrin ni Zambia, Cpper Queens tabi She-Polopolo, yoo kopa fun igba akọkọ ni idije Olympics ni Tokyo 2020 lọdun yii

  • Scott Vincent, 29

    Zimbabwe Gọọfu

    Ọdun yii ni igba akọkọ niyii, ti Scott Vincent yoo kopa ni Olympics. Lọdun 2019, ipo kẹrin ni ọmọ orilẹ-ede Zimbabwe ọhun ṣe ni idije Japan Open Golf Championships.

  • D'Tigers

    Nigeria Bọọlu Alapẹrẹ

    Ẹgbẹ agbabọọlu Alapẹrẹ ti Naijira, D'Tigers, lo gba tikẹẹti kan ṣoṣo to bọ si Africa fun idije Tokyo 2020 olympics, nibi idije 2019 FIBA Basketball World Cup.

    Ẹgbẹ agbabọọlu Alapẹrẹ ti Naijira, D'Tigers, lo gba tikẹẹti kan ṣoṣo to bọ si Africa fun idije Tokyo 2020 olympics, nibi idije 2019 FIBA Basketball World Cup.

    Awọn akọni ilẹ Africa ọhun, tun na Australia ati USA ni oṣu Keje, ọdun 2021, lasiko idije ọlọrẹ-sọrẹ meji ọtọọtọ to waye ṣaaju Olympics

  • The Pearls

    Angola Bọọlu gbigba pẹlu ọwọ

    Ẹgbẹ agbabọọlu ọlọwọ, ti awọn obinrin ni orilẹ-ede Angola, The Pearls, lo gba ife 2021 African Women's Handball Champions.

    Wọn ṣe ipo kẹjọ ni Rio 2016 Olympics, lẹyin ti wọn ja ni ipele 'Quarter finals'.